Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?

Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?

Tó o bá fẹ́ mọ ẹnì kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí wàá kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ ni pé, “Kí lorúkọ ẹ?” Tó o bá bi Ọlọ́run ní ìbéèrè yẹn, kí lo rò pé ó máa sọ?

“Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn.”​—Àìsáyà 42:8.

Ṣé o ti gbọ́ orúkọ yẹn rí? Ó ṣeé ṣe kó o má tíì gbọ́ ọ rí torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ lo orúkọ yẹn, àwọn míì ò sì lò ó rárá. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń fi orúkọ oyè náà “OLÚWA” rọ́pò ẹ̀. Síbẹ̀, orúkọ Ọlọ́run fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Álífábẹ́ẹ̀tì mẹ́rin nínú èdè Hébérù, ìyẹn YHWH tàbí JHVH ló para pọ̀ di orúkọ náà, òun sì ni wọ́n túmọ̀ sí “Jèhófà” lédè Yorùbá.

Àkájọ ìwé Sáàmù tí wọ́n rí nínú Òkun Òkú Ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní S.K., HÉBÉRÙ

Ìtumọ̀ Bíbélì Tyndale 1530, GẸ̀Ẹ́SÌ

Ìtumọ̀ Bíbélì Reina-Valera 1602, SPANISH

Ìtumọ̀ ti Union Version 1919, CHINESE

Léraléra ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù àti nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì míì

ÌDÍ TÍ ORÚKỌ ỌLỌ́RUN FI ṢE PÀTÀKÌ

Orúkọ náà ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run fúnra ẹ̀. Kò sí ẹnì kankan tó fún Ọlọ́run lórúkọ yìí, òun ló fún ara ẹ̀. Jèhófà fúnra ẹ̀ sọ pé: “Èyí ni orúkọ mi títí láé, bí wọ́n á sì ṣe máa rántí mi láti ìran dé ìran nìyí.” (Ẹ́kísódù 3:15) Nínú Bíbélì, orúkọ Ọlọ́run ìyẹn Jèhófà fara hàn ju àwọn orúkọ oyè míì lọ, bí Olódùmarè, Baba, Olúwa, tàbí Ọlọ́run. Kódà ó tún fara hàn ju orúkọ àwọn èèyàn lọ, bí Ábúráhámù, Mósè, Dáfídì àti Jésù. Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ orúkọ òun gangan. Bíbélì sọ pé: “Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.”​—Sáàmù 83:18.

Orúkọ náà ṣe pàtàkì sí Jésù. Nínú àdúrà táwọn èèyàn mọ̀ sí Àdúrà Olúwa, Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa bẹ Ọlọ́run pé: “Kí orúkọ rẹ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Jésù fúnra ẹ̀ gbàdúrà pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” (Jòhánù 12:28) Bí Jésù ṣe máa fi ògo fún orúkọ Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù sí i, ìdí nìyẹn tó fi sọ nínú àdúrà ẹ̀ pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n.”​—Jòhánù 17:26.

Orúkọ náà ṣe pàtàkì sáwọn tó mọ Ọlọ́run. Àwọn èèyàn tó jọ́sìn Ọlọ́run láyé àtijọ́ mọ̀ pé tí wọ́n bá fẹ́ rí ààbò àti ìgbàlà, ó ṣe pàtàkì pé káwọn mọ orúkọ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ààbò.” (Òwe 18:10) Ó tún sọ pé: “Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò sì rí ìgbàlà.” (Jóẹ́lì 2:32) Bíbélì fi hàn pé orúkọ Ọlọ́run máa fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run àtàwọn tí kò sìn ín. “Gbogbo èèyàn yóò máa rìn ní orúkọ ọlọ́run wọn, àmọ́ àwa yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé.”​—Míkà 4:5; Ìṣe 15:14.

OHUN TÍ ORÚKỌ ỌLỌ́RUN JẸ́ KÁ MỌ̀

Ó jẹ́ ká dá Ọlọ́run tòótọ́ mọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì ló gbà pé orúkọ náà Jèhófà túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Jèhófà fúnra ẹ̀ jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ orúkọ ẹ̀ nígbà tó ń sọ nípa ara ẹ̀ fún Mósè pé: “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Torí náà, orúkọ yẹn ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ ju pé kéèyàn kàn pe Ọlọ́run ní Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Orúkọ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní agbára láti ṣe ohunkóhun, ó sì lè lo ìṣẹ̀dá rẹ̀ èyíkéyìí láti ṣe ohunkóhun tó bá ní lọ́kàn. Àwọn orúkọ oyè kan ń tọ́ka sí ipò Ọlọ́run, àṣẹ tó ní tàbí agbára ẹ̀. Àmọ́ orúkọ ẹ̀ gangan ló sọ irú ẹni tó jẹ́ ní pàtó àti ohun tó lè ṣe.

Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. Ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ gbogbo nǹkan tó dá títí kan àwa èèyàn. Bí Ọlọ́run ṣe sọ orúkọ ẹ̀ fún wa jẹ́ kó dá wa lójú pé ó fẹ́ ká mọ òun. Kò retí pé ká béèrè lọ́wọ́ òun, fúnra ẹ̀ ló sọ ọ́ fún wa. Láìsí àní-àní, Ọlọ́run fẹ́ ká mọ̀ pé òun kì í ṣe àdììtú, àmọ́ òun jẹ́ ẹni tó wà lóòótọ́, a sì lè sún mọ́ òun.​—Sáàmù 73:28.

Tá a bá ń lo orúkọ Ọlọ́run, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Àpẹẹrẹ kan rèé, ká sọ pé o pàdé ẹnì kan tó o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í bá ṣọ̀rẹ́, o wá sọ fún un pé orúkọ ẹ gangan lo fẹ́ kó máa pè ẹ́. Àmọ́ ní gbogbo ìgbà tẹ́ni náà bá rí ẹ, orúkọ míì ló máa ń pè ẹ́. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ó ṣeé ṣe kó o máa rò ó pé ẹni náà ò ṣe tán láti di ọ̀rẹ́ ẹ. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí pẹ̀lú Ọlọ́run. Jèhófà ti sọ orúkọ ẹ̀ fún wa, ó sì gbà wá níyànjú pé ká máa lò ó. Tá a bá ń lo orúkọ náà, ńṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a fẹ́ sún mọ́ ọn. Kódà, Ọlọ́run máa ń fiyè sí ‘àwọn tó ń ṣàṣàrò lórí orúkọ ẹ̀ tàbí àwọn tó ka orúkọ ẹ̀ sí pàtàkì!’​—Málákì 3:16.

Tá a bá fẹ́ mọ Ọlọ́run, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé ká mọ orúkọ ẹ̀. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó parí síbẹ̀. Ó tún yẹ ká mọ irú ẹni tó jẹ́.

KÍ NI ORÚKỌ ỌLỌ́RUN? Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Orúkọ yẹn fi hàn pé òun nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ tó jẹ́ alèwílèṣe