Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì, Ó sì Ṣeé Gbára Lé

Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì, Ó sì Ṣeé Gbára Lé

Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló gbà pé Bíbélì ṣeé gbára lé torí pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Lónìí, àìmọye èèyàn ló ń fi ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò láyé wọn. Síbẹ̀, àwọn míì sọ pé Bíbélì kò bá ìgbà mu àti pé ìtàn àròsọ lásán ló wà nínú rẹ̀. Kí lèrò ẹ? Ṣó o rò pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?

ÌDÍ TÓ O FI LÈ GBÁRA LÉ BÍBÉLÌ

Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá Bíbélì jẹ́ ìwé tó ṣeé gbára lé? Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé o ní ọ̀rẹ́ kan tó máa ń sọ òtítọ́ nígbà gbogbo, o sì ti mọ̀ ọ́n sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó dájú pé kò ní ṣòro fún ẹ láti gbára lé e. Bíi ti ọ̀rẹ́ yẹn, ṣé ìgbà gbogbo ni Bíbélì náà máa ń sọ òtítọ́? Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.

Olóòótọ́ Làwọn Tó Kọ Bíbélì

Olóòótọ́ làwọn tó kọ Bíbélì, kódà wọ́n tún kọ àṣìṣe tiwọn fúnra wọn síbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Jónà kọ nípa ìwà àìgbọràn rẹ̀ sínú Bíbélì. (Jónà 1:1-3) Nígbà tó tiẹ̀ ń kọ apá tó parí nínú ìwé rẹ̀, ó sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe bá a wí, àmọ́ kò sọ̀rọ̀ nípa bí òun ṣe ronú pìwà dà. (Jónà 4:1, 4, 10, 11) Bí gbogbo àwọn tó kọ Bíbélì ṣe sọ òtítọ́ fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.

Òtítọ́ Tó Ṣeé Gbára Lé

Ṣé àwọn ìmọ̀ràn gidi wà nínú Bíbélì? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tá a lè ṣe kí àárín àwa àtàwọn ẹlòmíì má bàa bà jẹ́, ó ní: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.” (Mátíù 7:12) Ó tún sọ pé: “Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ líle ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Ó dájú pé òtítọ́ làwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, wọ́n sì wúlò fún wa lóde òní bí wọ́n ṣe wúlò nígbà tí wọ́n kọ ọ́.

Òtítọ́ Làwọn Ìtàn Inú Rẹ̀

Ọ̀pọ̀ ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí láwọn ọdún tó ti kọjá jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, títí kan àwọn èèyàn àtàwọn ibi tí wọ́n dárúkọ ló wà lóòótọ́. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kékeré kan. Bíbélì sọ pé nígbà ayé Nehemáyà, àwọn èèyàn ilẹ̀ Tírè (ìyẹn àwọn Foníṣíà tó wá láti Tírè) tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù “kó ẹja àti oríṣiríṣi ọjà wá.”​—Nehemáyà 13:16.

Ṣé ẹ̀rí kankan wà tó fi hàn pé òótọ́ ni ẹsẹ Bíbélì yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀rí wà. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí àwọn nǹkan kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì, lára rẹ̀ ni ọjà táwọn Foníṣíà kó wá sí Ísírẹ́lì, tó fi hàn pé àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ṣòwò pọ̀ lóòótọ́. Wọ́n tún rí egungun ẹja inú òkun Mẹditaréníà hú jáde ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn awalẹ̀pìtàn náà gbà pé ó ní láti jẹ́ ẹja táwọn oníṣòwò kó wá sí etíkun láti ọ̀nà tó jìn. Lẹ́yìn àyẹ̀wò fínnífínní, ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tó wà ní Neh[emáyà] 13:16 tó sọ pé àwọn èèyàn ilẹ̀ Tírè wá ta ẹja ní Jerúsálẹ́mù fi hàn pé òótọ́ ni ẹsẹ Bíbélì yìí.”

Òtítọ́ Ló Sọ Nípa Sáyẹ́ǹsì

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì jẹ́ ìwé ẹ̀sìn àti ìwé tó sọ ọ̀pọ̀ ìtàn. Síbẹ̀, ohun tó bá sọ nípa sáyẹ́ǹsì máa ń bára mu, ó sì máa ń jóòótọ́ délẹ̀. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.

Láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn ni Bíbélì ti sọ pé ayé rọ̀ “sórí òfo.” (Jóòbù 26:7) Ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí ìtàn àròsọ táwọn èèyàn gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé orí omi ni ayé wà tàbí pé ìjàpá ńlá kan ló gbé ayé dúró. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kọ ìwé Jóòbù, àwọn èèyàn ò tíì gbà pé ayé rọ̀ sórí òfo, wọ́n sọ pé orí ohun kan ló jókòó lé. Àmọ́ kò ju nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún sẹ́yìn, ìyẹn ní 1687, tí Isaac Newton gbé ìwé kan jáde tó sọ̀rọ̀ nípa òòfà, ó wá ṣàlàyé pé ńṣe layé ń yí po, kò sì dúró sórí ohunkóhun. Ọ̀rọ̀ tí ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ sáyẹ́ǹsì yìí sọ bá ohun tí Bíbélì sọ mu láti ohun tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọdún sẹ́yìn lọ!

Òótọ́ Ni Àsọtẹ́lẹ̀ Inú Rẹ̀

Ṣé òótọ́ làwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tí Àìsáyà sọ nípa bí Bábílónì ṣe máa pa run.

Àsọtẹ́lẹ̀ Náà: Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Àìsáyà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé Bábílónì tó máa jẹ́ olú ìlú ìjọba tó lágbára jù láyé ìgbà yẹn máa pa run pátápátá, àwọn èèyàn ò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́. (Àìsáyà 13:17-20) Àìsáyà tiẹ̀ sọ orúkọ ẹni tó máa ṣẹ́gun Bábílónì, ó ní Kírúsì lorúkọ rẹ̀. Ó tún sọ ọ̀nà tó maá gbà ṣe é, ó ní ó máa mú kí odò “gbẹ táútáú.” Ó tún sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè náà máa wà ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu.​—Àìsáyà 44:27–45:1.

Bí Àsọtẹ́lẹ̀ Náà Ṣe Ṣẹ: Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọdún lẹ́yìn tí Àìsáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀, ọba ilẹ̀ Páṣíà kan gbéjà ko Bábílónì. Orúkọ rẹ̀ sì ni Kírúsì. Kò rọrùn láti wọ ìlú Bábílónì, torí pé ògiri gìrìwò àti Odò Yúfírétì ló yí i ká. Torí náà, Kírúsì ní kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbẹ́ ilẹ̀ láti darí omi odò náà gba irà tó wà nínú igbó. Èyí mú kí omi náà fà débi tí àwọn ọmọ ogun Kírúsì fi lè gba inú omi jíjìn náà kọjá débi ògiri ìlú. Ó yani lẹ́nu pé lọ́jọ́ yẹn, àwọn ará Bábílónì ṣílẹ̀kùn tó dojú kọ odò yẹn sílẹ̀ gbayawu! Ni àwọn ọmọ ogun Kírúsì bá gba ẹnubodè wọlé, wọ́n sì ṣẹ́gun ìlú yẹn.

Àmọ́, ó ku ìsọfúnni pàtàkì kan: Ṣé òótọ́ ni pé kò sẹ́nì kankan tó ń gbé Bábílónì mọ́? Ó tó ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan táwọn èèyàn ṣì fi ń gbé ibẹ̀. Àmọ́ lónìí, àwókù ìlú Bábílónì tó wà nítòsí Baghdad, lórílẹ̀-èdè Ìráàkì jẹ́ ẹ̀rí pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ látòkè délẹ̀. Ẹ ò rí i pé tí Bíbélì bá sọ ohun kan nípa ọjọ́ iwájú, ó máa ń ṣẹ.