Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ILÉ ÌṢỌ́ No. 1 2023 | Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìlera Ọpọlọ

Kárí ayé, àìmọye èèyàn ló ní àárẹ̀ ọpọlọ. Ìṣòro yìí ò mọ ọmọdé bẹ́ẹ̀ ni kò mọ àgbà, kò mọ olówó bẹ́ẹ̀ ni kò mọ tálákà. Bákan náà, kò sí ẹ̀yà tàbí àwọn ẹlẹ́sìn kan tí wọn ò lè níṣòro yìí. Kí ni àárẹ́ ọpọlọ? Báwo la ṣe lè mọ̀ tẹ́nì kan bá ní àárẹ̀ ọpọlọ? Ìwé yìí sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn tó níṣòro yìí gba ìtọ́jú tó yẹ, ó sì tún sọ àwọn ọ̀nà pàtàkì tí Bíbélì lè gbà ran àwọn tó ní àárẹ̀ ọpọlọ lọ́wọ́.

 

Àárẹ̀ Ọpọlọ​—Ìṣòro Tó Kárí Ayé

Kò sẹ́ni tí ò lè ní àárẹ̀ ọpọlọ, kò mọ ọmọdé, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ àgbàlagbà. Ka ìwé yìí kó o lè rí àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì táá jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè máa ní ìlera tó jí pépé.

Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Rẹ

Kí ló máa jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ, ó sì mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ ju ẹnikẹ́ni lọ?

1 | Àdúrà—“Ẹ Máa Kó Gbogbo Àníyàn Yín Lọ Sọ́dọ̀ Rẹ̀”

Ṣé òótọ́ ni pé a lè gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn nǹkan tó ń kó ìdààmú ọkàn bá wa? Táwọn tó ní ìdààmú ọkàn bá ń gbàdúrà, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wọ́n?

2 | “Ìtùnú Látinú Ìwé Mímọ́”

Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó jẹ́ ká nírètí pé láìpẹ́ a ò ní máa ro èrò òdì mọ́.

3 | Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Èèyàn Inú Bíbélì

Tá a bá ka ìtàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, àá rí i pé ọ̀rọ̀ wọn jọ tiwa, àpẹẹrẹ wọn sì máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn.

4 | Ìmọ̀ràn Tó Wúlò Wà Nínú Bíbélì

Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè rí bó o ṣe lè fara da àìlera ọpọlọ tó o bá ń ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó o sì láwọn àfojúsùn tọ́wọ́ ẹ lè tètè tẹ̀.

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Ní Àárẹ̀ Ọpọlọ Lọ́wọ́

Tó o bá múra tán láti ran èèyàn ẹ tó ní àárẹ̀ ọpọlọ lọ́wọ́, ó máa rọrùn fún un láti lè máa fara dà á.