Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Gbé Ìgbé Ayé Tó Dára Jù Lọ

Bó O Ṣe Lè Gbé Ìgbé Ayé Tó Dára Jù Lọ

LÓNÌÍ, ìgbésí ayé kò rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí. Ńṣe ló yẹ kí gbogbo àwọn èèyàn tó wà láyé fi ara wọn sábẹ́ ìdarí Ọlọ́run, kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, kí wọ́n sì fìwà jọ ọ́. Ńṣe ló yẹ kí wọ́n wà níṣọ̀kan, kí wọ́n máa láyọ̀, kí wọ́n máa bímọ, kí wọ́n máa ṣàwárí àwọn nǹkan tuntun, kí wọ́n sì sọ gbogbo ayé di Párádísè.

ỌLỌ́RUN ṢÈLÉRÍ PÉ ÒUN Á MÚ KÍ AYÉ RÍ BÓ ṢE YẸ KÓ RÍ

  • Ó máa “fòpin sí ogun kárí ayé.”​Sáàmù 46:9.

  • “Àkókò wá tó . . . láti run àwọn tó ń run ayé.”​Ìfihàn 11:18.

  • “Kò sí ẹnì kankan tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’ ”​Àìsáyà 33:24.

  • “Àwọn àyànfẹ́ mi sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”​Àìsáyà 65:22.

Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe máa ṣẹ? Ọlọ́run ti yan Jésù Ọmọ rẹ̀ láti di Ọba ìjọba tó dára jù lọ, á sì ṣàkóso ayé láti ọ̀run. Bíbélì pe ìjọba náà ní Ìjọba Ọlọ́run. (Dáníẹ́lì 2:44) Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Ọlọ́run . . . máa fún un ní ìtẹ́ . . . , ó máa jẹ Ọba.”​—Lúùkù 1:​32, 33.

Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu láti fi hàn pé tó bá di Alákòóso, ó máa mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn dára ju èyí tí wọ́n ń gbé yìí lọ.

JÉSÙ JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ ÒUN MÁA ṢE OHUN RERE FÚN ÀWỌN ONÍGBỌRÀN

  • Ó wo onírúurú àìsàn, èyí fi hàn pé ó máa mú gbogbo àìlera kúrò láyé.​Mátíù 9:35.

  • Ó mú kí òkun pa rọ́rọ́, ìyẹn fi hàn pé ó máa dáàbò bo àwọn èèyàn lọ́wọ́ ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn àjálù míì.​Máàkù 4:​36-39.

  • Ó bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn, èyí fi hàn pé ó máa pèsè àwọn nǹkan tá a nílò.​Máàkù 6:​41-44.

  • Ó sọ ọmi di wáìnì níbi ìgbèyáwò, èyí sì fi hàn pé ó máa jẹ́ kí àwọn èèyàn gbádùn ìgbésí ayé wọn.​Jòhánù 2:​7-11.

Kí lo yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ gbádùn irú ìgbésí ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn tó ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu? “Ọ̀nà” kan wà tó yẹ kó o tọ̀. Bíbélì pè é ní ‘ọ̀nà tó lọ sí ìyè, àwọn díẹ̀ ló sì ń rí i.’​—Mátíù 7:14.

MÁA RÌN LỌ́NÀ TÓ LỌ SÍ ÌYÈ

Kí ni ọ̀nà tó lọ sí ìyè? Ọlọ́run sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.” (Àìsáyà 48:17) Tó o bá ń rìn ní ọ̀nà yẹn, ìgbésí ayé tó dára jù lò ń gbé.

Jésù tún sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.” (Jòhánù 14:6) Tó o bá gba àwọn òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ni gbọ́, tó o sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó fi sílẹ̀, wàá sún mọ́ Ọlọ́run, wàá sì ṣe ara rẹ láǹfààní.

Báwo lo ṣe lè rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè? Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló wà, àmọ́ Jésù kìlọ̀ pé: “Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ló máa wọ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tó wà ní ọ̀run nìkan ló máa wọ̀ ọ́.” (Mátíù 7:21) Ó tún sọ pé: “Àwọn èso wọn lẹ máa fi dá wọn mọ̀.” (Mátíù 7:16) Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀sìn tòótọ́ àti ẹ̀sìn èké.​—Jòhánù 17:17.

Báwo lo ṣe lè máa rìn ní ọ̀nà ìyè? Tá a bá fẹ́ rìn ní ọ̀nà ìyè, ó yẹ ká mọ ẹni tó dá wa. Àwọn ìbéèrè tá a máa dáhùn rèé: Ta ni ẹni náà? Kí ni orúkọ rẹ̀? Irú ẹni wo ni? Kí ló ń ṣe fún wa báyìí? Kí ló fẹ́ ká máa ṣe? *

Ohun tí Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn máa ṣe kọjá pé ká kàn máa ṣiṣẹ́, ká máa jẹun, ká máa ṣeré, ká sì máa bímọ. Ó yẹ ká tún mọ Ẹlẹ́dàá wa, ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tá a bá ń ṣe ohun tó fẹ́. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo.”​—Jòhánù 17:3.

ỌLỌ́RUN Ń FI BÍBÉLÌ KỌ́ Ẹ “KÍ O LÈ ṢE ARA RẸ LÁǸFÀÀNÍ.”​—ÀÌSÁYÀ 48:17

ÌGBÉSẸ̀ ÀKỌ́KỌ́ TÍ A NÍ LÁTI GBÉ

Téèyàn bá fẹ́ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, ó ní láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì kan. Èyí lè fẹ́ dà bí ohun tó ṣòro díẹ̀, àmọ́ ayọ̀ ló máa gbẹ̀yìn ẹ̀. Ńṣe lọ̀rọ̀ yìí dà bí ìgbà tẹ́nì kan fẹ́ rìnrìn àjò. Ibi yòówù kí onítọ̀hún fẹ́ lọ, ó gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Tó o bá fẹ́ rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè nípa Ọlọ́run, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ níbi tó o bá fẹ́ àti ní àkókò tó rọrùn fún ẹ. O lè kàn sí wa lórí ìkànnì wa www.mt1130.com/yo.