Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ṣé èébú ni àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa “ajá kéékèèké” jẹ́?
Nígbà kan tí Jésù wà ní ààlà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní ìlú Síríà tó jẹ́ ọ̀kan lara ẹkùn-ìpínlẹ̀ Róòmù, obìnrin ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Jésù lo àpèjúwe kan tó dà bíi pé ó ń fi àwọn tí kì í ṣe Júù wé “ajá kéékèèké.” Bẹ́ẹ̀ sì rè é, lábẹ́ Òfin Mósè, ẹran aláìmọ́ ni wọ́n ka ajá sí. (Léfítíkù 11:27) Ṣé Jésù ń bú obìnrin Gíríìkì yìí àtàwọn míì tí kì í ṣe Júù ni?
Rárá. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, ojúṣe pàtàkì òun ni láti ran àwọn Júù lọ́wọ́. Ó wá fi àpèjúwe yẹn tẹ kókó yìí mọ́ obìnrin Gíríìkì yẹn lọ́kàn, ó ní: “Kò tọ́ kí a mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, kí a sì sọ ọ́ sí àwọn ajá kéékèèké.” (Mátíù 15:21-26; Máàkù 7:26) Àwọn Gíríìkì àtàwọn ọmọ ilẹ̀ Róòmù gbà pé ẹran ọ̀sìn tó dáa ni ajá, inú ilé wọn ló máa ń gbé, á sì máa bá àwọn ọmọ olówó rẹ̀ ṣeré. Ọ̀rọ̀ náà “ajá kéékèèké,” mú kí obìnrin yẹn rántí àjọṣe tó máa ń wà láàárín àwọn ajá àtàwọn olówó wọn. Obìnrin Gíríìkì yìí wá mú lára ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, ó sì fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa; ṣùgbọ́n àwọn ajá kéékèèké ní ti gidi máa ń jẹ nínú èérún tí ń jábọ́ láti orí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.” Jésù yin obìnrin náà torí ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó sì wo ọmọ obìnrin náà sàn.—Mátíù 15:27, 28.
Ṣé àbá tó dáa ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú wá nígbà tó ní káwọn atukọ̀ òkun dá ìrìn àjò wọn dúró díẹ̀?
Ìjì ń da ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi n gbé Pọ́ọ̀lù lọ sí orílẹ̀-èdè Ítálì láàmú. Nígbà tí wọ́n dúró díẹ̀ níbì kan, Pọ́ọ̀lù dábàá pé kí wọ́n dá ìrìn àjò náà dúró di ìgbà míì. (Ìṣe 27:9-12) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀?
Àwọn atukọ̀ ojú omi ayé ìgbà yẹn mọ̀ pé ó léwu láti tukọ̀ lórí òkun Mẹditaréníà láwọn oṣù tí òtútù máa ń mú gan-an. Wọ́n kì í tukọ̀ lórí òkun láti oṣù November 15 sí March 15, torí pé ó léwu. Àmọ́ oṣù September tàbí October ni ìrìn àjò tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ bọ́ sí. Nínú ìwé Epitome of Military Science, Ọ̀gbẹ́ni Vegetius tó jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Róòmù (ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni) sọ bí ìrìn àjò ojú òkun ṣe máa ń rí, ó ní: “Àwọn oṣù kan wà tí ìrìn àjò ojú òkun kì í léwu rárá, àwọn oṣù míì wà táwọn atukọ̀ kì í mọ̀ bóyá ó léwu, àwọn oṣù míì ò sì dáa rárá fún ìrìn àjò.” Ọ̀gbẹ́ni Vegetius tún sọ pé, kì í séwu téèyàn bá rìnrìn àjò láàárín oṣù May 27 sí September 14. Àmọ́ oṣù tí ò dá wọn lójú ni September 15 sí November 11. Oṣù tó máa ń léwu gan-an ni March 11 sí May 26. Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọ èyí dáadáa, torí pé ó máa ń rìnrìn àjò orí òkun dáadáa. Ó ṣeé ṣe kí àwọn atukọ̀ àti ẹni tó ni ọkọ̀ ojú omi náà mọ̀ bẹ́ẹ̀, àmọ́ wọ́n kọtí ikún sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù. Ọkọ̀ ojú omi náà sì rì.—Ìṣe 27:13-44.