JÍ! No. 1 2019 | Ǹjẹ́ Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ọkàn Wa Máa Balẹ̀?

Wo díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tá à ń dojú kọ àti ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe kí àwa èèyàn lè wà ní ààbò àti àláàfíà nínú ayé yìí.

Kò Sí Ààbò àti Ìfọ̀kànbalẹ̀

Àkókò yìí gan-⁠an ni ewu pọ̀ jù. Kí la lè ṣe sí i?

Ó Yẹ Ká Mọ Ohun Tó Ń Fa Ìṣòro Náà

Àìpé ẹ̀dá èèyàn ló fa ọ̀pọ̀ ìṣòro tí aráyé ń bá fínra lónìí. Ibo la lè yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́?

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìwà Ọmọlúwàbí

Kí àlàáfíà àti ààbò tó péye tó lè wà, àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ máa hùwà ọmọlúwàbí.

Ìtàn Ricardo àti Andres

Tẹ́lẹ̀, ńṣe ni Ricardo àti Andres máa dá wàhálà sílẹ̀ ní àdúgbò, àmọ́ ní báyìí, ńṣe ni wọ́n ń mú kí àlàáfíà wà ní àdúgbò. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Bíbélì ṣe tún ayé wọn ṣe.

“Àlàáfíà Kì Yóò Lópin”

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Àlàáfíà Máa Pọ̀ Yanturu Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ kárí ayé.

Kí Lèrò Rẹ?

Báwo lo ṣe lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ nínú Bíbélì?