AYÉ DOJÚ RÚ
3 | Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Tẹbítọ̀rẹ́ Dáa Sí I
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
Torí pé nǹkan túbọ̀ ń burú sí i láyé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ti jẹ́ kíyẹn ṣàkóbá fún àjọṣe àwọn pẹ̀lú ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn.
-
Àwọn èèyàn kan máa ń fẹ́ dá wà.
-
Àwọn tọkọtaya kan ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, wọ́n sì ń hùwà àìdáa síra wọn.
-
Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ò rí tàwọn ọmọ wọn rò, wọn ò sì kíyè sí bí nǹkan ṣe rí lára wọn.
Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀
-
Tó o bá ní ọ̀rẹ́ tó dúró tì ẹ́ nígbà ìṣòro, inú ẹ á dùn, ara ẹ á sì yá gágá.
-
Ìgbàkigbà ni nǹkan lè yí pa dà nínú ìdílé torí bí nǹkan ṣe ń nira sí i láyé yìí.
-
Àwọn ìròyìn burúkú tí wọ́n ń gbé jáde lójoojúmọ́ lè dẹ́rù ba àwọn ọmọ ẹ, ìyẹn sì lè má jẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀.
Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí
Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”—Òwe 17:17.
Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, wọ́n sì lè fún ẹ ní ìmọ̀ràn táá ṣe ẹ́ láǹfààní. Tó o bá ń rántí pé ẹnì kan wà tó nífẹ̀ẹ́ ẹ, tí ò sì fọ̀rọ̀ ẹ ṣeré, ìyẹn á fún ẹ lókun kó o lè máa fara da ìṣòro èyíkéyìí tó o bá kojú.