JÍ! No. 2 2016 | Ṣé Ìwé Tó Kàn Dáa Ni Bíbélì?
Ìdí pàtàkì wà tó fi jẹ́ pé Bíbélì ni ìwé tí wọ́n tí ì tẹ̀ tí wọ́n sì túmọ̀ jù lọ nínú gbogbo ìwé tó wà láyé.
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ṣé Ìwé Tó Kàn Dáa Ni Bíbélì?
Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń fi ẹ̀mí wọn wewu kí wọ́n lè ka Bíbélì tàbí láti ní Bíbélì?
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ
Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Tó Ń Bàlágà Lọ́wọ́
Ìmọ̀ràn márùn-ún pàtàkì tá a mú látinú Bíbélì lè mú kí àsìkò ìbàlágà náà rọrùn.
ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ
Onímọ̀ Nípa Ọlẹ̀ Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́
Ọ̀jọ̀gbọ́n Yan-Der Hsuuw gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó yí èrò rẹ̀ pa dà lẹ́yìn tó di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.
OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Àníyàn
Àníyàn tó dáa lè ṣàǹfààní; àmọ́ èyí tí kò dáa lè fa ìpalára. Bó o ṣe lè kojú rẹ̀, kó o sì ṣàṣeyọrí?
Ayékòótọ́ Aláwọ̀ Mèremère
Wo bí ìgbésí ayé àwọn ẹyẹ aláwọ̀ mèremère yìí rí.
OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ
Nípa Àjọṣe Àwọn Èèyàn
Àwọn ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ló wà nínú Bíbélì.
Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì
Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi
Ọ̀mùtí paraku ni Dmitry Korshunov, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì déédéé. Kí ló mú kó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà?
Mo Rìnnà Kore Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Donald, tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n nígbà kan sọ bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe jẹ́ kó mọ Ọlọ́run, tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà, tó sì wá di ọkọ rere.