Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 1

Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Máa Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu

Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Máa Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu

KÍ NI ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU?

Ẹni tó ní ìkóra-ẹni-níjàánu:

  • kì í wá ìgbádùn ojú ẹsẹ̀

  • máa ń ronú jinlẹ̀ kó tó ṣe nǹkan

  • máa ń parí ohun tó bá bẹ̀rẹ̀, tí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún un

  • máa ń fi àǹfààní àwọn míì ṣáájú ti ara rẹ̀

KÍ NÌDÍ TÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU FI ṢE PÀTÀKÌ?

Àwọn ọmọ tó ní ìkóra-ẹni-níjàánu máa ń dúró lórí ìpinnu wọn pé àwọn ò ní ṣe ohun tí kò dáa, kódà tó bá jẹ́ ohun tí wọ́n fẹ́ràn gan-an. Àmọ́, àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ tí kì í kó ara wọn níjàánu:

  • wọ́n máa ń tètè bínú

  • wọ́n máa ń ní ìdààmú ọkàn

  • wọ́n máa ń mu sìgá àti ọtí líle, wọ́n sì máa ń lo oògùn olóró

  • wọ́n máa ń jẹ pàrùpárù oúnjẹ

Ìwádìí kan fi hàn pé tí àwọn ọmọ tó ní ìkóra-ẹni-níjàánu bá dàgbà, wọn kì í sábà rú òfin, wọn kì í sábà ní ìṣòro àìlera tàbí kí wọ́n máa kanra torí pé wọn ò lówó lọ́wọ́. Ìwádìí yẹn ló mú kí ọ̀jọ̀gbọ́n Angela Duckworth tó wá láti Yunifásítì Pennsylvania gbà pé: “Ìkóra-ẹni-níjàánu kì í pọ̀ jù.”

BÍ A ṢE LÈ KỌ́ ỌMỌ NÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU

Máa dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́.’​—Mátíù 5:37.

Àwọn ọmọdé máa ń dìídì ṣe ìjàngbọ̀n nígbà míì, kí wọ́n lè wò ó bóyá àwọn òbí wọn á ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, wọ́n tiẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbangba. Táwọn òbí bá ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, àwọn ọmọ yẹn á wá rí i pé táwọn bá ṣe ìjàngbọ̀n àwọn òbí àwọn á ṣe ohun tí wọn ò fẹ́ ṣe.

Àmọ́ tí àwọn òbí bá dúró lórí ọ̀rọ̀ wọn, ńṣe ni wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ọwọ́ èèyàn máa ń tẹ ohun tó ń fẹ́. Èyí bá ohun tí Dókítà David Walsh sọ mu pé: “Ẹni tó bá gbà pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ọwọ́ èèyàn máa ń tẹ ohun tó bá ń fẹ́ ló máa ń láyọ̀ jù lọ. A ò ṣe àwọn ọmọ wa láǹfààní kankan, tá a bá ń kọ́ wọn pé gbogbo ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ lọwọ́ wọn máa tẹ̀.” *

Tó o bá ń dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ, ó máa ṣe ọmọ rẹ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, ó máa rọrùn fún un láti kọ̀ jálẹ̀ tí wọ́n bá ní kó lo oògùn olóró, kó ṣe ìṣekúṣe, tàbí tí wọ́n bá ní kó lọ́wọ́ sí àwọn ìwà burúkú míì.

Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé kò sí ohun tó ṣe tí kò lérè.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.”​—Gálátíà 6:7.

Ó yẹ kó o kọ́ àwọn ọmọ rẹ pé gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ṣe ni wọ́n máa jèrè. Torí náà tí wọn ò bá kí ń kó ara wọn níjàánu, ohun tó máa gbẹ̀yìn ẹ̀ ò ní dáa. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ rẹ bá ń bínú jù táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ ẹ́, àwọn èèyàn lè máa sá fún un. Àmọ́ tó bá ń kó ara rẹ̀ níjàánu táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ ẹ́, tó sì ń ṣe sùúrù, àwọn èèyàn á sún mọ́ ọn. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ó máa láyọ̀ tó bá ń kó ara rẹ̀ níjàánu.

Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:10.

Ìkóra-ẹni-níjàánu kọjá pé kéèyàn yẹra fún ohun tí kò dáa, ó tún máa ń jẹ́ kéèyàn ṣe ohun tó yẹ kó ṣe, kódà tí ohun náà kò bá gbádùn mọ́ni. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù ló yẹ kó kọ́kọ́ máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ ilé ìwé rẹ̀ kó tó lọ ṣeré.

Jẹ́ àpẹẹrẹ rere.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.”​—Jòhánù 13:15.

Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ rí i pé o máa ń kó ara rẹ níjàánu tí inú bá ń bí ẹ tàbí tó o bá ń kojú ìṣòro, kí wọ́n lè mọ̀ pé àǹfààní wà nínú kéèyàn kó ara rẹ̀ níjàánu. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ rẹ bá ṣe nǹkan tó bí ẹ nínú, ṣé o máa ń fara ya ni àbí o máa ń ṣe sùúrù?

^ ìpínrọ̀ 20 Látinú ìwé náà No: Why Kids​—of All Ages—​Need to Hear It and Ways Parents Can Say It.