Ẹ̀KỌ́ 2
Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ìrẹ̀lẹ̀
KÍ NI ÌRẸ̀LẸ̀?
Àwọn onírẹ̀lẹ̀ máa ń bọ̀wọ̀ fúnni. Wọn kì í hùwà àfojúdi, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ka ara wọn sí bàbàrà bíi pé káwọn èèyàn máa rábàbà fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ẹni tó nírẹ̀lẹ̀ máa ń ka àwọn èèyàn kún, ó sì gbà pé òun lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn.
Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń ka onírẹ̀lẹ̀ èèyàn sí ọ̀dẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, torí pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn gbà pé òun ò kọjá àṣìṣe, á sì ṣe tán láti gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi.
KÍ NÌDÍ TÍ ÌRẸ̀LẸ̀ FI ṢE PÀTÀKÌ?
-
Onírẹ̀lẹ̀ dùn-ún bá rìn. Ìwé kan tí wọ́n ń pè ní The Narcissism Epidemic sọ pé: “Àwọn èèyàn sábà máa ń fẹ́ bá onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ṣọ̀rẹ́ torí pé wọ́n máa ń dùn-ún bá sọ̀rọ̀, wọn kì í gbéraga, wọ́n sì máa ń ka èèyàn sí.”
-
Ìrẹ̀lẹ̀ máa wúlò fún ọmọ rẹ lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá kọ́ ọmọ rẹ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó máa ṣe é láǹfààní ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú, irú bíi tó bá ń wá iṣẹ́. Dókítà kan tó ń jẹ́ Leonard Sax sọ pé: “Tí ọ̀dọ́ kan ò bá mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, ó lè fìdí rẹmi tí agbanisíṣẹ́ bá ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Àmọ́ tí kò bá ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, tó sì pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ṣe pàtàkì sí agbanisíṣẹ́ náà, ó ṣeé ṣe kó rí iṣẹ́ náà gbà.” *
BÓ O ṢE LÈ KỌ́ ỌMỌ RẸ NÍ ÌRẸ̀LẸ̀
Kọ́ ọmọ rẹ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Tí ẹnì kan bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni.”—Gálátíà 6:3.
-
Bá ọmọ rẹ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀. O lè rò pé orí ọmọ rẹ á wú tó o bá ń sọ fún un pé “kò sóhun tó ń fẹ́ tọ́wọ́ ẹ̀ ò ní tẹ̀” tàbí “kò síbi tó fẹ́ dé tí kò lè dé,” àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, láyé tá a wà yìí kì í ṣe gbogbo ohun téèyàn bá ń lé lọwọ́ ẹ̀ lè tẹ̀. Ọmọ rẹ máa ṣàṣeyọrí tó bá ní àfojúsùn tó bọ́gbọ́n mu, tó sì ń sapá kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ̀ ẹ́.
-
Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ ìdí tó o fi gbóríyìn fún un. Tó o bá kàn ń sọ fún ọmọ rẹ pé “o káre ọmọ dáadáa,” ìyẹn ò ní mú kó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ sọ ohun tó ṣe ní pàtó.
-
Má ṣe jẹ́ kí ọmọ rẹ máa lo àkókò tó pọ̀ jù lórí ìkànnì àjọlò. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn máa ń lo ìkànnì àjọlò láti fi gbé ara wọn lárugẹ tàbí láti fi fọ́nnu nípa àwọn ohun tí wọ́n mọ̀ ọ́n ṣe, ìyẹn ò sì fi hàn pé èèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.
-
Kọ́ ọmọ rẹ láti máa tètè tọrọ àforíjì. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ ibi tó ti jẹ̀bi, kó sì gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi.
Máa dúpẹ́.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ máa dúpẹ́.”—Kólósè 3:15.
-
Kọ́ ọmọ rẹ láti mọyì ìṣẹ̀dá. Ó yẹ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ láti máa mọyì àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, kí wọ́n sì mọ̀ pé àwọn nǹkan yìí ló ń gbé ẹ̀mí wa ró. Bí àpẹẹrẹ, ká tó lè wà láàyè a nílò afẹ́fẹ́ tá a máa mí símú, omi tá a máa mu àti oúnjẹ tá a máa jẹ. Tó o bá ń fi àwọn àpẹẹrẹ yìí kọ́ àwọn ọmọ rẹ, wọ́n á túbọ̀ mọyì àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run.
-
Kó ọmọ rẹ láti máa mọyì àwọn èèyàn. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé gbogbo èèyàn ló jù ú lọ lọ́nà kan tàbí òmíì àti pé dípò kó máa jowú ẹ̀bùn táwọn ẹlòmíì ní, ó lè kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan lára wọn.
-
Kọ́ ọmọ rẹ láti máa dúpẹ́. Kọ́ ọmọ rẹ láti máa moore kó sì máa sọ pé “ẹ ṣeun” táwọn èèyàn bá ṣe nǹkan fún un, torí pé téèyàn bá ń dúpẹ́ oore, ó máa jẹ́ kéèyàn ní ìrẹ̀lẹ̀.
Kọ́ ọmọ rẹ pé èrè wà nínú kéèyàn máa fara ṣiṣẹ́ fún àǹfààní àwọn míì.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ, bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”—Fílípì 2:3, 4.
-
Fún ọmọ ní iṣẹ́ ilé ṣe. Máa fún un ọmọ rẹ ní iṣẹ́ ilé ṣe kó má bàa rò pé irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ kò tọ́ sí òun. Iṣẹ́ ilé ló yẹ kó kọ́kọ́ ṣe kó tó lọ ṣeré. Sọ àǹfààní tí àwọn ẹlòmíì máa rí nínú iṣẹ́ ilé tó ṣe àti pé wọ́n máa mọyì rẹ̀, wọ́n á sì bọ̀wọ̀ fún un.
-
Jẹ́ kó mọ̀ pé àǹfààní ló jẹ́ láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Táwọn ọmọ bá kọ́ láti máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, á jẹ́ kí wọ́n di ọmọlúwàbí. Torí náà, fún ọmọ rẹ ní ìṣírí pé kó wá ọ̀nà láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Sọ bó ṣe lè ṣe é, tì í lẹ́yìn, kó o sì gbóríyìn fún un bó ṣe ń sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 8 Látinú ìwé náà The Collapse of Parenting.