Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ Ọ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN NI BÍBÉLÌ TI WÁ LÓÒÓTỌ́?

Ṣé Lóòótọ́ Ni “Ọlọ́run Mí Sí” Bíbélì?

Ṣé Lóòótọ́ Ni “Ọlọ́run Mí Sí” Bíbélì?

ṢÉ O gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì? Àbí o rò pé èrò àwọn èèyàn ni wọ́n kàn kọ síbẹ̀?

Ọ̀rọ̀ yìí ti dá awuyewuye sílẹ̀ gan-an, kódà láàárín àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 2014 fi hàn pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ló sọ pé “láwọn ọ̀nà kan, àwọn gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá.” Àmọ́, àwọn míì tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò gbà pé Bíbélì jẹ́ “ìwé ìtàn àròsọ àtijọ́ kan tó jẹ́ pé ọgbọ́n àti ìlànà àwọn èèyàn ló wà níbẹ̀.” Bí èrò àwọn èèyàn ò ṣe ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ yìí lè mú kéèyàn máa béèrè pé, kí wá ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “mí sí” bó ṣe wà nínú Bíbélì?​—2 Tímótì 3:16.

KÍ NI ÌTUMỌ̀ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ “MÍ SÍ”?

Àwọn ìwe kéékèèké mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ló wà nínú Bíbélì, àwọn èèyàn ogójì [40] ló kọ ọ́, ó sì tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [1,600] ọdún tí wọ́n fi kọ ọ́. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn ló kọ Bíbélì, báwo ló ṣe wá jẹ́ pé “Ọlọ́run mí sí” i? Ohun tí ọ̀rọ̀ náà “Ọlọ́run mí sí” Bíbélì túmọ̀ sí ni pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì ti wá. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” (2 Pétérù 1:21) Ìyẹn ni pé, Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún àwọn tó kọ Bíbélì. Ńṣe ni ọ̀rọ̀ náà dà bí ìgbà tí ọ̀gá ilé-iṣẹ́ kan ní kí akọ̀wé òun kọ lẹ́tà kan, tó sì sọ ohun tó fẹ́ kí akọ̀wé náà kọ́ sínú rẹ̀. Akọ̀wé yẹn kọ́ ló ni lẹ́tà náà, ọ̀gá rẹ̀ ló ni ín, torí pé òun ló sọ ohun tó máa kọ sínú lẹ́tà náà.

Àwọn kan lára àwọn tó kọ Bíbélì tiẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ketekete nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì. Ọlọ́run fi ìran han àwọn míì. Ojú àlá ni Ọlọ́run ti bá àwọn míì sọ̀rọ̀. Láwọn ìgbà míì Ọlọ́run máa ń jẹ́ kí àwọn tó kọ Bíbélì lo ọ̀rọ̀ ara wọn, àmọ́ nígbà míì ó máa ń sọ ohun tí wọ́n á kọ gẹ́lẹ́. Torí náà, èrò Ọlọ́run ni àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì kọ sílẹ̀, kì í ṣe èrò ara wọn.

Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn tó kọ Bíbélì? Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀rí mẹ́ta tó mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn tó kọ Bíbélì.