Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 3 2018 | Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀

Báwo ni àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣe lè rí ìtùnú?

Àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí èèyàn ẹni bá kú, ó tún sọ àwọn nǹkan pàtó tó lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń ṣọ̀fọ̀.

 

Ìbànújẹ́ Ńlá Ni Ikú Èèyàn Ẹni Máa Ń Fà

Bóyá ni ohun mí ì wà tó ń fa ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára bí ikú ọkọ, aya, ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ ẹni. Jẹ́ ká gbọ́ ohun táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń ṣèwádìí nípa ẹ̀dùn ọkàn àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí.

Àwọn Nǹkan Tó Lè Ṣẹlẹ̀

Kí ni ìmọ̀lára àtàwọn ìṣòro tó sábà máa ń yọjú nígbà tí èèyàn ẹnì kan bá kú?

Ohun Tó Lè Ran Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Lọ́wọ́

Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ṣọ̀fọ̀ ló ti rí ìrànlọ́wọ́ gbà torí pé wọ́n ṣe àwọn nǹkan tó yẹ.

Ìrànlọ́wọ́ Tó Dára Jù Lọ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀

Bíbélì ló lè pèsè ìrànlọ́wọ́ tó dára jù lọ fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí: Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀

Ìwé Ìròyìn Jí! yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì tó lè ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́.