Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀

Ìrànlọ́wọ́ Tó Dára Jù Lọ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀

Ìrànlọ́wọ́ Tó Dára Jù Lọ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀

LẸ́NU ÀÌPẸ́ YÌÍ, ÀWỌN ÈÈYÀN TI ṢE ÌWÁDÌÍ PÚPỌ̀ NÍPA ỌGBẸ́ ỌKÀN TÍ IKÚ ÈÈYÀN ẸNI MÁA Ń FÀ. Àmọ́, bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, èyí tó dára jù nínú àwọn ìmọ̀ràn táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n máa ń fúnni bá ohun tó wà nínú ìwé àtayébáyé àti ìwé ọgbọ́n náà mu, ìyẹn Bíbélì. Èyí jẹ́ kó ṣe kedere pé kò sígbà tí ìmọ̀ràn inú Bíbélì kì í wúlò. Àmọ́, kì í ṣe àwọn ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé nìkan ló wà nínú Bíbélì. Àwọn nǹkan míì tún wà nínú Bíbélì tó jẹ́ pé a ò lè rí níbòmíì, ó sì ń mú ìtùnú ńlá wá fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀.

  • Ó dájú pé àwọn èèyàn wa tó ti kú kò sí níbì kan tí wọ́n ti ń jìyà

    Oníwàásù 9:5 sọ pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Sáàmù 146:4 náà sì sọ pé ‘àwọn ìrònú wọn ti ṣègbé.’ Ńṣe ni Bíbélì tún fi ikú wé oorun àsùnwọra.​—Jòhánù 11:11.

  • Ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run ìfẹ́ ń tuni nínú

    Bíbélì sọ ní Sáàmù 34:15 pé: “Ojú Jèhófà a ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” Bíbá Ọlọ́run sọ ohun tó wà lọ́kàn wa kì í wulẹ̀ ṣe ohun tó kàn ń mú ara yá gágá lásán, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀nà láti wulẹ̀ sọ èrò ọkàn wa jáde kí ara kàn lè tù wá. Àmọ́, ó jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa, ó sì lè fi agbára rẹ̀ tù wá nínú.

  • Ìgbà ọ̀tun ṣì máa wọlé dé

    Ronú nípa bó ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú nígbà táwọn tó ti kú bá jíǹde pa dà sórí ilẹ̀ ayé níbí! Léraléra ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àkókò tá à ń wí yìí. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa rí lójọ́ iwájú yẹn, ó sọ pé Ọlọ́run ‘yóò nu omijé gbogbo kúrò ní ojú wa, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.’​—Ìṣípayá 21:​3, 4.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí okun gbà gan-an nígbà tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ikú èèyàn wọn, torí wọ́n gba Ọlọ́run tó ni Bíbélì gbọ́, wọ́n sì nírètí pé àwọn ṣì máa rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú pa dà. Bí àpẹẹrẹ, Obìnrin kan tó ń jẹ́ Ann tí ọkọ rẹ̀ kú, tó sì jẹ́ pé wọ́n ti ń bá ara wọn bọ̀ láti ọdún márùndínláàádọ́rin [65] sọ pé: “Bíbélì fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn èèyàn wa tó ti kú kò sí níbì kan tí wọ́n ti ń jìyà, àti pé Ọlọ́run ṣì máa jí gbogbo àwọn tó wà ní ìrántí rẹ̀ dìde. Àwọn nǹkan tó máa ń wá sọ́kàn mi rèé nígbàkigbà tí mo bá ti ń ronú nípa ikú ọkọ mi, ńṣe ni èyí sì máa ń mú kí n lè fara da ohun tó bà mí lọ́kàn jẹ́ jù lọ láyé mi!”

Tiina tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Látìgbà tí Timo ọkọ mi ti kú ni mo ti ń rọ́wọ́ Ọlọ́run lára mi. Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ gan-an lákòókò wàhálà. Mo nígbàgbọ́ tó lágbára pé àwọn òkú máa jíǹde bí Bíbélì ṣe sọ. Èyí ń fún mi lókun láti máa fara dà á nìṣó, títí dìgbà tí màá tún rí Timo pa dà.”

Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí náà rèé lára ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n gbà gbọ́ dájú pé Bíbélì ṣeé gbára lé. Tó bá tiẹ̀ ń ṣe ẹ́ bíi pé àlá tí kò lè ṣẹ ni àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, jọ̀wọ́ ṣe ìwádìí kó o lè mọ̀ bóyá àwọn ìmọ̀ràn àti ìlérí tó wà nínú rẹ̀ ṣeé gbára lé lóòótọ́. Ìwọ fúnra rẹ lè wá rí i pé Bíbélì ló lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú jù lọ.

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA ÌRÈTÍ TÓ WÀ FÚN ÀWỌN TÓ TI KÚ

Wo àwọn fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa èyí lórí ìkànnì wa, jw.org/yo

Bíbélì sọ pé a máa rí àwọn èèyàn wa tó ti kú pa dà lọ́jọ́ iwájú

KÍ LÓ Ń ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN TÓ TI KÚ?

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ń tuni nínú tó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀

Lọ sí OHUN TÁ A NÍ > ÀWỌN FÍDÍÒ (Fídíò: BÍBÉLÌ)

ṢÉ O FẸ́ GBỌ́ ÌRÒYÌN AYỌ̀?

Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé ìròyìn burúkú là ń gbọ́ káàkiri yìí, ibo la ti lè gbọ́ ìròyìn ayọ̀?

Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀLÀÁFÍÀ ÀTI AYỌ̀

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú Bíbélì.