Gbígbọ́ Bùkátà
Ìlànà Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti dín ìṣòro àtirówó gbọ́ bùkátà kù.
NÍ ÈTÒ TÓ DÁA
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere, àmọ́ ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.”—Òwe 21:5.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ó yẹ kó o sapá gidigidi láti máa tẹ̀ lé ètò ìnáwó tó o bá ṣe. Torí náà, kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í náwó, rí i dájú pé o ṣètò bó o ṣe máa ná an. Máa rántí pé kì í ṣe gbogbo ohun tó o fẹ́ lo lè rà lẹ́ẹ̀kan náà. Torí náà, á dáa kó o fọgbọ́n ná owó ẹ.
OHUN TÓ O LÈ ṢE:
-
Máa ṣọ́wó ná. Kọ gbogbo ohun tó o fẹ́ rà sílẹ̀, kó o sì pín wọn sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Lẹ́yìn náà, pín owó tó o fẹ́ ná sí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan. Tó o bá ná ju iye tó o pín sórí ìsọ̀rí kan lọ, yọ díẹ̀ lára owó tó o pín sórí ìsọ̀rí míì láti fi dí i. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ná ju iye tó o rò lọ sórí epo mọ́tò rẹ, yọ lára owó tó o fẹ́ ná sórí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan láti fi dí i, bóyá kó o mú lára owó tó o fẹ́ fi ṣe fàájì.
-
Má ṣe jẹ gbèsè. Tó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti má ṣe yáwó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. Ńṣe ni kó o sapá láti tọ́jú owó pa mọ́ fúnra ẹ títí tó fi máa pé iye tó o fẹ́ fi ra ohun tó o nílò. Tó o bá gbàwìn ọjà, tètè wá bó o ṣe máa sanwó ọjà náà, tó bá sì jẹ́ pé ńṣe lo yáwó, tètè san owó náà pa dà kí èlé tó bẹ̀rẹ̀ sí í gorí ẹ̀. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé àkókò tó o dá ti kọjá, ṣe ìwé fún ẹni tó o jẹ ní gbèsè láti sọ bí wàá ṣe máa san owó náà, kó o sì rí i pé o mú àdéhùn rẹ ṣẹ.
Ìwádìí kan sọ pé àwọn tó máa ń fi káàdì rajà àwìn máa ń náwó púpọ̀ tí wọ́n bá ń ràjà. Torí náà, o ní láti máa kó ara ẹ níjàánu gan-an tó o bá nírú káàdì bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́.
ṢỌ́RA FÁWỌN ÀṢÀ TÓ LÈ KÓ BÁ Ẹ
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ọ̀lẹ kì í túlẹ̀ nígbà òtútù, tó bá dìgbà ìkórè, á máa tọrọ torí pé kò ní nǹkan kan.”—Òwe 20:4.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ìṣẹ́ ló máa ń gbẹ̀yìn ọ̀lẹ. Torí náà, máa ṣiṣẹ́ kára, kó o sì máa ṣọwó ná kó o lè lówó tí wàá ná lẹ́yìnwá ọ̀la.
OHUN TÓ O LÈ ṢE:
-
Ṣiṣẹ́ kára. Tó o bá gbájú mọ́ṣẹ́, tó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, ọgá ẹ á fẹ́ràn ẹ, kò sì ní fẹ́ fi ẹ́ sílẹ̀.
-
Jẹ́ olóòótọ́. Má ṣe ja ọ̀gá ẹ lólè. Ìwà àìṣòótọ́ lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́, kó sì mú kó ṣòro fún ẹ láti ríṣẹ́ míì.
-
Má ṣe jẹ́ olójúkòkòrò. Tó o bá ń lépa owó lójú méjéèjì, o ò ní gbádùn ara ẹ, àjọṣe ẹ pẹ̀lú àwọn míì sì lè bà jẹ́. Máa rántí pé ẹ̀mí ju owó lọ.
ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ
MÁ ṢE FI ÀKÓKÒ ÀTI OWÓ ṢÒFÒ LÓRÍ OHUN TÍ KÒ NÍ LÁÁRÍ.
“Ọ̀mùtí àti alájẹkì yóò di òtòṣì, ìtòògbé yóò sì sọni di alákìísà.”—ÒWE 23:21.
MÁ ṢE MÁA RONÚ JÙ NÍPA OWÓ.
“Ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.”—MÁTÍÙ 6:25.
MÁ ṢE ÌLARA ẸNIKẸ́NI.
“Onílara èèyàn ń wá bó ṣe máa di olówó, kò mọ̀ pé òṣì máa ta òun.”—ÒWE 28:22.