Ohun tó wà nínú ìwé yìí: Ṣé Bíbélì Lè Mú Káyé Ẹ Dáa Sí I?
Ìwé Àtijọ́ Kan Tó Wúlò Lóde Òní
Kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọsìn nìkan ló wà nínú Bíbélì, àìmọye ìmọ̀ràn tó wúlò fún wa lóde òní ló wà níbẹ̀. Lára wọn ni:
Ọ̀rọ̀ ìlera
Bá a se lè jẹ́ onísùúrù
Bá a ṣe lè ní ìdílé aláyọ̀ àti ọ̀rẹ́ àtàtà
Gbígbọ́ bùkátà
Bá a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run
Ìwé Tó Wúlò Jù Lọ Láyé
Láti ọdúnmọ́dún ni Bíbélì ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tó sì ń mú kí ìgbésí ayé wọn dáa sí i. Lónìí, Bíbélì wà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún èdè. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè jàǹfààní látinú ọgbọ́n tó wà nínú rẹ̀.