Kí Ni Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ̀?
Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa bí ọ̀run àti ayé ṣe bẹ̀rẹ̀, ó sọ pé: “Ìtàn ọ̀run àti ayé nìyí, ní àkókò tí Ọlọ́run dá wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:4) Ṣé ohun tí Bíbélì sọ bá ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe mu? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.
Ṣé ayé àti ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀?
Jẹ́nẹ́sísì 1:1 sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.”
Ṣáájú ọdún 1950, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó jẹ́ gbajúmọ̀ ni ò gbà pé ayé àti ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló ti wá gbà pé ayé àti ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀.
Báwo ni ayé ṣe rí níbẹ̀rẹ̀?
Jẹ́nẹ́sísì 1:2, 9 sọ bí ayé ṣe rí níbẹ̀rẹ̀, ó sọ pé ‘ayé wà ní bọrọgidi, ó ṣófo,’ ibú omi sì wà lórí rẹ̀.
Ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe jẹ́ kí wọ́n gbà pé òótọ́ lohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. Patrick Shih tó jẹ́ onímọ̀ nípa ohun alààyè sọ pé ayé yìí ò ṣeé gbé níbẹ̀rẹ̀, torí pé kò sí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn níbẹ̀, kò sì dùn ún wò. Ṣe ló dà bí ibi tí ò wúlò fún ohunkóhun. Ìwé ìròyìn Astronomy sọ pé: “Ìwádìí tá a ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti jẹ́ ká rí i pé omi ló bo gbogbo ayé níbẹ̀rẹ̀, ìwọ̀nba nibi téèyàn sì ti lè rí ilẹ̀ nígbà yẹn.”
Báwo ni nǹkan ṣe yí pa dà lójú ọ̀run?
Jẹ́nẹ́sísì 1:3-5 jẹ́ ká rí i pé nígbà tí ìmọ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tàn sí ayé, èèyàn ò lè rí orísun ìmọ́lẹ̀ náà. Ìgbà tó yá ni oòrùn àti òṣùpá wá bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:14-18.
Bíbélì ò sọ pé wákàtí mẹ́rìnlélógún ló wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọjọ́ mẹ́fà tí Ọlọ́run fi dá ayé
Àjọ Smithsonian Environmental Research Center ṣàlàyé pé ìwọ̀nba ìmọ́lẹ̀ ló lè dé ayé lásìkò yẹn, torí pé ohun tó dà bíi kùrukùru ló wà lójú ọ̀run. Àjọ náà sọ pé: “Gáàsì kan tí wọ́n ń pè ní methane ló wà lójú ọ̀run níbẹ̀rẹ̀.” Nígbà tó yá, “gáàsì náà bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò díẹ̀díẹ̀, kó tó di pé ojú ọ̀run mọ́lẹ̀ kedere.”
Báwo làwọn ohun alààyè ṣe dé ayé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé?
Jẹ́nẹ́sísì 1:20-27 jẹ́ ká mọ̀ pé ẹja ló kọ́kọ́ wà, ẹ̀yìn ìyẹn làwọn ẹyẹ àtàwọn ẹranko tó ń gbé orí ilẹ̀ wà, kó tó di pé èèyàn wà. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé ó pẹ́ táwọn ẹja ti wà káwọn ẹranko orí ilẹ̀ tó wà, wọ́n sì gbà pé àwa èèyàn la dé gbẹ̀yìn.
Bíbélì ò sọ pé àwọn nǹkan alààyè ò lè yí pa dà bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́
Ohun Tí Bíbélì Kò Sọ
Àwọn kan sọ pé ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ sóhun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ṣàwárí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tó nírú èrò yìí ni ò ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ.
Bíbélì ò sọ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún péré ni ayé àti ọ̀run ti wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Bíbélì ò sọ ní pàtó iye ọdún tí ayé àti ọ̀run ti wà.
Bíbélì ò sọ pé wákàtí mẹ́rìnlélógún ló wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọjọ́ mẹ́fà tí Ọlọ́run fi dá ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́” láti tọ́ka sí àwọn àkókò kan. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa “ọjọ́” mẹ́fà tí Jẹ́nẹ́sísì orí 1 sọ pé Ọlọ́run fi dá ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀, Bíbélì pe gbogbo àkókò náà ní “ọjọ́ tí Jèhófà * Ọlọ́run dá ayé àti ọ̀run.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:4) Torí náà, ó ní láti jẹ́ pé ṣe ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn “ọjọ́” mẹ́fà tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fi dá ayé yìí wulẹ̀ ń ṣàpẹẹrẹ àwọn àkókò tó gùn gan-an.
Bíbélì ò sọ pé àwọn nǹkan alààyè ò lè yí pa dà bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé Ọlọ́run dá àwọn ẹranko “ní irú tiwọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:24, 25) Ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí gbòòrò gan-an ju ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rò nípa ẹ̀. Torí náà, “irú” ohun alààyè kan lè wà lóríṣiríṣi, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ohun kan pàtó tó mú kí wọ́n yàtọ̀ síra. Èyí jẹ́ ká rí i pé, bí oríṣi ohun alààyè kan bá ṣe ń pẹ́ sí i lágbègbè kan, ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan kan máa yí pa dà lára ẹ̀, kíyẹn sì mú kó yàtọ̀ sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ “irú” kan náà.
Kí lèrò ẹ?
Bá a ṣe rí i nínú àlàyé tó wà lókè yìí, ọ̀nà tó ṣe tààràtà, tó sì rọrùn láti lóye ni Bíbélì gbà ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀, bí ayé ṣe rí níbẹ̀rẹ̀ àti bí àwọn nǹkan alààyè ṣe débẹ̀. Tí Bíbélì bá wá sọ̀rọ̀ nípa Ẹni tó dá àwọn nǹkan yìí, ṣé kò yẹ ká gbà pé òótọ́ lohun tó sọ? Ìwé Encyclopædia Britannica sọ pé: “Tẹ́nì kan bá gbà pé agbára kan tó ju ti ẹ̀dá èèyàn lọ ló mú káwọn ohun alààyè wà, ohun tẹ́ni náà gbà gbọ́ bá ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní sọ mu.” *