Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Jésù Wà Lóòótọ́?

Ṣé Jésù Wà Lóòótọ́?

KÌ Í ṢE olówó, kì í sì í ṣe èèyàn jàǹkàn láwùjọ. Kódà kò ní ilé tara ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ti tún ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe. Àmọ́, ṣé Jésù Kristi wà lóòótọ́? Kí làwọn onímọ̀ láyé àtijọ́ àti lóde òní sọ nípa Jésù?

  • Michael Grant, tó máa ń sọ ìtàn nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́ sọ pé: “Tá a bá fi ohun tí Bíbélì sọ wé àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́, àá rí i dájú pé Jésù wà lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn ṣe gbà pé àwọn èèyàn olókìkí kan gbé láyé rí.”

  • Rudolf Bultmann, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ májẹ̀mú tuntun nínú Bíbélì sọ pé: “Kò tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu rárá pé kéèyàn máa ṣiyè méjì bóyá Jésù wà àbí kò sí. Èmi ò rò pé ẹni tí orí ẹ̀ pé máa jiyàn irú nǹkan bẹ́ẹ̀ torí pé Jésù ló pilẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni.”

  • Will Durant, tó jẹ́ òpìtàn, òǹkọ̀wé àti onímọ̀ ọgbọ́n orí sọ pé: “Iṣẹ́ ìyanu tó ju gbogbo iṣẹ́ ìyanu lọ ni pé àwọn ọkùnrin mélòó kan [tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere] sọ ohun kan náà tó mọ́gbọ́n dání tó sì tani jí nípa ọkùnrin kan nínú ìwé Ìhìn Rere.”

  • Albert Einstein, tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Jámánì, sọ pé: “Júù ni mí, àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan ló jọ mí lójú nípa ohun tí mo kà nípa ọkùnrin ará Násárétì yìí.” Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó gbà pé Jésù gbé ayé rí lóòótọ́, ó sọ pé: “Kò sẹ́ni tó máa ka ohun tí àwọn ìwé ìhìn rere sọ nípa Jésù tí kò ní gbà pé Jésù wà lóòótọ́.”

    “Kò sẹ́ni tó máa ka ohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa Jésù tí kò ní gbà pé Jésù wà lóòótọ́.”—Albert Einstein

KÍ NI ÌTÀN SỌ?

Àkọsílẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere náà, ìyẹn ìwé Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù, orúkọ àwọn èèyàn tó kọ àwọn ìwé náà ni wọ́n sì fi pè wọ́n. Àmọ́ láfikún sí èyí, àwọn àkọsílẹ̀ míì wà láyé àtijọ́, tí kì í ṣe ti àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni, tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

  • TÁSÍTỌ́SÌ

    (nǹkan bí ọdún 56 sí 120 Sànmánì Kristẹni) Tásítọ́sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlúmọ̀ọ́ká òpìtàn tó gbayì jù lọ nílẹ̀ Róòmù ìgbàanì. Àwọn ìtàn rẹ̀ dá lórí Ilẹ̀ Ọba Róòmù láàárín ọdún 14 sí 68 Sànmánì Kristẹni. (Jésù sì kú ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni) Tásítọ́sì sọ nǹkan kan nínú ìwé kan tó kọ tó fi hàn pé Jésù wà lóòótọ́. Nígbà kan tí iná jó nílùú Róòmù, tó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ lọ́dún 64 Sànmánì Kristẹni, Nérò tó jẹ́ Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù ni gbogbo èèyàn ń pariwo pé ó fà á. Nínú ìwé yẹn, Tásítọ́sì sọ pé: Nérò fẹ̀sùn kan àwọn Kristẹni pé àwọn ló dá iná náà sílẹ̀, “kó lè pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́ àwọn èèyàn lẹ́nu.” Nínú ọ̀rọ̀ tí Tásítọ́sì tún wá sọ, ó ní: “Pọ́ńtíù Pílátù dájọ́ ikú fún Kristi tó dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ lásìkò ìṣàkóso Tìbéríù.”—Annals, XV, 44.

  • SUETONIUS

    (nǹkan bí ọdún 69 sí 122 Sànmánì Kristẹni) Nínú ìwé Lives of the Caesars, tí òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Róòmù yìí ṣe, ó sọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò ìṣàkóso àwọn olú ọba mọ́kànlá àkọ́kọ́ tó jẹ nílẹ̀ Róòmù. Ní apá tó fi sọ̀rọ̀ nípa Kíláúdíù, ó ṣàlàyé pé awuyewuye kan wáyé láàárín àwọn Júù tó ṣeé ṣe kó jẹ́ nípa Jésù. (Ìṣe 18:2) Suetonius sọ pé: “Torí pé àwọn Júù ń fa wàhálà ṣáá nípa Kristi, Kíláúdíù lé wọn kúrò ní Róòmù.” (Ìwé The Deified Claudius, XXV, 4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irọ́ ni Suetonius pa mọ́ Jésù pé òun ló ń dá wàhálà sílẹ̀, síbẹ̀ kò ṣiyè méjì pé Jésù wà.

  • PLINY KÉKERÉ

    (nǹkan bí ọdún 61 sí 113 Sànmánì Kristẹni) Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Róòmù yìí tó tún jẹ́ alákòóso kan ní Bítíníà (orílẹ̀-èdè Tọ́kì báyìí) kọ̀wé sí Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù kan tó ń jẹ́ Trajan, nípa ohun tó máa ṣe sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìpínlẹ̀ rẹ̀. Pliny sọ pé òun fẹ́ fipá mú àwọn Kristẹni láti jáwọ́ nínú ẹ̀sìn Kristẹni àti pé ńṣe lòun máa pa ẹnikẹ́ni tó bá kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní: ‘Ẹni tó bá gbàdúrà sí òrìṣà, tó lo wáìnì tàbí lọ́fíńdà láti júbà ère rẹ tó sì sọ̀rọ̀ òdì sí Kristi, ni mo máa dá sílẹ̀.’Pliny—Letters, Book X, XCVI.

  • FLAVIUS JOSEPHUS

    (nǹkan bí ọdún 37 sí 100 Sànmánì Kristẹni) tó jẹ́ àlùfáà Júù àti òpìtàn, sọ pé Ánásì tó jẹ́ àlùfáà àgbà àwọn Júù tó sì lẹ́nu lágbo ìṣèlú, “pe ìpàdé àwọn adájọ́ Sànhẹ́dírìn, ó sì mú Jákọ́bù arákùnrin Jésù tí wọ́n tún ń pè ní Kristi wá síwájú wọn.”Jewish Antiquities, XX, 200.

  • ÌWÉ TÁMỌ́DÌ

    Àkójọ ìwé àwọn Júù yìí tó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta sí ìkẹfà Sànmánì Kristẹni fi hàn pé àwọn ọ̀tá Jésù pàápàá gbà pé Jésù wà. Apá kan nínú ìwé náà sọ pé “wọ́n kan Jésù ará Násárétì mọ́gi lọ́jọ́ Ìrékọjá.” Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. (ìwé Babylonian Talmud, Sanhedrin 43a, Munich Codex; wo Jòhánù 19:14-16.) Apá míì sọ pé: “A ò ní bí ọmọ ìyà tó máa dójú ti ara rẹ̀ ní gbangba bíi ti ará Násárétì.” Jésù ni wọ́n máa ń pè ní ará Násárétì.—Babylonian Talmud, Berakoth 17b, footnote, Munich Codex; wo Lúùkù 18:37.

ÀWỌN Ẹ̀RÍ LÁTINÚ BÍBÉLÌ

Àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, títí kan àlàyé nípa àwọn èèyàn, ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti wáyé àti àkókò tó wáyé, gbogbo èyí la sì fi ń mọ ìtàn tó jóòótọ́. Àpẹẹrẹ kan wà nínú Lúùkù 3:1, 2, tó jẹ́ ká mọ ọjọ́ náà pàtó tí Jòhánù Oníbatisí, ẹni tó ṣáájú Jésù, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.”2 Tímótì 3:16

Lúùkù sọ pé: “Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tìbéríù Késárì, nígbà tí Pọ́ńtíù Pílátù jẹ́ gómìnà Jùdíà, tí Hẹ́rọ́dù sì jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Gálílì, ṣùgbọ́n tí Fílípì arákùnrin rẹ̀ jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè ilẹ̀ Ítúréà àti Tírákónítì, tí Lísáníà sì jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Ábílénè, ní àwọn ọjọ́ olórí àlùfáà Ánásì àti ti Káyáfà, ìpolongo Ọlọ́run tọ Jòhánù ọmọkùnrin Sekaráyà wá nínú aginjù.” Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé yìí, jẹ́ ká mọ ìgbà tí “ìpolongo Ọlọ́run tọ Jòhánù” wá lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni.

Àwọn èèyàn pàtàkì méje tí Lúùkù dárúkọ wọn yìí kì í ṣe àìmọ̀ fún àwọn òpìtàn. Àmọ́ ìgbà kan wà táwọn alátakò sọ pé kò sẹ́ni tó ń jẹ́ Pọ́ńtíù Pílátù àti Lísáníà. Àmọ́ kò pẹ́ táwọn alátakò yìí fi kó ọ̀rọ̀ wọn jẹ. Wọ́n rí àwọn ohun kan tí wọ́n kọ orúkọ àwọn alákòóso méjèèjì yìí sí, tó fi hàn pé òótọ́ ni Lúùkù sọ. *

KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ?

Jésù kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run tó máa ṣàkóso gbogbo ayé

Ó ṣe pàtàkì ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè nípa bóyá Jésù wà lóòótọ́, torí pé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣe pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè láyọ̀ nígbèésí ayé wọn, táyé wọn á sì nítumọ̀. * Ó tún ṣèlérí àsìkò kan tí gbogbo aráyé á máa gbé lálàáfíà àti ààbò, tí gbogbo wa á sì wà níṣọ̀kan lábẹ́ ìjọba kan táá máa ṣàkóso lórí gbogbo ayé ìyẹn “Ìjọba Ọlọ́run.”Lúùkù 4:43.

Ó tọ́ bá a ṣe ń pe ìjọba yẹn ní “Ìjọba Ọlọ́run” torí òun ló máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn gbà pé Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ lórí ayé. (Ìṣípayá 11:15) Jésù mú kí ọ̀rọ̀ yìí ṣe kedere nínú àdúrà àwòṣe tó gbà, ó ní: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, . . . Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ . . . lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 6:9, 10) Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé? Díẹ̀ lára wọn rè é:

  • Kò ní sí ogun àti ọ̀tẹ̀ mọ́.Sáàmù 46:8-11.

  • Ìwà ìkà, ojúkòkòrò àti ìwà jẹgúdújẹrá, kò ní sí mọ́ títí láé, àwọn ẹni ibi kò ní sí mọ́.Sáàmù 37:10, 11.

  • Àwọn tó bá wà nínú Ìjọba yìí máa ṣe iṣẹ́ tó ń fún ni láyọ̀, tó sí gbádùn mọ́ni. Aísáyà 65:21, 22.

  • Oúnjẹ máa pọ̀ yanturu torí ilẹ̀ máa ti dọ̀tun.Sáàmù 72:16; Aísáyà 11:9.

Àwọn kan lè sọ pé àlá tí kò lè ṣẹ ni àwọn ìlérí wọ̀nyí. Àmọ́, àwa èèyàn la máa ń ṣèlérí tá a sì máa ń yẹ̀ ẹ́. Gbé èyí yẹ̀wò: Pẹ̀lú bí ìmọ̀ ẹ̀kọ́, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ti ṣe tẹ̀ síwájú, síbẹ̀ ọkàn ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ò balẹ̀, wọn ò sì mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Ojoojúmọ́ la sì ń rí i tí ètò ọrọ̀ ajé ń dẹnu kọlẹ̀, tí àwọn olóṣèlú àti àwọn ẹlẹ́sìn sì ń jẹ gàba lé àwọn èèyàn lórí. Bákan náà ni ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà jẹgúdújẹrá ń pọ̀ sí i. Gbogbo èyí jẹ́ ẹ̀rí pé ìjọba èèyàn ti forí ṣánpọ́n!Oníwàásù 8:9.

Kà sòótọ́, bá a ṣe jíròrò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù wà lóòótọ́ ti ṣe wá láǹfààní. *2 Kọ́ríńtì 1:19, 20 ṣe sọ: “Bí ó ti wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ [Kristi].”

^ ìpínrọ̀ 23 Wọ́n ti rí ohun kan tí wọ́n kọ orúkọ “alákòóso kan” tó ń jẹ́ Lísáníà sí lára. (Lúùkù 3:1) Ó ṣàkóso ìlú Ábílénè ní àkókò tí Lúùkù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 25 Irú ẹ̀kọ́ àtàtà tí Jésù fi kọ́ni wà nínú Mátíù orí 5 sí 7, èyí tí wọ́n sábà máa ń pè ní Ìwàásù Orí Òkè.

^ ìpínrọ̀ 32 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa Jésù àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, lọ́ sí ìkànnì wa www.mt1130.com/yo, wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ.