“Yóò Sì Sún Mọ́ Yín”
“Yóò Sì Sún Mọ́ Yín”
“[Ọlọ́run] kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—ÌṢE 17:27.
1, 2. (a) Nígbà tá a bá ń wo ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀, ìbéèrè wo la lè béèrè nípa Ẹlẹ́dàá? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe mú un dá wa lójú pé àwọn èèyàn ò kéré rárá lójú Jèhófà?
ǸJẸ́ o ti gbójú sókè wo ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀ ní alẹ́ kan tójú ọjọ́ mọ́lẹ̀ rekete tí kàyéfì ńlá sì ṣe ọ́ rí? Bí ìràwọ̀ ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ tí gbalasa òfuurufú sì lọ salalu lè múni kún fún ẹ̀rù. Nínú àgbáálá ayé kíkàmàmà yìí, ilé ayé kò ju kékeré bíńtín níbẹ̀. Ǹjẹ́ èyí wá túmọ̀ sí pé Ẹlẹ́dàá, tó jẹ́ “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé,” ti ga ju ẹni tó lè máa ṣàníyàn nípa ẹ̀dá ènìyàn ni àbí pé ńṣe ló jìnnà gan-an tí kò sì sí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà mọ̀ ọ́n?—Sáàmù 83:18.
2 Bíbélì mú un dá wa lójú pé àwọn èèyàn ò kéré rárá lójú Jèhófà. Kódà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú láti wá a, ó sọ pé: “Kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27; 1 Kíróníkà 28:9) Ní ti tòótọ́, tá a bá sapá láti sún mọ́ Ọlọ́run, òun náà ò ní ṣàì kọbi ara sí ìsapá wa. Lọ́nà wo? Ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún wa fún 2003 fún wa ní ìdáhùn amọ́kànyọ̀ yìí pé: “Yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Ẹ jẹ́ ká jíròrò díẹ̀ lára àwọn àgbàyanu ìbùkún tí Jèhófà ń fún àwọn tó sún mọ́ ọn.
Ẹ̀bùn Ti Ara Ẹni Látọ̀dọ̀ Jèhófà
3. Ẹ̀bùn wo ni Jèhófà ń fún àwọn tó sún mọ́ ọn?
3 Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye kan tó ti fi pa mọ́ fún àwọn èèyàn rẹ̀. Gbogbo agbára, ọrọ̀, àti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ètò nǹkan ìsinsìnyí lè fúnni kò lè pèsè ẹ̀bùn yìí. Ẹ̀bùn ti ara ẹni ni, èyí tí Jèhófà ń fún kìkì àwọn tó bá sún mọ́ ọn. Kí ni ẹ̀bùn náà? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáhùn pé: “Bí o bá . . . fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an. Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n.” (Òwe 2:3-6) Fojú inú wò ó ná, pé ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn aláìpé láti rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an”! Ẹ̀bùn yẹn—ìmọ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—la fi wé “ìṣúra fífarasin.” Kí nìdí?
4, 5. Báwo la ṣe lè fi “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an” wé “ìṣúra fífarasin”? Ṣàpèjúwe.
4 Lọ́nà kan, ìmọ̀ Ọlọ́run ṣeyebíye gan-an. Ọ̀kan lára ìbùkún ṣíṣeyebíye jù lọ tó wà níbẹ̀ ni ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 17:3) Àmọ́ ìmọ̀ yẹn ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀ kódà nísinsìnyí pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá à ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ti jẹ́ ká mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì bíi: “Kí ni orúkọ Ọlọ́run? (Sáàmù 83:18) Ipò wo làwọn òkú wà gan-an? (Oníwàásù 9:5, 10) Kí ni ète tí Ọlọ́run fi dá ilẹ̀ ayé àti ìran ènìyàn? (Aísáyà 45:18) A tún ti mọ̀ pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbé ìgbésí ayé ni kéèyàn máa fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò. (Aísáyà 30:20, 21; 48:17, 18) Nípa bẹ́ẹ̀, a ní ìtọ́sọ́nà yíyè kooro tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa kojú àwọn àníyàn ìgbésí ayé yìí àti láti máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà kan tó ń fúnni ní ayọ̀ tòótọ́ àti ìtẹ́lọ́rùn. Lékè gbogbo rẹ̀, ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà ní àti láti sún mọ́ ọn. Kí ló tún lè ṣeyebíye ju àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, èyí tá a gbé karí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an”?
5 Ìdí mìíràn tún wà tó lè mú ká fi ìmọ̀ Ọlọ́run wé “ìṣúra fífarasin.” Bí ọ̀pọ̀ ohun ìṣúra ṣe ṣọ̀wọ́n ni òun náà ò ṣe wọ́pọ̀ nínú ayé yìí. Nínú àwọn bílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn olùjọsìn Jèhófà, tàbí nǹkan bí ẹnì kan nínú ẹgbẹ̀rún èèyàn ló ti rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” Láti ṣàpèjúwe bó ṣe jẹ́ àǹfààní ńlá láti mọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbé ìbéèrè kan ṣoṣo tó jẹ mọ́ Bíbélì yìí yẹ̀ wò: Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn nígbà tó bá kú? Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ọkàn máa ń kú àti pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun. (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹ̀sìn ayé ní ìgbàgbọ́ èké pé ohun kan wà nínú èèyàn tó máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. Ó jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Ó tún gbilẹ̀ nínú ìsìn Búdà, Híńdù, Ìsìláàmù, Jaini, ìsìn àwọn Júù, ìsìn Sikh, Ṣintó àti Tao. Ìwọ rò ó wò ná—àìmọye bílíọ̀nù ènìyàn ni wọ́n mà ti fi ẹ̀kọ́ èké yìí tàn jẹ!
6, 7. (a) Kìkì àwọn wo ló lè rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an”? (b) Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà ti fi òye tó jinlẹ̀ èyí tí ọ̀pọ̀ “àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn olóye” kò mọ̀ jíǹkí wa?
6 Èé ṣe táwọn èèyàn púpọ̀ sí i kò tíì rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an”? Ìdí ni pé kò sẹ́ni tó lè lóye ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìsí ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀. Rántí pé ẹ̀bùn ni ìmọ̀ yìí. Kìkì àwọn tó múra tán láti fi òótọ́ inú àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wá inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Jèhófà sì ń fún ní ẹ̀bùn ọ̀hún. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè máà jẹ́ “ọlọ́gbọ́n nípa ti ara.” (1 Kọ́ríńtì 1:26) Àwọn èèyàn ayé tiẹ̀ lè ka ọ̀pọ̀ lára wọn sí “púrúǹtù àti gbáàtúù.” (Ìṣe 4:13) Síbẹ̀, ìyẹn ò já mọ́ ohunkóhun. “Ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an” ni èrè tí Jèhófà ń san fún wa nítorí àwọn ànímọ́ tó rí nínú ọkàn wa.
7 Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì ló ti tẹ àwọn ìwé rẹpẹtẹ jáde lórí Bíbélì. Irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ lè ṣàlàyé ìtàn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Pẹ̀lú gbogbo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wọn, ǹjẹ́ irú àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an” ní ti gidi? Tóò, ǹjẹ́ wọ́n lóye ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì—ìyẹn dídá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ọ̀run? Ǹjẹ́ wọ́n mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run kì í ṣe ara Mẹ́talọ́kan? Àmọ́ àwa ní tiwa ní ìmọ̀ pípéye lórí irú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ti fún wa ní òye tó jinlẹ̀ nípa òtítọ́ tẹ̀mí èyí tí ọ̀pọ̀ “àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye” kò mọ̀. (Mátíù 11:25) Ẹ ò rí i bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tó sún mọ́ ọn!
“Jèhófà Ń Ṣọ́ Gbogbo Àwọn Tí Ó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀”
8, 9. (a) Báwo ni Dáfídì ṣe ṣàpèjúwe ìbùkún mìíràn tó wà fáwọn tó sún mọ́ Jèhófà? (b) Èé ṣe táwọn Kristẹni tòótọ́ fi nílò ààbò Ọlọ́run?
8 Àwọn tó sún mọ́ Jèhófà tún ń gbádùn ìbùkún mìíràn—ìyẹn ni ààbò Ọlọ́run. Dáfídì onísáàmù nì, tí òun alára ti kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro àti ìpọ́njú, kọ̀wé pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́. Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là. Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 145:18-20) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà wà nítòsí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi lè tètè dá wọn lóhùn nígbà tí wọ́n bá ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́.
9 Èé ṣe tá a fi nílò ààbò Ọlọ́run? Yàtọ̀ sí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ń jẹ nínú ìyà tí “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí ń fà, àwọn gan-an ni olórí Ọ̀tá Ọlọ́run nì, Sátánì Èṣù, tún dìídì dájú sọ. (2 Tímótì 3:1) Ọ̀tá tó gbọ́n ọgbọ́n àrékérekè yẹn ti múra tán ‘láti pa wá jẹ.’ (1 Pétérù 5:8) Sátánì ń ṣe inúnibíni sí wa, ó ń fúngun mọ́ wa, ó sì ń dán wa wò. Ó tún ń wá ọ̀nà láti tibi èrò inú àti ọkàn wa gbá wa mú. Ète rẹ̀ ni pé: kó sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ kó sì ba tiwa jẹ́ nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 12:12, 17) Níwọ̀n bí a ti ní irú ọ̀tá alágbára bẹ́ẹ̀ láti bá wọ̀yá ìjà, ǹjẹ́ kò fi wá lọ́kàn balẹ̀ láti mọ̀ pé “Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀”?
10. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣọ́ àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Irú ààbò wo ló ṣe pàtàkì jù lọ, èé sì ti ṣe?
10 Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣọ́ àwọn èèyàn rẹ̀? Ìlérí tó ṣe pé òun á dáàbò bò wá kò túmọ̀ sí pé a ò ní í ní ìṣòro kankan nínú ètò nǹkan yìí; bẹ́ẹ̀ ni kò túmọ̀ sí pé ó di dandan fún un láti ṣe iṣẹ́ ìyanu nítorí tiwa. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ń pèsè ààbò nípa tara fún àwọn èèyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan. Ó ṣe tán, kò ní gbà láé pé kí Èṣù rẹ́yìn àwọn olùjọsìn tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé! (2 Pétérù 2:9) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jèhófà ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí. Ó ń fún wa ni gbogbo ohun tá a nílò láti fara da àwọn àdánwò àti láti pa àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Lékè gbogbo rẹ̀, ààbò tẹ̀mí ṣì ni ààbò tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kí nìdí? Níwọ̀n ìgbà tá a bá ti ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà, kò sí ohunkóhun—kódà ikú pàápàá—tó lè ṣe ìpalára ayérayé fún wa.—Mátíù 10:28.
11. Àwọn ìpèsè wo ni Jèhófà ti ṣe fún ààbò tẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ̀?
11 Jèhófà ti ṣe ètò tó pọ̀ rẹpẹtẹ fún ààbò tẹ̀mí àwọn tó sún mọ́ ọn. Nípasẹ̀ Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fún wa ní ọgbọ́n tá a fi lè kojú onírúurú àdánwò. (Jákọ́bù 1:2-5) Fífi ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ sílò pàápàá, ààbò ni. Láfikún sí i, Jèhófà tún ń fi “ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí yẹn ni ipá tó lágbára jù lọ ní ọ̀run òun ayé, ìdí nìyẹn tó fi dájú pé ó lè mú wa gbára dì láti kojú àdánwò tàbí inúnibíni èyíkéyìí tó lè dojú kọ wá. Jèhófà tún tipasẹ̀ Kristi pèsè “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn.” (Éfésù 4:8) Àwọn ọkùnrin tó tóótun nípa tẹ̀mí wọ̀nyí ń sapá láti lo ẹ̀mí ìyọ́nú Jèhófà nígbà tí wọ́n bá ń ran àwọn olùjọsìn bíi tiwọn lọ́wọ́.—Jákọ́bù 5:14, 15.
12, 13. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa lákòókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu? (b) Ojú wo lo fi ń wo àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè fún ire wa nípa tẹ̀mí?
12 Jèhófà tún pèsè nǹkan mìíràn láti fi ìṣọ́ ṣọ́ wa: ìyẹn ni oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Mátíù 24:45) Jèhófà ń pèsè ohun tá a nílò fún wa lákòókò tá a nílò wọn nípasẹ̀ àwọn ìwé tá à ń tẹ̀ jáde, títí kan àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àti nípasẹ̀ àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ. Ǹjẹ́ o lè rántí àkókò kan tó o gbọ́ ohun kan tó gún ọkàn rẹ ní kẹ́ṣẹ́ nípàdé Kristẹni kan tàbí ní àpéjọ kan tó sì wá fún ọ lókun tàbí tó tù ọ́ nínú? Ǹjẹ́ o ti ka àpilẹ̀kọ kan nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn tá a mẹ́nu kàn lókè yìí, tó o wá sọ pé ìwọ gan-an ni wọ́n kọ àpilẹ̀kọ náà fún?
13 Ọ̀kan lára àwọn irin iṣẹ́ gbígbéṣẹ́ jù lọ tí Sátánì ń lò ni ìrẹ̀wẹ̀sì, ipa tó ń ní kò sì yọ àwa náà sílẹ̀. Ó mọ̀ pé wíwà ní ipò àìnírètí fún ìgbà pípẹ́ lè sọ wá di aláìlókun, ó tiẹ̀ lè sọ wá di ẹni tọ́wọ́ rẹ̀ lè tètè bà pàápàá. (Òwe 24:10) A nílò ìrànlọ́wọ́ nítorí pé Sátánì máa ń gbìyànjú láti fi èrò òdì múni. Àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! máa ń gbé àwọn àpilẹ̀kọ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbógun ti ìrẹ̀wẹ̀sì jáde lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ọ̀kan lára irú àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ ló mú kí Kristẹni arábìnrin kan kọ̀wé pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni mò ń ka àpilẹ̀kọ náà, kò sì tíì yéé jẹ́ kí omijé dà lójú mi. Mo fi sí ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi kí n lè máa kà á ní gbogbo ìgbà tí mo bá fẹ́ rẹ̀wẹ̀sì. Àwọn àpilẹ̀kọ bí ìwọ̀nyí máa ń jẹ́ kí n rí i pé ọwọ́ ààbò Jèhófà ń gbá mi mọ́ra.” a Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún oúnjẹ tẹ̀mí tó ń fún wa lásìkò? Rántí pé àwọn ìpèsè tó ṣe fún ire tẹ̀mí wa ni ẹ̀rí tó fi hàn pé ó sún mọ́ wa àti pé ó ti fi wá sí abẹ́ ààbò rẹ̀.
Òmìnira Láti Dé Ọ̀dọ̀ “Olùgbọ́ Àdúrà”
14, 15. (a) Ìbùkún ara ẹni wo ni Jèhófà ń fún àwọn tó sún mọ́ ọn? (b) Èé ṣe tí òmìnira tá a ní láti tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà fi jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́?
14 Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé bí agbára àti ọlá àṣẹ táwọn èèyàn ni bá ṣe ń pọ̀ sí i ni wọ́n sábà máa ń di ẹni táwọn ọmọ abẹ́ wọn ò lè sún mọ́? Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run ńkọ́? Ṣe ipò rẹ̀ ga gan-an débi tí ò fi ní lè nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn lásánlàsàn ń bá a sọ? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ẹ̀bùn àdúrà tún jẹ́ ìbùkún mìíràn tí Jèhófà fún àwọn tó sún mọ́ ọn. Bá a ṣe lómìnira àtidé ọ̀dọ̀ “Olùgbọ́ àdúrà” jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́. (Sáàmù 65:2) Kí nìdí?
15 Àpèjúwe kan rèé: Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ńlá kan ní ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀ gan-an. Òun ló máa pinnu àwọn ọ̀ràn tó máa bójú tó fúnra rẹ̀ àti èyí tó máa yàn fáwọn ẹlòmíràn. Bákan náà ni Alákòóso Gíga Jù Lọ láyé òun ọ̀run láǹfààní láti pinnu àwọn ọ̀ràn tó máa fúnra rẹ̀ bójú tó àtàwọn tó máa yàn fáwọn ẹlòmíràn láti ṣe. Ronú nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ti yàn fún Jésù, Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Ó ti fún Ọmọ náà ní “ọlá àṣẹ láti ṣe ìdájọ́.” (Jòhánù 5:27) Ó ti fi àwọn áńgẹ́lì “sábẹ́ rẹ̀.” (1 Pétérù 3:22) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tó lágbára wà lárọ̀ọ́wọ́tó Jésù kó lè ràn án lọ́wọ́ láti dárí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 15:26; 16:7) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lè sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 28:18) Àmọ́, nígbà tó bá kan ọ̀rọ̀ nípa àdúrà wa, Jèhófà ti yàn láti fúnra rẹ̀ bójú tó ìyẹn. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ká darí àdúrà wa sí, ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jésù.—Sáàmù 69:13; Jòhánù 14:6, 13.
16. Èé ṣe tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà wa?
16 Ǹjẹ́ Jèhófà tiẹ̀ máa ń fetí sí àdúrà wa? Tó bá jẹ́ pé kì í gbọ́ àdúrà wa ni, kò ní rọ̀ wá pé ká “máa ní ìforítì nínú àdúrà” tàbí pé ká kó ẹrù ìnira wa àti gbogbo àníyàn wa wá sọ́dọ̀ òun. (Róòmù 12:12; Sáàmù 55:22; 1 Pétérù 5:7) Ó dá àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ tó wà ní àkókò tá a kọ Bíbélì lójú hán-únhán-ún pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà. (1 Jòhánù 5:14) Abájọ tí onísáàmù náà, Dáfídì fi sọ pé: “[Jèhófà] ń gbọ́ ohùn mi.” (Sáàmù 55:17) Kò sídìí kankan tí kò fi yẹ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà sún mọ́ wa, ó sì múra tán láti gbọ́ gbogbo èrò inú àti àníyàn wa.
Jèhófà Ń San Èrè fún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀
17, 18. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ìsìn tòótọ́ táwọn ẹ̀dá rẹ̀ onílàákàyè ń ṣe? (b) Ṣàlàyé bí Òwe 19:17 ṣe fi hàn pé Jèhófà ń kíyè sí àwọn iṣẹ́ àánú tá à ń ṣe.
17 Kò sí ohun táwọn ẹ̀dá ènìyàn lásánlàsàn lè ṣe tàbí ohun tí wọ́n lè kọ̀ láti ṣe tó máa nípa kankan lórí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run tó mọrírì ni Jèhófà. Ó mọyì—àní, ó mọrírì—iṣẹ́ ìsìn tòótọ́ táwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ onílàákàyè ń ṣe. (Sáàmù 147:11) Nítorí náà, àǹfààní mìíràn táwọn tó sún mọ́ Jèhófà ń gbádùn ni pé: Ó ń san ẹ̀san fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Hébérù 11:6.
18 Bíbélì fi hàn kedere pé Jèhófà mọyì ohun táwọn olùjọsìn rẹ̀ ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a kà á pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” (Òwe 19:17) Ìgbatẹnirò aláàánú tí Jèhófà ní fún àwọn ẹni rírẹlẹ̀ hàn kedere nínú Òfin Mósè. (Léfítíkù 14:21; 19:15) Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà nígbà tá a bá fara wé àánú rẹ̀ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Nígbà tá a bá fún àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ní nǹkan, tá ò retí láti gba ohunkóhun padà, Jèhófà ka èyí sí owó tí a yá Òun. Jèhófà ṣèlérí láti fi ojú rere àti ìbùkún san gbèsè náà padà. (Òwe 10:22; Mátíù 6:3, 4; Lúùkù 14:12-14) Bẹ́ẹ̀ ni o, nígbà tá a bá fi ìyọ́nú hàn sí àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa tó jẹ́ aláìní, ó máa ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀. A mà dúpẹ́ o, láti mọ̀ pé Baba wa ọ̀run ń kíyè sí àwọn iṣẹ́ àánú tá à ń ṣe!— Mátíù 5:7.
19. (a) Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé Jèhófà mọrírì ohun tá à ń ṣe nínú iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń san ẹ̀san iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba rẹ̀?
19 Jèhófà dìídì mọrírì ohun tá à ń ṣe nítorí Ìjọba rẹ̀. Nígbà tá a bá sún mọ́ Jèhófà, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé a óò fẹ́ láti fi àkókò wa, agbára wa, àti ohun ìní wa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20) Àwọn ìgbà mìíràn wà tá a lè máa ronú pé ìwọ̀nba àṣeyọrí díẹ̀ là ń ṣe. Ọkàn wa tó jẹ́ aláìpé tiẹ̀ lè mú ká máa ṣiyèméjì nípa pé bóyá inú Jèhófà dùn sí àwọn ìsapá wa tàbí kò dùn sí i. (1 Jòhánù 3:19, 20) Àmọ́ Jèhófà mọrírì gbogbo ẹ̀bùn—tó bá wá látinú ọkàn tí ìfẹ́ sún láti gbégbèésẹ̀—bó ti wù kó kéré tó. (Máàkù 12:41-44) Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 6:10) Láìsí àní-àní, Jèhófà máa ń rántí èyí tó kéré jù lọ pàápàá nínú iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe láti ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn, ó sì ń san èrè fún wa. Yàtọ̀ sí ìbùkún tẹ̀mí tá à ń rí nísinsìnyí, a tún lè fojú sọ́nà fún ayọ̀ wíwà láàyè nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, níbi tí Jèhófà yóò ti fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ṣí ọwọ́ rẹ̀ tí yóò sì tẹ́ ìfẹ́ òdodo tó wà lọ́kàn gbogbo àwọn tó sún mọ́ ọn lọ́rùn!—Sáàmù 145:16; 2 Pétérù 3:13.
20. Báwo la ṣe lè fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa fún ọdún 2003 sọ́kàn jálẹ̀ ọdún yìí, kí ni yóò sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?
20 Jálẹ̀ ọdún 2003 ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká máa bi ara wa léèrè bóyá à ń sapá láìdáwọ́dúró láti sún mọ́ Baba wa ọ̀run. Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè dá wa lójú pé yóò ṣe ohun tó ti ṣèlérí rẹ̀ fún wa. Ó ṣe tán, “Ọlọ́run . . . kò lè purọ́.” (Títù 1:2) Bó o bá sún mọ́ ọn, yóò sún mọ́ ìwọ náà. (Jákọ́bù 4:8) Kí ni yóò sì jẹ́ àbájáde rẹ̀? Àwọn ìbùkún yàbùgà yabuga nísinsìnyí àti ìrètí sísún mọ́ Jèhófà títí ayérayé fáàbàdà!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èyí ni ohun tẹ́nì kan kọ lẹ́yìn tó ka àpilẹ̀kọ náà, “Jèhófà Tóbi Jù Ọkàn-àyà Wa Lọ,” nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ti May 1, 2000, ojú ìwé 28 sí 31.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ẹ̀bùn wo ni Jèhófà ń fún àwọn tó sún mọ́ ọn?
• Ìpèsè wo ni Jèhófà ṣe fún ààbò tẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ̀?
• Kí nìdí tí fífún tá a fún wa lómìnira láti tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà fi jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́?
• Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé Jèhófà mọrírì iṣẹ́ ìsìn tòótọ́ táwọn ẹ̀dá rẹ̀ onílàákàyè ń ṣe?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jèhófà ti fi òye tó jinlẹ̀ nípa òtítọ́ tẹ̀mí jíǹkí wa
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Jèhófà ń pèsè ààbò tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jèhófà sún mọ́ wa, ó sì múra tán láti gbọ́ gbogbo àdúrà wa