Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Àwọn wo ni “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì 6:2, 4 sọ pé wọ́n gbé ayé ṣáájú Ìkún-omi?
Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ni. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ẹsẹ ìkejì ìwé Jẹ́nẹ́sísì orí kẹfà yẹn sọ pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.”—Jẹ́n. 6:2.
Nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, gbólóhùn náà “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” àti “àwọn ọmọ Ọlọ́run” fara hàn nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì 6:2, 4; Jóòbù 1:6; 2:1; 38:7; àti Sáàmù 89:6. Kí ni àwọn ẹsẹ yẹn sọ nípa “àwọn ọmọ Ọlọ́run”?
Ó hàn kedere pé “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” tí ìwé Jóòbù 1:6 mẹ́nu kàn jẹ́ àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n pé jọ síwájú Ọlọ́run. Ọ̀kan lára wọn ni Sátánì tí Bíbélì sọ pé ó ń “lọ káàkiri ní ilẹ̀ ayé.” (Jóòbù 1:7; 2:1, 2) Bákan náà, ìwé Jóòbù 38:4-7 sọ nípa “àwọn ọmọ Ọlọ́run” tí wọ́n “hó yèè nínú ìyìn” nígbà tí Ọlọ́run ‘fi òkúta igun ilẹ̀ ayé lélẹ̀.’ Àwọn ọmọ Ọlọ́run yìí ní láti jẹ́ àwọn áńgẹ́lì nítorí Ọlọ́run kò tíì dá èèyàn nígbà yẹn. “Àwọn ọmọ Ọlọ́run” tí ìwé Sáàmù 89:6 náà mẹ́nu kàn kì í ṣe ẹ̀dá èèyàn, wọ́n ní láti jẹ́ àwọn áńgẹ́lì tó wà ní òkè ọ̀run pẹ̀lú Ọlọ́run.
Àwọn wo wá ni “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì 6:2, 4 sọ̀rọ̀ nípa wọn? Pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí ní àwọn ìpínrọ̀ tó ṣáájú, ó fi hàn pé ó ní láti jẹ́ àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ wá sáyé ni ẹsẹ yìí ń sọ.
Ó ṣòro fáwọn kan láti gbà gbọ́ pé ó lè máa wu àwọn áńgẹ́lì láti ní ìbálòpọ̀. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 22:30 fi hàn pé àwọn tó ń gbé ní ọ̀run kì í ṣègbéyàwó, wọn ò sì ń ní ìbálòpọ̀. Àmọ́ láwọn ìgbà kan, àwọn áńgẹ́lì kan gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n bá àwọn èèyàn jẹ, wọ́n tún bá wọn mu. (Jẹ́n. 18:1-8; 19:1-3) Torí náà, a lè sọ pé láwọn àsìkò tí wọ́n gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ yẹn, ó ṣeé ṣe fún wọn láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin.
Àwọn ẹ̀rí wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé ohun tí àwọn áńgẹ́lì kan ṣe gan-an nìyẹn. Ìwé Júúdà 6, 7 sọ̀rọ̀ nípa ‘àwọn áńgẹ́lì tí kò dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì.’ Ó wá fi ohun tí wọ́n ṣe wé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọkùnrin tó ń gbé ní Sódómù tí wọ́n ṣe àgbèrè àtàwọn ìwà ìbàjẹ́ míì tí kò bá ìwà ẹ̀dá mu. Ohun kan tí àwọn áńgẹ́lì yìí àtàwọn ará Sódómù fi jọra ni pé, gbogbo wọn ni wọ́n ṣe àgbèrè lọ́nà tó lékenkà, tí wọ́n sì hu àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí kò bá ìwà ẹ̀dá mu. Nígbà tí 1 Pét. 3:19, 20 ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì tó ṣàìgbọràn, ó mẹ́nu kan “ọjọ́ Nóà.” (2 Pét. 2:4, 5) Nípa bẹ́ẹ̀, a lè sọ pé ohun tí àwọn áńgẹ́lì tó ṣàìgbọràn ní ọjọ́ Nóà ṣe jọ ẹ̀ṣẹ̀ táwọn ará Sódómù àti Gòmórà dá.
Ibi tá a parí èrò sì yìí bọ́gbọ́n mu gan-an ni, tá a bá lóye rẹ̀ pé “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì 6:2, 4 sọ nípa wọn jẹ́ àwọn áńgẹ́lì tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ tí wọ́n sì bá àwọn obìnrin ṣe ìṣekúṣe.
1 Pét. 3:19) Kí ni ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?
Bíbélì sọ pé Jésù “wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú ẹ̀wọ̀n.” (Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé àwọn ẹ̀mí yìí ni àwọn tí wọ́n “ti jẹ́ aláìgbọràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run ń dúró ní àwọn ọjọ́ Nóà.” (1 Pét. 3:20) Èyí fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ọ̀tẹ̀ rẹ̀ ni Pétérù ń tọ́ka sí. Júúdà náà sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì tí ‘kò dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì.’ Ó wá sọ pé Ọlọ́run “ti fi [wọ́n] pa mọ́ de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá náà pẹ̀lú àwọn ìdè ayérayé lábẹ́ òkùnkùn biribiri.”—Júúdà 6.
Kí làwọn áńgẹ́lì kan ṣe ní ọjọ́ Nóà tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ aláìgbọràn? Ṣáájú Ìkún-omi, àwọn áńgẹ́lì burúkú yìí ṣe ohun tó lódì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n sì wá sáyé. (Jẹ́n. 6:2, 4) Ìyẹn nìkan kọ́, wọ́n tún ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin. Ohun tí wọ́n ṣe yìí lódì pátápátá torí pé Ọlọ́run ò dá àwọn áńgẹ́lì láti máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin. (Jẹ́n. 5:2) Torí náà, tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó ṣàìgbọràn wọ̀nyí ló máa pa run. Àmọ́ ní báyìí, gẹ́gẹ́ bí ìwé Júúdà ṣe sọ, wọ́n wà nínú “òkùnkùn biribiri.” Ṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run fi wọ́n sẹ́wọ̀n.
Ìgbà wo ni Jésù wàásù fún ‘àwọn ẹ̀mí yìí nínú ẹ̀wọ̀n’? Báwo ló sì ṣe ṣe é? Pétérù sọ pé èyí wáyé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde. (1 Pét. 3:18, 19) Tá a bá wo ẹsẹ tó ṣáájú ibi tí Pétérù ti sọ̀ pé Jésù “wàásù,” a máa rí i pé àárín ìgbà tí Jésù jíǹde àti ìgbà tí Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ ni Jésù wàásù fún “àwọn ẹ̀mí nínú ẹ̀wọ̀n.” Èyí wá fi hàn pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ló sọ ìdájọ́ Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀mí burúkú náà, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n. Àwọn ohun tí Jésù sọ fún wọn mú kó ṣe kedere sí wọn pé kò sí ìrètí kankan fún wọn mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kéde ìdájọ́ lé wọn lórí. (Jónà 1:1, 2) Bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, tó sì tún jíǹde fi hàn pé Èṣù kò ní agbára kankan lórí rẹ̀. Èyí ló sì mú kí ẹnú rẹ̀ gbà á láti kéde irú ìdájọ́ mímúná bẹ́ẹ̀ sórí Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.—Jòh. 14:30; 16:8-11.
Láìpẹ́, Jésù máa de Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì burúkú yẹn, á sì sọ wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. (Lúùkù 8:30, 31; Ìṣí. 20:1-3) Ní báyìí ná, wọ́n ṣì wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí, ó sì dájú pé wọ́n máa pa run yàn-an yàn nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Ìṣí. 20:7-10.