Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Amágẹ́dọ́nì Ogun Ọlọ́run Tó Máa Fòpin Sí Gbogbo Ogun

Amágẹ́dọ́nì Ogun Ọlọ́run Tó Máa Fòpin Sí Gbogbo Ogun

Amágẹ́dọ́nì Ogun Ọlọ́run Tó Máa Fòpin Sí Gbogbo Ogun

“Lójú àwọn ẹ̀yà Inuit tó wà nílẹ̀ Greenland, nǹkan burúkú gbáà ni kéèyàn pa èèyàn bíi tiẹ̀, nítorí náà ogun ò bọ́gbọ́n mu lójú tiwọn, ó sì kó wọn nírìíra, kódà kò sóhun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ lédè wọn.”—Ọ̀RỌ̀ TÍ OLÙṢÈWÁDÌÍ FRIDTJOF NANSEN ỌMỌ ILẸ̀ NORWAY SỌ NÍPA Ẹ̀YÀ INUIT NÍLẸ̀ GREENLAND LỌ́DÚN 1888.

TA NI inú rẹ̀ kò ní dùn láti gbé láwùjọ àwọn èèyàn tó ka ogun sí ‘ohun tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì kóni nírìíra’? Ta ni kì í wù kó máa gbé nínú ayé kan tí kò tiẹ̀ sí ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó ń jẹ́ ogun rárá àti rárá? Ó lè dà bíi pé kò lè sírú ayé bẹ́ẹ̀ láéláé, pàápàá tó bá jẹ́ pé ọmọ èèyàn la gbójú lé pé ó máa sọ ayé dà bẹ́ẹ̀.

Àmọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Ọlọ́run ṣèlérí pé ohun tí òun máa ṣe nìyẹn. Ó ní: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:4.

Ó dájú pé kí ìlérí yìí tó lè nímùúṣẹ, àyípadà ní láti bá ayé òde òní. Ìdí ni pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ogun tí wọ́n ń jà káàkiri ayé pọ̀ tó ogún, tí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ogún [20,000,000] èèyàn sì wà lẹ́nu iṣẹ́ ológun. Abájọ tí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè yóò fi dá sí ọ̀ràn aráyé. Ohun tí Jèhófà máa ṣe yìí ló máa yọrí sí ohun tí Bíbélì pè ní ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ìṣípayá 16:14, 16.

Lóòótọ́, àwọn kan fún “Amágẹ́dọ́nì” ní ìtumọ̀ míì tó yàtọ̀ lóde òní, pé ó jẹ́ ogun átọ́míìkì arunlérùnnà tó máa kárí ayé, ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé: “Ó jẹ́ ibi tí ire àti ìwà ibi yóò ti ja ìjà àjàkẹ́yìn, ìjà náà sì máa gbóná.” Ǹjẹ́ ire máa ṣẹ́gun ibi, àbí ohun àròsọ lásán ni ìjà yìí?

Ẹ jẹ́ ká lọ fọkàn balẹ̀ torí Bíbélì sọ ọ́ lásọtúnsọ pé ìwà ibi yóò dópin. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò pa rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé; àti ní ti àwọn ẹni burúkú, wọn kò ní sí mọ́.” (Sáàmù 104:35) Ìwé Òwe náà sọ pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”—Òwe 2:21, 22.

Bíbélì fi hàn kedere pé àwọn ẹni ibi ò ní gbà lójú bọ̀rọ̀, ìdí nìyí tí Ọlọ́run fi máa lo ogun rẹ̀ láti fi fòpin sí gbogbo ìwà ibi, títí kan àwọn ohun búburú tí ogun ti fà. (Sáàmù 2:2) Orúkọ náà Amágẹ́dọ́nì tí Bíbélì pe ogun àrà ọ̀tọ̀ yìí gbàfiyèsí gan-an.

Àwọn Ogun Tí Wọ́n Ti Jà Lágbègbè Mẹ́gídò

Ohun tí Amágẹ́dọ́nì túmọ̀ sí ni “Òkè Ńlá Mẹ́gídò.” Ìlú Mẹ́gídò ìgbàanì àti Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jésíréélì tó yí i ká jẹ́ ibi táwọn èèyàn ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ sí ibi tí wọ́n ti sábà máa ń ja ogun àjàmọ̀gá. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Eric H. Cline tó kọ ìwé The Battles of Armageddon, èyí tó fi sọ̀rọ̀ nípa Amágẹ́dọ́nì, sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, ìlú Mẹ́gídò àti Àfonífojì Jésíréélì ni ibi tí wọ́n ti máa ń ja ogun tí wọ́n á fi mọ ẹni tí agbára ayé máa bọ́ sí lọ́wọ́.”

Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Cline ṣe sọ, àwọn ogun tí wọ́n jà ní àgbègbè Mẹ́gídò sábà máa ń jẹ́ ogun àjàmọ̀gá lóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, àfonífojì Jésíréélì ni wọ́n ti kọ́kọ́ ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun ẹ̀yà Mongol tó ti ṣẹ́gun ibi tó pọ̀ jù lọ ní ilẹ̀ Éṣíà ní èyí tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] ọdún sẹ́yìn. Ìtòsí Mẹ́gídò náà ni àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lábẹ́ Ọ̀gágun Edmund Allenby ti ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Turkey nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Òpìtàn ogun kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun Allenby sọ pé, “ogun yẹn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ogun àjàmọ̀gá tó yára parí jù lọ, tí wọ́n sì ti rẹ́yìn àwọn ọ̀tá pátápátá jù lọ nínú àwọn ogun táráyé ti ń jà.”

Ọ̀pọ̀ ogun àjàmọ̀gá náà ni Bíbélì ròyìn pé wọ́n jà lágbègbè Mẹ́gídò. Bí àpẹẹrẹ, ibẹ̀ ni Bárákì tó jẹ́ Onídàájọ́ ti ṣẹ́gun ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kénáánì lábẹ́ ọ̀gágun Sísérà. (Àwọn Onídàájọ́ 4:14-16; 5:19-21) Gídíónì àti ọ̀ọ́dúnrún [300] ọmọ ogun péré tó ní ṣẹ́gun agbo ọmọ ogun àwọn ará Mídíánì ní àgbègbè yìí kan náà. (Àwọn Onídàájọ́ 7:19-22) Òkè Gíbóà tó wà lágbègbè yìí kan náà ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn Filísínì ti ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, tí wọ́n sì pa Sọ́ọ̀lù Ọba àti Jónátánì ọmọ rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 31:1-7.

Láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún sẹ́yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ni wọ́n ti jà ní Mẹ́gídò àtàwọn àfonífojì tó wà lágbègbè rẹ̀ torí pé ibẹ̀ jẹ́ ibi tó máa ń rọ àwọn ọmọ ogun lọ́rùn láti pitú ọwọ́ wọn. Òpìtàn kan tiẹ̀ ka ogun tó tó mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n tí wọ́n jà níbẹ̀ nìkan!

Láìsí àní-àní, ìtàn Mẹ́gídò àti bí àgbègbè ibẹ̀ ṣe rí nípa lórí bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan péré ni Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà Amágẹ́dọ́nì, ohun tí ìwé Ìṣípayá ń sọ bọ̀ tó fi lò ó jẹ́ kó hàn gbangba pé gbogbo aráyé pátá ló máa kàn.

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Amágẹ́dọ́nì

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ogun tí wọ́n jà ní àgbègbè Mẹ́gídò ni wọ́n fi mọ ẹni tó yẹ kí wọ́n gbà lọ́gàá, síbẹ̀ kò sí èyí tó fòpin sí ìwà ibi. Nítorí kò sí èyíkéyìí nínú ogun yẹn tí wọ́n jà torí àtilè fòpin sí ìwà ibi pátápátá láyé. Ọlọ́run nìkan ló dájú pé ó lè dojú ìjà kọ ìwà ibi lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ohun tí Jésù sì sọ nígbà kan ni pé, “kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run.” (Lúùkù 18:19) Síwájú sí i, Bíbélì sọ ọ́ kedere pé ogun Ọlọ́run ni Amágẹ́dọ́nì.

Ìwé Ìṣípayá sọ pé, a óò kó “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” jọ pọ̀ sí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 16:14) Asọtẹ́lẹ̀ yẹn wá fi kún un pé: “Wọ́n sì kó wọn jọpọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù,” tàbí Amágẹ́dọ́nì. a (Ìṣípayá 16:16) Ìwé Ìṣípayá tún ṣàlàyé síwájú sí i pé “àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn” yóò “kóra jọpọ̀ láti bá ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ja ogun.” (Ìṣípayá 19:19) Ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ dájú pé Jésù Kristi ni ẹni tó jókòó sórí ẹṣin náà.—1 Tímótì 6:14, 15; Ìṣípayá 19:11, 12, 16.

Kí làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí ń jẹ́ kó yé wa? Òun ni pé Amágẹ́dọ́nì jẹ́ ogun tí Ọlọ́run máa bá àwọn ọmọ aráyé aláìgbọràn jà. Kí nìdí tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi fi máa ja ogun yìí? Ìdí kan ni pé, ogun Amágẹ́dọ́nì yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Bákan náà, yóò mú ayé alálàáfíà wá, ìyẹn “ayé tuntun . . . tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Máa Ja Ogun Amágẹ́dọ́nì?

Ǹjẹ́ ó ṣòro fún ọ láti gbà pé Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run ìfẹ́” yóò yan Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” láti jagun? (2 Kọ́ríńtì 13:11; Aísáyà 9:6) Mímọ ohun tó máa sún wọn ja ogun yìí á jẹ́ ká lóye ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Ìwé Sáàmù ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí akọni lójú ogun. Kí nìdí tó fi ń jagun? Onísáàmù náà sọ pé, Kristi ń gẹṣin “nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo.” Ó ń jagun torí pé ó nífẹ̀ẹ́ òdodo, ó sì kórìíra ìwà burúkú.—Sáàmù 45:4, 7.

Bákan náà, Bíbélì sọ bí àìṣèdájọ́ òdodo tó wà nínú ayé yìí ṣe rí lára Jèhófà. Wòlíì Aísáyà sọ pé: “Jèhófà rí i, ó sì burú ní ojú rẹ̀ pé kò sí ìdájọ́ òdodo. Nígbà náà ni ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe, ó sì fi àṣíborí ìgbàlà sí orí rẹ̀. Síwájú sí i, ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ àgbéwọ̀, ó sì fi ìtara bo ara rẹ̀ bí ẹni pé aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá ni.”—Aísáyà 59:15, 17.

Àwọn olódodo èèyàn kò lè ní àlàáfíà àti ààbò níwọ̀n ìgbà tí agbára bá ṣì wà lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi. (Òwe 29:2; Oníwàásù 8:9) Ó dájú pé ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú ò lè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi. Nítorí náà, àyàfi tí Ọlọ́run bá mú àwọn ẹni ibi kúrò ni àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo yóò tó wà. Ìdí nìyí tí Sólómọ́nì fi sọ pé: “Ẹni burúkú ni ìràpadà fún olódodo.”—Òwe 21:18.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni Onídàájọ́, ó dájú pé ìdájọ́ tó tọ́ làwọn ẹni ibi máa gbà. Ábúráhámù béèrè pé: “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” Ohun tí Ábúráhámù wá mọ̀ ni pé, Jèhófà kì í ṣe àìtọ́ lọ́nàkọnà, gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe ohun tó tọ́! (Jẹ́nẹ́sísì 18:25) Síwájú sí i, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kì í dùn mọ́ Jèhófà nínú láti pa àwọn ẹni ibi run, ìgbà tó bá pọn dandan ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìsíkíẹ́lì 18:32; 2 Pétérù 3:9.

Má Fọwọ́ Yẹpẹrẹ Mú Ogun Amágẹ́dọ́nì

Ẹ̀yìn ta la máa wà nínú ogun àjàmọ̀gá yìí? Èyí tó pọ̀ jù nínú wa ló máa sọ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lòun máa wà. Àmọ́ báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la wà? Wòlíì Sefanáyà rọ̀ wá pé: “Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù.” (Sefanáyà 2:3) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4.

Ohun àkọ́kọ́ téèyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ kó tó lè ní ìgbàlà ni òtítọ́ nípa Jèhófà àti ìpinnu rẹ̀ láti mú ìwà ibi kúrò. Ohun kejì tá a máa ṣe ni pé ká jẹ́ olódodo, èyí tí yóò jẹ́ ká rí ojú rere àti ààbò Ọlọ́run.

Tá a bá ṣe ohun méjì tá a sọ yìí, ńṣe la ó máa fojú sọ́nà fún Amágẹ́dọ́nì, ogun Ọlọ́run tó máa fòpin sí ogun aráyé. Nígbà tógun yìí bá sì parí, àwọn èèyàn níbi gbogbo yóò máa wo ogun bí ohun tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì kóni nírìíra. ‘Wọn kì yóò sì kọ́ṣẹ́ ogun mọ́’ láéláé.—Aísáyà 2:4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ bóyá ibi kan ní ti gidi ni Amágẹ́dọ́nì, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé,” lójú ìwé 31.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Ogun tí Ọlọ́run yóò fi dá sí ọ̀rọ̀ aráyé ló ń jẹ́ Amágẹ́dọ́nì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Gídíónì àtàwọn ọkùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun ogun àjàmọ̀gá tí wọ́n jà lágbègbè Mẹ́gídò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

MẸ́GÍDÒ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Lẹ́yìn tí Amágẹ́dọ́nì bá ti kọjá, àwọn èèyàn níbi gbogbo yóò wo ogun bí ohun tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì kóni nírìíra

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ohun àkọ́kọ́ téèyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ kó tó lè ní ìgbàlà ni òtítọ́ nípa Jèhófà àti ìpinnu rẹ̀ láti mú ìwà ibi kúrò