Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?
Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?
ÈDÈ Hébérù, Árámáíkì àti Gíríìkì ìgbàanì ni wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, Bíbélì tí wọ́n ti túmọ̀ sí èdè míì ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn tó bá fẹ́ ka Bíbélì máa rí kà.
Lóde òní, Bíbélì ni ìwé tí wọ́n tíì túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ láyé, wọ́n ti túmọ̀ apá ibì kan nínú rẹ̀ sí èdè tó ju ẹgbẹ̀rún méjì ó lé irínwó [2,400] lọ. Àwọn èdè míì wà tó ní oríṣi Bíbélì kan ṣoṣo, àwọn èdè míì sì ní oríṣiríṣi Bíbélì. Tó bá jẹ́ pé oríṣiríṣi Bíbélì ló wà ní èdè rẹ, ó dájú pé wàá fẹ́ láti ka Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ lọ́nà tó dára jù lọ.
Kó o bàa lè mọ Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ lọ́nà tó dára jù lọ tó yẹ kó o máa kà, ó ṣe pàtàkì pé kó o rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n gbà túmọ̀ Bíbélì? Kí nìdí táwọn ọ̀nà ìtumọ̀ kan fi dáa ju òmíràn lọ? Kí sì nìdí tó fi yẹ kó o kíyè sára nígbà tó o bá ń ka àwọn Bíbélì kan?
Ọ̀nà Tí Wọ́n Gbà Túmọ̀ Bíbélì Yàtọ̀ Síra
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n gbà túmọ̀ Bíbélì, àmọ́ a lè pín ọ̀nà tí wọ́n gbà túmọ̀ rẹ̀ sí mẹ́ta. Ọ̀nà kan ni pé kí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Bí wọ́n ṣe túmọ̀ eléyìí ni pé wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ èdè àbínibí kọ̀ọ̀kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó wà ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Ọ̀nà míì tó jẹ́ òdìkejì ìyẹn ni pé kí wọ́n tún ọ̀rọ̀ inú Bíbélì èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ sọ lọ́nà míì ní èdè àbínibí. Àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n túmọ̀ irú àwọn Bíbélì yìí wulẹ̀ ń ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì bó ṣe yé wọn, ohun tí wọ́n sì rò pé ó máa fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra nìyẹn.
Ọ̀nà kẹ́ta tí wọ́n ń gbà túmọ̀ Bíbélì ni èyí tó mú díẹ̀ lára ọ̀nà èkínní tó sì tún mú díẹ̀ lára ọ̀nà kejì. Àwọn tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì lọ́nà yìí sapá láti túmọ̀ ọ̀rọ̀ àti ẹwà inú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì lọ́nà tó rọrùn láti kà.
Ṣé Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní Ẹyọ Kọ̀ọ̀kan Ló Dára Jù?
Tá a bá fẹ́ kí ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ inú Bíbélì ṣe kedere, a ò ní túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Kí nìdí? Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ pọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára wọn:
1. Kò sí èdè méjì tí gírámà wọn, ọ̀rọ̀ wọn àti ìhun gbólóhùn wọn bára mu délẹ̀délẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú èdè Hébérù tó ń jẹ́ S. R. Driver sọ pé: “Kì í kàn ṣe pé gírámà àti ibi tí ọ̀rọ̀ ti wá yàtọ̀ síra nínú èdè méjì nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún yàtọ̀ . . . nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan di gbólóhùn.” Àwọn tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa ń ní òye ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Driver ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, o sọ pé: “Ìdí nìyẹn tí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan di gbólóhùn nínú oríṣiríṣi èdè fi yàtọ̀ síra.”
Níwọ̀n bí kò ti wá sí èdè tí ọ̀rọ̀ àti gírámà rẹ̀ bá ti èdè Hébérù àti Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì mu, Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan kò ní yé èèyàn, ó sì lè gbé ìtumọ̀ òdì wá. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù, ó lo gbólóhùn kan. Nígbà tí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, ohun tó jẹ́ ni, “nínú ọmọ ayò àwọn èèyàn.” (Éfésù 4:14, The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan) a Gbólóhùn yìí ń sọ nípa báwọn èèyàn ṣe máa ń rẹ́ ara wọn jẹ nígbà tí wọ́n bá ń fi ọmọ ayò ta tẹ́tẹ́. Àmọ́, ní ọ̀pọ̀ èdè, títúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn yìí ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan kò yéèyàn. Ṣùgbọ́n bí Bíbélì kan ṣe túmọ̀ gbólóhùn yìí sí “ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn,” ó túbọ̀ jẹ́ kó yé èèyàn dáadáa.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn ará Róòmù, ó lo gbólóhùn èdè Gíríìkì kan. Nígbà tí wọ́n túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, ohun tó jẹ́ ni “sí ẹ̀mí tó ń hó.” (Róòmù 12:11, Kingdom Interlinear) Ṣé gbólóhùn yìí nítumọ̀ ní èdè rẹ? Ohun tí gbólóhùn yìí wulẹ̀ túmọ̀ sí ni “kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín.”
Nínú ọ̀kan nínú ìwàásù Jésù tó lókìkí, ó lo gbólóhùn kan tí wọ́n sábà máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí: ‘Alábùkún-fún ni àwọn òtòṣi ní ẹ̀mí.’ (Mátíù 5:3) Títúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn yìí ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan kò nítumọ̀ rárá ní ọ̀pọ̀ èdè. Nínú àwọn Bíbélì kan tí wọ́n ti túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn yìí ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, ó tiẹ̀ máa ń fi hàn pé ọpọlọ àwọn “òtoṣi li ẹmí” kò pé, wọ́n ò lókun wọ́n ò sì lè dápinnu ṣe. Àmọ́ ohun tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn ni pé kì í ṣe níní dúkìá ni yóò jẹ́ kí wọ́n láyọ̀, bí kò ṣe mímọ̀ tí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run àti bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé e. (Lúùkù 6:20) Nítorí náà, àwọn Bíbélì tó túmọ̀ gbólóhùn yìí sí “àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” ló sọ ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an.—Mátíù 5:3.
2. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn kan lè yí padà torí àwọn ọ̀rọ̀ tó yí i ká. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n sábà máa ń lò tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọwọ́ èèyàn lè nítumọ̀ oríṣiríṣi. Nígbà míì àwọn ọ̀rọ̀ tó yí i ká lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí “àkóso,” “ẹ̀mí ọ̀làwọ́” tàbí “agbára.” (2 Sámúẹ́lì 8:3; 1 Àwọn Ọba 10:13; Òwe 18:21) Kódà, a túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù yìí sí oríṣi ogójì ọ̀nà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Nítorí pé àwọn gbólóhùn tó yí ọ̀rọ̀ kan ká lè pinnu bá a ṣe máa túmọ̀ rẹ̀, Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì lo àwọn ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì b Kí nìdí tí ìyàtọ̀ fi wà nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì? Ìdí ni pé àwọn ìgbìmọ̀ atúmọ̀ èdè tó túmọ̀ Bíbélì yẹn mọ̀ pé ohun tó dáa jù ni pé káwọn lo àwọn gbólóhùn tó yí ọ̀rọ̀ kan ká láti fi túmọ̀ rẹ̀, kì í ṣe pé káwọn túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn kan ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀ náà, àwọn ìgbìmọ̀ yìí ṣì gbìyànjú débi tí wọ́n lè ṣeé dé láti rí i pé àwọn ò lo àwọn ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì tó pọ̀ jù fún àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n túmọ̀ látinú èdè Hébérù àti ti Gíríìkì.
tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún [16,000] láti fi túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [5,500]. Ó sì lo àwọn ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27,000] láti fi túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [8,500].Ó ṣe kedere pé títúmọ̀ Bíbélì kì í kàn ṣe pé kéèyàn kàn ṣáà ti máa fi ọ̀rọ̀ kan náà túmọ̀ ọ̀rọ̀ kan ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo ibi tó bá ti fara hàn. Àwọn atúmọ̀ èdè gbọ́dọ̀ lo làákàyè nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yan ọ̀rọ̀ tí wọ́n a fi túmọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n bàa lè yan ọ̀rọ̀ tó bá a mu gan-an, táá sì yé èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí wọ́n bá ń túmọ̀ Bíbélì, wọ́n ní láti hun àwọn gbólóhùn wọn lọ́nà tó máa bá ìlànà gírámà èdè àbínibí tí wọ́n ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sí mu.
Bíbélì Tí Wọ́n Tún Àwọn Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Sọ Lọ́nà Míì Ńkọ́?
Àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n tún àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ lọ́nà míì nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Bíbélì máa ń sọ ohun tó yàtọ̀ pátápátá sóhun tó wà nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Lọ́nà wo? Nínú kí wọ́n fi òye tara wọn ṣàlàyé ohun tí wọ́n rò pé èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ń túmọ̀ ń sọ, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ yọ lára àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ kúrò. Nítorí pé Bíbélì tí wọ́n tún ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sọ lọ́nà míì rọrùn láti kà, ó lè fa èèyàn mọ́ra. Àmọ́, akitiyan wọn láti túmọ̀ Bíbélì lọ́nà tó rọrùn láti kà lọ́pọ̀ ìgbà kì í jẹ́ kí ìtumọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe kedere, ó tiẹ̀ lè yí i padà nígbà míì.
Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì kan tí wọ́n tún ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ sọ lọ́nà míì ṣe túmọ̀ àdúrà tí Jésù kọ́ wa, tí gbogbo èèyàn mọ̀ yẹn, ó sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, fi irú ẹni tó o jẹ́ hàn.” (Mátíù 6:9, The Message: The Bible in Contemporary Language lédè Gẹ̀ẹ́sì) Bíbélì míì tó túmọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù yìí lọ́nà tó péye sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” Ẹ tún wo báwọn Bíbélì kan tí wọ́n tún ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ lọ́nà míì ṣe túmọ̀ Jòhánù 17:26. Lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n máa fàṣẹ ọba mú Jésù, ó gbàdúrà sí Baba rẹ̀, ó ní: “Mo jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́.” (Today’s English Version, lédè Gẹ̀ẹ́sì) Ṣùgbọ́n, Bíbélì kan tó túmọ̀ àdúrà Jésù yìí dáadáa bó ṣe wà nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ sọ pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn.” Ǹjẹ́ ẹ wá rí i báwọn atúmọ̀ èdè kan ṣe fi òótọ́ kan pa mọ́, ìyẹn òótọ́ náà pé Ọlọ́run ní orúkọ kan tó yẹ ká máa lò ká sì máa bọ̀wọ̀ fún?
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Kíyè Sára Nípa Irú Bíbélì Tá À Ń Kà?
Bí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn Bíbélì kan tí wọ́n tún ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sọ lọ́nà míì kò jẹ́ ká rí ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kan tó ń jẹ́ The Message: The Bible in Contemporary Language, lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10, pé: “Ṣé ẹ ò mọ̀ pé kì í ṣe bó ṣe yẹ kéèyàn máa ṣayé rèé? Àwọn aláìdáa èèyàn tí wọn ò ka Ọlọ́run sí kò ní dé inú ìjọba rẹ̀. Àwọn tí wọ́n ń ṣe àìdáa sí ọmọnìkejì wọn, tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀ lọ́nà òdì, tí wọ́n ń lo ayé àti gbogbo nǹkan tó wà nínú rẹ̀ nílò àpà, kò ní yẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìjọba Ọlọ́run.”
Ẹ wá fi èyí wé bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe sọ ọ́ lọ́nà tó dáa jù báyẹn lọ, ó ní: “Kínla!
Ẹ kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” Ẹ kíyè sí i pé nínú Bíbélì tí wọ́n tún ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sọ lọ́nà míì, wọn ò mẹ́nu ba àwọn ìwà náà gan-an tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ká yẹra fún.Bí atúmọ̀ èdè kan bá ṣe lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì tún máa ń pinnu bó ṣe máa túmọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀ sọ ọ̀rọ̀ tí Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ báyìí, ó ní: “Ẹ gba ẹnu ọ̀nà tí ó fún wọlé. Ọ̀nà ọ̀run apaadi gbòòrò, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń gba ibẹ̀.” (Mátíù 7:13) Àwọn atúmọ̀ èdè yìí ki ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run apaadi” bọnú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí nígbà tó sì ṣe kedere pé “ìparun” ni Mátíù lò. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí kí wọ́n lè koná mọ́ ẹ̀kọ́ náà pé àwọn ẹni búburú kò ni pa run, àmọ́, a máa dá wọn lóró títí láé ni. c
Bó O Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Rẹ̀ Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ
Ọ̀rọ̀ tí gbogbo onírúurú èèyàn ń lò lójoojúmọ́ ni wọ́n fi kọ Bíbélì. (Nehemáyà 8:8, 12; Ìṣe 4:13) Torí náà, Bíbélì tí wọ́n bá túmọ̀ lọ́nà tó dára á jẹ́ kí gbogbo onírúurú èèyàn tó bá dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ lè kà á, láìka irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ sí. Ó tún máa ṣe àwọn nǹkan tá a sọ wọ̀nyí:
◼ Ó máa túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí lọ́nà tó péye.—2 Tímótì 3:16.
◼ Ó máa túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn kan ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, tó bá máa ṣeé sọ bẹ́ẹ̀ lédè àbínibí.
◼ Ó máa gbé òye ọ̀rọ̀ kan tàbí gbólóhùn kan jáde, tó bá ṣẹlẹ̀ pé títúmọ̀ ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn náà ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan máa yí ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí padà tàbí tó bá máa jẹ́ kó ṣòro láti yé èèyàn.
◼ Ó máa lo ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti yé èèyàn, táá sì mú kó wu èèyàn láti kà.
Ṣé Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀ wà? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn yìí yàn láti máa lo Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Kí nìdí? Nítorí pé wọ́n fara mọ́ ọ̀nà tí ìgbìmọ̀ atúmọ̀ èdè gbà túmọ̀ rẹ̀. Ọ̀nà tí wọ́n gbà túmọ̀ rẹ̀ wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, ó ní: “A kò tún ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ sọ lọ́nà míì. A sapá gan-an láti rí i pé a túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, ìyẹn láwọn ibi tí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì òde òní bá ti gbà wá láyè àti láwọn ibi tí títúmọ̀ ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan kò bá ti ní jẹ́ kó ṣòro láti lóye gbólóhùn náà.”
A ti tẹ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó ju ọgọ́ta lọ, lápapọ̀ iye tá a ti tẹ̀ ju mílíọ̀nù márùnlélógóje [145,000,000] lọ. Níwọ̀n bí Bíbélì yìí ti wà ní èdè Yorùbá, o ò ṣe kúkú sọ pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọ ní ẹ̀dà kan, kó o sì rí àǹfààní tó wà nínú kíka Bíbélì yìí tí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó péye.
Àwọn tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fẹ́ láti ní òye ohun tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, wọ́n sì fẹ́ ṣe ohun tó bá sọ. Tó bá jẹ́ pé irú èèyàn bẹ́ẹ̀ ni ọ́, a jẹ́ pé o nílò Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó péye. Ká sòótọ́, ó yẹ kó o nírú Bíbélì bẹ́ẹ̀, kó o bàa lè máa kà á, kó o sì lóye rẹ̀.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan máa ń jẹ́ kí òǹkàwé rí èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n rí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú rẹ̀.
b Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n túmọ̀ àwọn Bíbélì kan sí èdè Gẹ̀ẹ́sì lo oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ tó pọ̀ ju èyí tí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lò, èyí kò jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò bára mu páàpáà.
c Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni pé téèyàn bá kú, èèyàn máa padà sí erùpẹ̀, pé ọkàn èèyàn máa ń kú, àti pé téèyàn bá ti kú kò ro nǹkan kan mọ́, bẹ́ẹ̀ sí ni kó nímọ̀lára kankan mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Oníwàásù 9:5, 6; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Kò síbì kankan tí Bíbélì ti kọ́ni pé ọkàn ẹni búburú ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú tí iná ọ̀run àpáàdì á sì máa dá a lóró títí láé.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
Nítorí pé Bíbélì tí wọ́n tún ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sọ lọ́nà míì rọrùn láti kà, ó lè fa èèyàn mọ́ra. Àmọ́, akitiyan wọn láti túmọ̀ Bíbélì lọ́nà tó rọrùn láti kà lọ́pọ̀ ìgbà kì í jẹ́ kí ìtumọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe kedere, ó tiẹ̀ lè yí i padà nígbà míì
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
A ti tẹ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó ju ọgọ́ta lọ, lápapọ̀ iye tá a ti tẹ̀ ju mílíọ̀nù márùnlélógóje [145,000,000] lọ
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
BÍ WỌ́N ṢE TÚN Ọ̀RỌ̀ INÚ BÍBÉLÌ SỌ LÁYÉ ÀTIJỌ́
Kì í ṣe ìsinsìnyí ni àṣà títún ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ lọ́nà míì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Láyé àtijọ́, àwọn Júù ṣa àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ jọ, wọ́n sì ṣàlàyé ẹ̀ lọ́rọ̀ ara wọn sínú àwọn ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Aramaic Targums ní ìsinsìnyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé yìí kò péye gẹ́gẹ́ bíi Bíbélì, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ ká rí bí àwọn Júù ṣe lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì kan, èyí sì ran àwọn atúmọ̀ èdè lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe máa túmọ̀ àwọn ẹsẹ kan tó ṣòro láti lóye. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣàlàyé pé “àwọn ọmọ Ọlọ́run” tó wà nínú Jóòbù 38:7, túmọ̀ sí “àwùjọ àwọn áńgẹ́lì.” Nínú Jẹ́nẹ́sísì 10:9, Aramaic Targums jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ tí èdè Hébérù fi ṣàpèjúwe Nímírọ́dù fi hàn pé ó jẹ́ èèyàn burúkú. Ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí “ní ìlòdì sí” tàbí “ní àtakò sí,” dípò “níwájú” tí kò gbé èrò kankan jáde. Wọ́n máa ń lo àwọn àlàyé yìí pẹ̀lú Bíbélì, ṣùgbọ́n wọn ò fìgbà kankan rí lò ó dípò Bíbélì.
[Àwòrán]
JÓÒBÙ 38:1-15 NÍNÚ WALTON’S “BIBLIA POLYGLOTTA,” TÍ WỌ́N PARÍ KÍKỌ RẸ̀ LỌ́DÚN 1657
Bíbélì ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní èdè Hébérù (tí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan sí èdè Látìn)
Ọ̀rọ̀ kan náà rèé nítumọ̀ Aramaic Targum
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
ÉFÉSÙ 4:14, NÍNÚ BÍBÉLÌ “THE KINGDOM INTERLINEAR TRANSLATION OF THE GREEK SCRIPTURES,” TÍ WỌ́N TÚMỌ̀ Ọ̀RỌ̀ INÚ RẸ̀ LỌ́KỌ̀Ọ̀KAN LÉDÈ GẸ́Ẹ̀SÌ
Ìtumọ̀ gbólóhùn ní ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ló wà lápá òsì. Nígbà tí ìtumọ̀ tó yé èèyàn wà ní apá ọ̀tún
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwòrán tó wà lẹ́yìn: Shrine of the Book, Israel Museum, Jerusalem