Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi í Lọ Sójú Ogun?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé
Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi í Lọ Sójú Ogun?
Ibi yòówù káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà, ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti mọ̀ pé wọn kì í lọ́wọ́ sí ogun, yálà èyí táwọn orílẹ̀-èdè ń bára wọn jà ni o tàbí ti ogun abẹ́lé tí wọ́n ń jà lórílẹ̀-èdè wọn. Ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó ń jẹ́ Australian Encyclopædia sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí ọ̀ràn ogun rárá.”
Ìdí pàtàkì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ́wọ́ sí ogún ni pé, lílọ́wọ́ sírú làásìgbò bẹ́ẹ̀ lòdì sí ẹ̀rí ọkàn wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Àṣẹ tí Jésù Kristi Olúwa pa àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ ni wọ́n fi kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wọn. Ó tún pàṣẹ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, láti máa ṣe rere sí àwọn tí ó kórìíra yín.” (Lúùkù 6:27; Mátíù 22:39) Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fẹ́ lo idà láti fi gbèjà Jésù, ó sọ fún un pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù fi hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kò gbọ́dọ̀ lo ohun ìjà ogun rárá.
Ìdí mìíràn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ sójú ogun ni pé àwọn ará wa tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ wà káàkiri ayé. Tá a bá ń lọ sójú ogun, kò sí bá ò ṣe ní dojú ìjà kọ àwọn ara wa, èyí sì lòdì sí àṣẹ tí Jésù pa pé ká ‘nífẹ̀ẹ́ ara wa.’—Jòhánù 13:35.
Kì í ṣe pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn ń fẹnu lásán sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà onífẹ̀ẹ́ yìí ni o, àmọ́ wọ́n tún fi ń ṣèwà hù. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká wo ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, tó wáyé lọ́dún 1939 sí 1945. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọ̀ọ́dúnrún [4,300] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣẹ̀wọ̀n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ sójú ogun. Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, títí kan àwọn obìnrin tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ sójú ogun. Lákòókò tí ìjọba Násì ń ṣàkóso nílẹ̀ Jámánì, nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ó dín ọgbọ̀n [270] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìjọba ṣekú pa nítorí pé wọ́n kọ̀ láti jagun. Nígbà ìjọba Násì, àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n tàbí tí wọ́n fi síbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àṣekú lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000]. Bákan náà, wọ́n fi palaba ìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Japan. Kí gbogbo àwọn tí èèyàn wọn kú nínú Ogun Àgbáyé Kejì tàbí àwọn ogun mìíràn tó jà lẹ́yìn náà mọ̀ dájú pé kò sí ìkankan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lọ́wọ́ sí ikú àwọn èèyàn wọn.
Nínú ọ̀rọ̀ tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Wolfgang Kusserow sọ ṣáájú kí wọ́n tó pa á, ó ṣàlàyé kan tó lágbára nípa ìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ́wọ́ sí ogun. Ní ọdún 1942, ìjọba Násì bẹ́ orí ọmọ ogún ọdún tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì yìí nítorí pé ó kọ̀ láti lọ sójú ogun. (Aísáyà 2:4) Nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́ àwọn ológun, ó sọ pé: “Inú ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, ìlànà Ìwé Mímọ́ tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n sì fi kọ́ mi. Òfin tó tóbi jù lọ tó sì jẹ́ mímọ́ jù lọ tí Ọlọ́run fún ọmọ aráyé ni pé: ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run rẹ ju ohunkóhun mìíràn lọ, kó o sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Òfin mìíràn tún sọ pé: ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn.’ Ṣé àwọn igi ni Ọlọ́run ṣe àwọn òfin yìí fún ni?”—Máàkù 12:29-31; Ẹ́kísódù 20:13.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló máa mú àlàáfíà tó máa wà títí láé wá sórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n ń retí ìgbà tó máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun yóò mú kí “ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 46:9.