Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mímọ Òtítọ́ Nípa Ọ̀run Àpáàdì Ṣe Lè Nípa Lórí Rẹ?

Báwo Ni Mímọ Òtítọ́ Nípa Ọ̀run Àpáàdì Ṣe Lè Nípa Lórí Rẹ?

Báwo Ni Mímọ Òtítọ́ Nípa Ọ̀run Àpáàdì Ṣe Lè Nípa Lórí Rẹ?

IRỌ́ gbuu làwọn tó ń kọ́ni pé Ọlọ́run máa dá àwọn èèyàn lóró ni ọ̀run àpáàdì ń pa mọ́ Jèhófà Ọlọ́run, wọn ò sì sòótọ́ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀. Lóòótọ́, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa pa àwọn ẹni ibi run. (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run máa ń bínú lọ́nà òdodo, ìyẹn kọ́ ni ànímọ́ rẹ̀ tó ta yọ.

Ọlọ́run kì í ṣe òǹrorò. Ó tiẹ̀ béèrè pé: ‘Èmi ha ní inú-dídùn rárá pé kí ènìyàn búburú kí ó kú?’ (Ìsíkíẹ́lì 18:23, Bibeli Ajuwe) Tí kò bá dùn mọ́ Ọlọ́run nínú pé kí èèyàn búburú kú, báwo ló ṣe máa wá dùn mọ́ ọn nínú kó máa wo báwọn wọ̀nyí á ṣe máa joró títí láé?

Ìfẹ́ ló ta yọ jù lọ lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run. (1 Jòhánù 4:8) Ká sòótọ́, ‘OLÚWA ṣeun fún ẹni gbogbo; ìyọ́nú rẹ̀ sì ńbẹ lórí iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.’ (Orin Dáfídì [Sáàmù, Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun] 145:9, Bibeli Ajuwe) Ọlọ́run sì fẹ́ káwa náà fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ òun láti fi hàn pé a mọyì oore rẹ̀.—Mátíù 22:35-38.

Ṣé Torí Pé Ò Ń Bẹ̀rù Ọ̀run Àpáàdì Lo Ṣe Ń Sin Ọlọ́run àbí Torí Pé O Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀?

Ńṣe lohun táwọn èèyàn ń kọ́ni pé ọkàn máa ń joró ní ọ̀run àpáàdì ń jẹ́ káwọn èèyàn máa gbọ̀n jìnnìjìnnì tí wọ́n bá ti gbọ́ nípa Ọlọ́run. Àmọ́, bí ẹnì kan bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, tó sì wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, onítọ̀hún á bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ìwé Orin Dáfídì [Sáàmù, Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun] 111:10 sọ pé: ‘Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n; òye rere ni gbogbo àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ ní: ìyìn rẹ̀ dúró láéláé.’ (Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ kì í ṣe èyí tó máa ń mú kéèyàn máa gbọ̀n jìnnìjìnnì, àmọ́ ó jẹ́ ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá. Èyí ló máa ń jẹ́ ká máa bẹ̀rù láti ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́.

Ẹ jẹ́ ká wo bí kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa ọ̀run àpáàdì ṣe nípa lórí obìnrin kan tó ń jẹ́ Kathleen, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32] tó máa ń loògùn olóró tẹ́lẹ̀. Nígbà kan rí kò mọ̀ ju fàájì, ìwà ipá àti ìṣekúṣe lọ, ó sì máa ń kórìíra ara ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Ó sọ pé: “Nígbà míì tí mo bá ń wo ọmọbìnrin mi tí ò ju ọmọ ọdún kan lọ, ńṣe ló máa ń sọ sí mi lọ́kàn pé, ‘Ẹ wo nǹkan tí mò ń ṣe sọ́mọ yìí. Ṣé kì í ṣe ohun tí màá fi jóná nínú ọ̀run àpáàdì ni mò ń ṣe yìí?’” Kathleen gbìyànjú láti jáwọ́ nínú àṣà lílo oògùn olóró, àmọ́ kò kẹ́sẹ járí. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ jéèyàn rere, àmọ́ gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé mi àti láyé yìí ló ń bà mí lọ́kàn jẹ́. Ó wá dà bíi pé kò sídìí fún mi láti jéèyàn rere.”

Lọ́jọ́ kan Kathleen bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Ó sọ pé: “Wọ́n kọ́ mi pé kò sí iná nínú ọ̀run àpáàdì. Ẹ̀rí tí wọ́n sì fún mi látinú Ìwé Mímọ́ bọ́gbọ́n mu gan-an ni. Bí mo ṣe mọ̀ pé mi ò ní jóná nínú ọ̀run àpáàdì tù mí lára gan-an ni.” Àmọ́, ó tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé èèyàn lè gbé títí láé nínú ayé tí kò ti ní sí ìwà ibi mọ́. (Sáàmù 37:10, 11, 29; Lúùkù 23:43) Tayọ̀tayọ̀ ló fi sọ pé: “Mo ti wá nírètí tó dájú láti gbé títí láé nínú Párádísè báyìí!”

Ní báyìí tí Kathleen ti wá mọ̀ pé kò sí iná nínú ọ̀run àpáàdì, ṣó máa wá fẹ́ jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró? Ó sọ pé: “Nígbà tó bá ń ṣe mí bíi kí n lo oògùn olóró, ńṣe ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run pé kó jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́. Mo máa ń ronú lórí bí irú ìwàkiwà tí mò ń hù yìí ṣe máa rí lójú Jèhófà, mi ò sì fẹ́ já a kulẹ̀. Ó gbọ́ àdúrà mi.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Bí Kathleen ṣe ń bẹ̀rù láti ṣe ohun tí ò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú ló jẹ́ kó lè jáwọ́ nínú àṣà burúkú tó ti sọ di bárakú yìí.

Ó dájú pé bá a bá fi kọ́ra láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tá a sì bẹ̀rù rẹ̀ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, tí kì í ṣe ẹ̀rù ìdálóró nínú ọ̀run àpáàdì ló ń bà wá, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ká bàa lè gbádùn ayọ̀ tó wà títí láé. Onísáàmù kọ̀wé pé: ‘Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa, tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.’—Orin Dáfídì [Sáàmù, Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun] 128:1, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

ÀWỌN WO LÓ MÁA JÁDE WÁ LÁTINÚ Ọ̀RUN ÀPÁÀDÌ?

Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan dojú ọ̀rọ̀ rú nípa bí wọ́n ṣe túmọ̀ Geʹen·na àti Haiʹdes tó jẹ́ ọ̀rọ̀ Gíríìkì méjì tó yàtọ̀ síra, wọ́n pe ọ̀rọ̀ méjèèjì ní “ọ̀run àpáàdì.” Nínú Bíbélì, Geʹen·na túmọ̀ sí ìparun pátápátá, ìyẹn ni ikú tí kò ní àjíńdé. Àmọ́, àwọn tí wọ́n wà nínú Haiʹdes, tàbí Hédíìsì máa jíǹde.

Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jésù kú tí Ọlọ́run sì jí i dìde, àpọ́sítélì Pétérù mú un dá àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ lójú pé Ọlọ́run ò ní fi ọkàn Jésù “sílẹ̀ sínú ọ̀run àpáàdì.” (Ìṣe 2:27, 31, 32; Sáàmù 16:10; ìtúmọ̀ King James Version) Haiʹdes ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ọ̀run àpáàdì” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. Jésù ò lọ sínú iná. Isà òkú ni Hédíìsì tàbí “ọ̀run àpáàdì” túmọ̀ sí. Àmọ́ Jésù nìkan kọ́ ni Ọlọ́run mú jáde látinú Hédíìsì.

Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde, ó sọ pé: ‘Ikú àti Isà-òkú sì yọ̀ọ̀da òkú tí ó wà nínú wọn.’ (Ìfihàn [Ìṣípayá, Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun] 20:13, 14, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Bí kò ṣe ní sí ohunkóhun mọ́ nínú “Isà-òkú” túmọ̀ sí pé Ọlọ́run á jẹ́ kí gbogbo àwọn tó yẹ fún àjíǹde wà láàyè. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ohun àgbàyanu mà là ń retí lọ́jọ́ ọ̀la o, ìyẹn ni bá a ó ṣe máa rí i táwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú á máa jí dìde látinú sàréè! Jèhófà Ọlọ́run ìfẹ́ ló máa ṣe èyí.