Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Gbogbo Ìwòsàn Lọ́nà Ìyanu Ti Wá?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé
Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Gbogbo Ìwòsàn Lọ́nà Ìyanu Ti Wá?
Ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run lágbára láti woni sàn. Òótọ́ sì ni pé ó lè fáwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ lágbára láti woni sàn lọ́nà ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, ìwòsàn lọ́nà ìyanu jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀bùn pàtàkì tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń fúnni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé: “Ìfihàn ẹ̀mí ni a fún olúkúlùkù fún ète tí ó ṣàǹfààní. Fún àpẹẹrẹ, a fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún ẹnì kan nípasẹ̀ ẹ̀mí, . . . a fún òmíràn ní àwọn ẹ̀bùn ìmúniláradá nípasẹ̀ ẹ̀mí kan ṣoṣo náà, . . . a fún òmíràn ní ìsọtẹ́lẹ̀, . . . a fún òmíràn ní onírúurú ahọ́n àjèjì.”—1 Kọ́ríńtì 12:4-11.
Àmọ́, Pọ́ọ̀lù tún sọ nínú lẹ́tà kan náà tó kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì pé ẹ̀bùn ìwòsàn lọ́nà ìyanu tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń jẹ́ kéèyàn ní máa dópin. Ó sọ pé: “Yálà àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ wà, a óò mú wọn wá sí òpin; yálà àwọn ahọ́n àjèjì wà, wọn yóò ṣíwọ́; yálà ìmọ̀ wà, a óò mú un wá sí òpin.”—1 Kọ́ríńtì 13:8.
Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù Kristi àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ woni sàn lọ́nà ìyanu. Nígbà yẹn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, ẹ̀bùn ẹ̀mí àti agbára láti woni sàn máa ń jẹ́ káwọn àpọ́sítélì lè fògo fún Ọlọ́run, ó sì tún ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà fọwọ́ sí ìjọ Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ yìí, ó sì ń bù kún un. Àmọ́, lẹ́yìn tí ìjọ Kristẹni ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa, ẹ̀bùn ẹ̀mí kọ́ làwọn Kristẹni á tún máa tọ́ka sí pé ó jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n á máa tọ́ka sí ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ wọn tó túbọ̀ ń lágbára sí i. (Jòhánù 13:35; 1 Kọ́ríńtì 13:13) Torí náà, nígbà tó di nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] ọdún Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run ò fáwọn èèyàn lágbára láti woni sàn lọ́nà ìyanu mọ́. a
Síbẹ̀, ó lè máa yà ẹ́ lẹ́nu pé, ‘Kí wá nìdí tí mo ṣì fi ń gbọ́ pé àwọn kan ṣì ń ṣèwòsàn lọ́nà ìyanu?’ Bí àpẹẹrẹ, ìròyìn kan sọ nípa ọkùnrin kan tí wọ́n sọ pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Wọ́n sọ pé kókó wà lórí ẹ̀, lára kíndìnrín ẹ̀, kódà ó tún wà nínú egungun ẹ̀. Ó dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ fún un, àfi lọ́jọ́ kan tó sọ pé Ọlọ́run bá òun sọ̀rọ̀. Ìròyìn yẹn sọ pé ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà àrùn jẹjẹrẹ náà pòórá.
Tó o bá gbọ́ irú ọ̀rọ̀ báyìí, o ò ṣe kọ́kọ́ bi ara ẹ pé: ‘Ṣóòótọ́ nìròyìn yìí? Ṣé ẹ̀rí kankan wà lákọọ́lẹ̀ nílè ìwòsàn tó fi hàn pé òótọ́ lẹni yẹn lárùn tí wọ́n sọ pé ó ní? Tó bá sì wá jẹ́ lóòótọ́ lara ọkùnrin náà ti yá, ṣé Bíbélì kọ́ni pé Ọlọ́run ló wà lẹ́yìn gbogbo ohun tó bá ti dà bí ìwòsàn lọ́nà ìyanu?’
Ìdáhùn síbèérè tó kẹ́yìn yìí ṣe pàtàkì gan-an ni. Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké . . . Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.”—Mátíù 7:15, 21-23.
Ẹ̀rí wà nínú Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìwòsàn lọ́nà ìyanu tí wọ́n ń ṣe lónìí lè máà jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Tá ò bá fẹ́ káwọn tó ń forúkọ Ọlọ́run bojú fi iṣẹ́ ìyanu tàn wá jẹ, àfi ká ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, ká lo ọpọlọ tí Ọlọ́run fún wa láti fi ronú, ká sì kọ́ bá a ṣe máa dá àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ mọ̀.—Mátíù 7:16-19; Jòhánù 17:3; Róòmù 12:1, 2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹ̀rí fi hàn pé, lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì ti kú tán, Ọlọ́run ò tún fáwọn èèyàn láwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí kan mọ́, agbára láti woni sàn lọ́nà ìyanu sì ti dópin látìgbà táwọn tó gbà á ti kú.