Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

3 Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Nípa Jésù

3 Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Nípa Jésù

3 Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Nípa Jésù

“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

ÌDÍ TÓ FI ṢÒRO: Àwọn kan máa fẹ́ kó o gbà gbọ́ pé kò sẹ́ni tó ń jẹ́ Jésù. Àwọn míì gbà pé Jésù wá sáyé rí, àmọ́ pé èèyàn bíi tiwa náà ni, ó sì ti kú tipẹ́.

BÓ O ṢE LÈ ṢÀṢEYỌRÍ: Ó máa dáa kó o fara wé ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó ń jẹ́ Nàtáníẹ́lì. a Ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó ń jẹ́ Fílípì ló wá sọ fún un pé ó jọ pé àwọn ti rí Mèsáyà, ìyẹn “Jésù, ọmọkùnrin Jósẹ́fù, láti Násárétì.” Àmọ́, Nàtáníẹ́lì ò wulẹ̀ gba ọ̀rọ̀ Fílípì gbọ́. Ohun tó fi dá Fílípì lóhùn ni pé: “Ohun rere kankan ha lè jáde wá láti Násárétì bí?” Síbẹ̀, ó gbà láti tẹ̀ lé Fílípì nígbà tí Fílípì sọ fún un pé kó “wá wò ó,” fúnra ẹ̀. (Jòhánù 1:43-51) Ìwọ náà máa jàǹfààní tó o bá fúnra ẹ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó wà nípa Jésù. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó wà pé Jésù gbé láyé rí. Òpìtàn táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ni Josephus àti Tacitus, ọ̀rúndún kìíní làwọn méjèèjì gbé láyé, wọn kì í sì í ṣe Kristẹni. Àwọn méjèèjì jẹ́rìí sí i pé Jésù Kristi gbé láyé rí lóòótọ́. Nígbà tí Tacitus ń ṣàlàyé bí Nérò Olú Ọba Róòmù ṣe di ẹ̀bi iná tó jà ní Róòmù lọ́dún 64 Sànmánì Kristẹni ru àwọn Kristẹni, ó kọ̀wé pé: “Nérò sọ pé àwọn ẹgbẹ́ kan táwọn èèyàn ń pè ní Kristẹni ló fa iná tó jà nílùú Róòmù, ó sì fìyà jẹ wọ́n gidigidi, àwọn ará Róòmù kórìíra ẹgbẹ́ yìí gan-an torí àwọn àṣà Kristẹni tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Christus [ìyẹn Kristi] táwọn ẹgbẹ́ yìí fi sọ ara wọn lórúkọ jìyà àjẹkúdórógbó lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn baálẹ̀ wa tó ń jẹ́ Pọ́ńtíù Pílátù nígbà ìjọba Tìbéríù.”

Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica, tí wọ́n ṣe lọ́dún 2002 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí táwọn òpìtàn ọ̀rúndún kìíní àti ìkejì ní nípa Jésù àtàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ó sọ pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ tí ò ṣeé já ní koro wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀ pé láyé ọjọ́un, àwọn tó ń ṣàtakò sáwọn Kristẹni gan-an ò jiyàn pé Jésù ti gbé láyé rí, àfìgbà tí ọ̀rúndún kejìdínlógún [18] ń parí lọ, ọ̀rúndún kọkàndínlógún [19] àti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún [20] táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kọminú pé Jésù ò gbé láyé rí, bẹ́ẹ̀ àwọn ẹ̀rí wọn ò lẹ́sẹ̀-ńlẹ̀.” Lọ́dún 2002, akọ̀ròyìn àgbà ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé: “Yàtọ̀ sáwọn tí ò gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀mọ̀wé ló ti gbà pé Jésù ará Násárétì ti gbé láyé rí.”

Ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí tó wà pé Jésù jíǹde. Nígbà táwọn ọ̀tá Jésù fàṣẹ ọba mú un, àwọn tí wọ́n jọ ń rìn pa á tì, Pétérù tó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ẹ̀ tún lóun ò mọ̀ ọ́n rí nítorí ìbẹ̀rù èèyàn. (Mátíù 26:55, 56, 69-75) Lẹ́yìn tí wọ́n fàṣẹ ọba mú Jésù, ńṣe làwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ tú ká. (Mátíù 26:31) Àmọ́, kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù. Pétérù àti Jòhánù fìgboyà lọ bá àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara wàásù débi pé wọ́n fi ẹ̀kọ́ nípa Jésù kún gbogbo Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ó tẹ́ wọn lọ́rùn láti kú dípò kí wọ́n pa ìgbàgbọ́ wọn tì.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ọ̀kan lára àwọn ohun tó fà á táwọn tó ti fẹsẹ̀ fẹ tẹ́lẹ̀ fi wá ń fìtara wàásù, ó ní Ọlọ́run jí Jésù dìde, ó sì wá “fara han Kéfà [Pétérù], lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà.” Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ pé: “Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó fojú ara wọn rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde ṣì wà láàyè nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. (1 Kọ́ríńtì 15:3-7) Ó lè rọrùn fáwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ láti sọ pé ẹ̀rí ẹnì kan tàbí méjì lára àwọn tọ́rọ̀ náà ṣojú wọn ò lẹ́sẹ̀-ńlẹ̀. (Lúùkù 24:1-11) Àmọ́, bí Jésù ṣe fara han àwọn èèyàn tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lẹ́yìn tó jíǹde jẹ́ ẹ̀rí tí ò ṣeé já ní koro pé Ọlọ́run jí i dìde.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍBẸ̀: Àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú Jésù tí wọ́n sì ṣègbọràn sí i máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, wọ́n sì máa ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Máàkù 2:5-12; 1 Tímótì 1:19; 1 Pétérù 3:16-22) Bí wọ́n bá tiẹ̀ kú, Jésù ti ṣèlérí pé òun máa jí wọn dìde “ní ọjọ́ ìkẹyìn.”—Jòhánù 6:40.

Fún àlàyé síwájú sí i, ka orí 4 tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ta Ni Jésù Kristi?” àti orí 5 tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? b

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bátólómíù ni Mátíù, Máàkù àti Lúùkù pe Nàtáníẹ́lì nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere tí wọ́n kọ.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Bíi ti Nàtáníẹ́lì, ó máa dáa kó o fúnra rẹ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó wà nípa Jésù