Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Gbogbo Ìsìn ni Ìsìn Tòótọ́?

Ṣé Gbogbo Ìsìn ni Ìsìn Tòótọ́?

Ṣé Gbogbo Ìsìn ni Ìsìn Tòótọ́?

INÚ ayé tí ẹ̀sìn tó yàtọ̀ síra ti pọ̀ lọ jàra là ń gbé. Ìwádìí kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé oríṣiríṣi ìsìn pàtàkì mọ́kàndínlógún [19] ló wà kárí ayé, nígbà tí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ẹ̀sìn kéékèèké sì jáde wá látinú àwọn ìsìn pàtàkì wọ̀nyí. Onírúurú ẹ̀sìn wọ̀nyí sì ń lo oríṣiríṣi nǹkan láti fi fa àwọn èèyàn mọ́ra ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Torí náà, ṣé ẹ̀sìn èyíkéyìí tó bá ṣáà ti wu èèyàn ló lè máa ṣe?

Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run kan ṣoṣo là ń sìn, ẹ̀sìn nìkan ló yàtọ̀. Lójú tiwọn, ẹ̀sìn èyíkéyìí tó bá wu èèyàn ló lè máa ṣe, wọ́n gbà pé ibì kan náà ni gbogbo ẹ̀ máa já sí. Wọ́n ronú pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run Olódùmarè kan ṣoṣo ló wà, òun nìkan náà ni gbogbo ẹlẹ́sìn ń ké pè.

Ṣé Gbogbo Ìsìn Ló Ń Sinni Lọ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run?

Kí ni Jésù Kristi tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìsìn táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún jù lọ nínú ìtàn sọ lórí kókó yìí? Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: ‘Ẹ bá ẹnu ọ̀nà híhá wọlé.’ Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé: ‘Gbòòrò ni ẹnu ọ̀nà náà àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. Nítorí híhá ni ẹnu ọ̀nà náà àti tóóró ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.’—Mátíù 7:13, 14, Bibeli Ajuwe.

Ṣóhun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn ìsìn kan lè sin èèyàn lọ sí “ìparun”? Àbí ohun tó ń kọ́ni ni pé àwọn aláìgbàgbọ́ nìkan ló wà lójú ọ̀nà gbòòrò, nígbà táwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ wà lójú ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè, láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí?

Kété lẹ́yìn tí Jésù sọ pé ọ̀nà méjì péré ló wà, ó sọ pé: ‘Ẹ ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tí wọ́n máa wá sọ́dọ̀ yín. Ní òde, wọ́n dà bí àgùntàn, ṣùgbọ́n nínú, ìkookò tí ó ya ẹhànnà ni wọ́n.’ (Mátíù 7:15, Ìròhìn Ayọ̀) Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: ‘Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ń pè mí pé, ‘Olúwa, Olúwa’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe àwọn tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.’ (Mátíù 7:21, Ìròhìn Ayọ̀) Ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé onísìn lẹni táwọn èèyàn bá ń pè ní wòlíì tàbí ẹni tó sọ pé Jésù ni “Olúwa” òun, onítọ̀hún kì í ṣe aláìgbàgbọ́. Èyí jẹ́ kó ṣe kedere pé ńṣe ni Jésù ń kìlọ̀ fún wa pé kì í ṣe gbogbo ìsìn ni ìsìn tòótọ́, kì í sì í ṣe gbogbo ẹni tó bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ló yẹ kéèyàn máa gba ọ̀rọ̀ ẹ̀ gbọ́.

Ṣó Ṣeé Ṣe Láti Mọ Ọ̀nà Tóóró Náà?

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìsìn ni ìsìn tòótọ́, báwo lo ṣe lè mọ èyí tó máa sìn ẹ́ lọ sí ìyè láàárín ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀sìn tó wà? Jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé o sọ nù sí ìlú ńlá kan. Lo bá ní kó o béèrè ọ̀nà. Ẹnì kan tó dá lójú pé òun mọ̀nà sọ fún ẹ pé kó o gba apá ọ̀tún. Ẹlòmíì sọ fún ẹ pé kó o gba apá òsì. Àmọ́ ẹlòmíì sọ fún ẹ pé kó o gba ọ̀nà tó o bá rò pé ó dáa jù. Níkẹyìn, ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ ń rìnrìn àjò mú ìwé atọ́nà kan tó ṣeé gbára lé jáde, ó sì fi ọ̀nà tó yẹ kó o gbà hàn ẹ́. Onítọ̀hún sì wá fi ìwé atọ́nà yẹn lé ẹ lọ́wọ́ kó o lè máa yẹ̀ ẹ́ wò bó o ṣe ń lọ. Ṣé ọkàn ẹ ò ní balẹ̀ pé wàá débi tó ò ń lọ láìsí pé o tún ń sọ nù?

Bákan náà, tó bá kan ọ̀rọ̀ ká yan ìsìn tòótọ́, a nílò ìwé kan tá a lè gbẹ́kẹ̀ lé tó máa tọ́ wa sọ́nà. Ṣérú ìwé bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ wà rárá? Ó dájú pé ó wà. Bíbélì ni ìwé náà tó máa tọ́ wa sọ́nà, Bíbélì sọ pé: ‘Gbogbo Ìwé Mímọ́ tí ó ní ìmísí Ọlọ́run ni ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo.’—2 Tímótì 3:16, Bibeli Mimọ.

Ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì ló wà lédè Yorùbá tó máa tọ́ ẹ sọ́nà láti mọ ìsìn tòótọ́. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe ìwé ìròyìn yìí ti ṣe ìtúmọ̀ Bíbélì kan tó ṣeé gbára lé, ìyẹn ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Àmọ́ tí o kì í bá ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè fẹ́ lo ìtúmọ̀ Bíbélì míì nígbà tó o bá ń ṣèwádìí lórí bó o ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké mọ̀. Ìdí nìyẹn tá a fi lo oríṣiríṣi ìtúmọ̀ Bíbélì, táwọn ẹlẹ́sìn míì ń lò dáadáa nínú àwọn àpilẹ̀kọ́ yìí.

Bó o ṣe ń ka àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, máa fàwọn ohun tó o ti mọ̀ wéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ. Má gbàgbé àwọn ohun tí Jésù sọ nípa bá a ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí ìsìn èké. Ó sọ pé: ‘Igi rere ní í so èso rere; ṣùgbọ́n igi búburú ní í so èso búburú. Igi rere kò lè so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò sì lè so èso rere.’ (Mátíù 7:17, 18, Bibeli Ajuwe) Jẹ́ ká wo mẹ́ta péré nínú àwọn èso rere tí Bíbélì sọ pé a máa fi dá “igi rere” mọ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Bíbélì dà bí ìwé atọ́nà tó ṣeé gbára lé tó lè jẹ́ kéèyàn mọ ìsìn tòótọ́