Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Jésù Àti Bàbá Rẹ̀ Ṣe Jẹ́ Ọ̀kan?

Báwo Ni Jésù Àti Bàbá Rẹ̀ Ṣe Jẹ́ Ọ̀kan?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Báwo Ni Jésù Àti Bàbá Rẹ̀ Ṣe Jẹ́ Ọ̀kan?

Jésù sọ pé: “Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.” (Jòhánù 10:30) Àwọn kan máa ń tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì yìí láti fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn pé Jésù àti Bàbá rẹ̀ jẹ́ ẹni méjì tó jẹ́ apá kan mẹ́talọ́kan. Ṣóhun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí?

Jẹ́ ká gbé àyíká ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò. Ní ẹsẹ 25, Jésù sọ pé ní orúkọ Bàbá òun ni òun ṣàwọn iṣẹ́ tóun ṣe. Láti ẹsẹ 27 sí 29, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹni bí àgùntàn tí Bàbá fún òun. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí kò ní yé àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo lòun àti Bàbá rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé, ‘Òun àti Bàbá òun wà níṣọ̀kan débi pé kò sẹ́ni tó lè gba àwọn àgùntàn náà lọ́wọ́ òun bí kò ṣe sẹ́ni tó lè gbà wọ́n lọ́wọ́ Bàbá.’ Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ọmọ kan bá ń sọ fún ọ̀tá Bàbá ẹ̀ pé, ‘Èmi lò ń bá jà tó o bá bá bàbá mi jà.’ Kò sẹ́ni tó máa sọ pé ẹnì kan náà ni ọmọ yìí àti bàbá rẹ̀. Àmọ́, gbogbo èèyàn ló máa rí i pé àjọṣe tó wà láàárín wọn lágbára gan-an.

Jésù àti Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ̀ jẹ́ “ọ̀kan” ní ti pé àárín wọn wọ̀ débi pé kò sí ìyàtọ̀ nínú àfojúsùn wọn, ìlànà wọn àtàwọn ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì. Láìdàbí Sátánì Èṣù àtàwọn tọkọtaya àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, Jésù ò fìgbà kankan rí fẹ́ láti kúrò lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run. Jésù ṣàlàyé pé: “Ọmọ kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bí kò ṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe. Nítorí ohun yòówù tí Ẹni yẹn ń ṣe, nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ ń ṣe pẹ̀lú lọ́nà kan náà.”—Jòhánù 5:19; 14:10; 17:8.

Àmọ́ ìṣọ̀kan tó lágbára tó wà láàárín Ọlọ́run àti Jésù Ọmọkùnrin rẹ̀ yìí kò ní ká máà dá wọn mọ̀ yàtọ̀. Ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló ní ìwà tiẹ̀. Ó ní bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jésù, ó láwọn ohun tó ń rò, ó láwọn ìrírí tiẹ̀, ó sì lómìnira láti yan ohun tó bá fẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ó yàn láti ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀. Jésù sọ nínú ìwé Lúùkù 22:42 pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” Ohun tó sọ yìí kò ní nítumọ̀ ká ní Jésù ò lómìnira láti yan ohun tó yàtọ̀ sí ohun tí Bàbà rẹ̀ fẹ́. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni kò sí ìyàtọ̀ kankan láàárín Jésù àti Bàbá rẹ̀, kí nìdí tí Jésù fi gbàdúrà sí Ọlọ́run, kí sì nìdí tó fi fìrẹ̀lẹ̀ gbà pé àwọn nǹkan kan wà tó jẹ́ pé Bàbá òun nìkan ló mọ̀ ọ́n?—Mátíù 24:36.

Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn ló ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run tí ìtàn fi hàn pé wọ́n bá àwọn ìdílé tiwọn fúnra wọn ṣaáwọ̀, tí wọ́n sì bá wọn jà. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Gíríìkì, Cronus já ìṣàkóso gbà lọ́wọ́ Uranus tó jẹ́ bàbá ẹ̀, ó sì pa ọmọ tó bí jẹ. Ẹ ò rí i pé èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìṣọ̀kan tó dá lórí ìfẹ́ tòótọ́ tó wà láàárín Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Ọmọ rẹ̀! Ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn yìí ló sì jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ wọn. Ká sòótọ́, àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní láti wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn Ẹni méjì tó ga jù lọ láyé àtọ̀run. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó bẹ bàbá rẹ̀ pé: “Kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa.”—Jòhánù 17:20, 21.

Torí náà, kì í ṣe àdììtú Mẹ́talọ́kan ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan,” ohun tó ń sọ ni ìṣọ̀kan tó lágbára, ìyẹn àjọṣe tímọ́tímọ́ tó máa ń wà láàárín ẹni méjì.