Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Wọ́n Ṣe Pàdánù Párádísè

Bí Wọ́n Ṣe Pàdánù Párádísè

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Bí Wọ́n Ṣe Pàdánù Párádísè

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 3:1-24.

Kí lo rò pé Éfà kọ́kọ́ ṣe nígbà tí ejò yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ̀rọ̀?

․․․․․

Bó o ti ṣe mọ̀ pé ṣe ni Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, báwo lo ṣe rò pé ọ̀rọ̀ náà rí lára wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 7 sí 10 ṣe sọ?

․․․․․

Báwo lo ṣe rò pé nǹkan ṣe rí nígbà tí wọ́n lé Ádámù àti Éfà kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 22 sí 24 ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀?

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Báwo ni ojú Éfà ṣe wà lára ohun tó kó bá a? (Tún ẹsẹ 6 kà.)

․․․․․

Kí nìdí tí èso náà fi di ohun “tí ojú [Éfà] ń yánhànhàn fún”? (Tún ẹsẹ 4 àti 5 kà.)

․․․․․

Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí Ádámù náà lọ́wọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ Éfà? (Tún ẹsẹ 6 kà.)

․․․․․

Ipa búburú wo ni ẹ̀ṣẹ̀ máa ní lórí ìran èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin? (Tún ẹsẹ 16 kà.)

․․․․․

Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti Éfà ti dá wàhálà sílẹ̀ láàárín wọn? (Tún ẹsẹ 12 kà.)

․․․․․

Báwo ni Jèhófà ṣe dá sí ọ̀ràn náà ní kíákíá kí ohun tó ní lọ́kàn bàa lè yọrí sí rere? (Tún ẹsẹ 15 kà.)

․․․․․

MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. KỌ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ewu tó wà nínú ẹ̀mí kí èèyàn fẹ́ wà ní òmìnira.

․․․․․

Bí ojú ẹni ṣe lè jẹ́ kí èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ro èròkerò.

․․․․․

Ìdí tí kò fi bá ọgbọ́n mu láti máa di ẹ̀bi àṣìṣe wa ru àwọn ẹlòmíì.

․․․․․

KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․