Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Jésù Ni Máíkẹ́lì Olú Áńgẹ́lì?

Ṣé Jésù Ni Máíkẹ́lì Olú Áńgẹ́lì?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ṣé Jésù Ni Máíkẹ́lì Olú Áńgẹ́lì?

▪ Ní kúkúrú, bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn náà. Ó wọ́pọ̀ nínú ọ̀pọ̀ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kí wọ́n máa pe èèyàn ní orúkọ tó ju ẹyọ kan lọ. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn tá a dárúkọ wọn nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, orúkọ míì tí Jékọ́bù baba ńlá ń jẹ́ ni Ísírẹ́lì. (Jẹ́nẹ́sísì 35:10) Orúkọ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n pe àpọ́sítélì Pétérù, àwọn ni, Símíónì, Símónì, Pétérù, Kéfà àti Símónì Pétérù. (Mátíù 10:2; 16:16; Jòhánù 1:42; Ìṣe 15:7, 14) Báwo ló ṣe dá wa lójú pé Jésù ni wọ́n tún ń pè ní Máíkẹ́lì? Gbé àwọn ẹ̀rí inú Ìwé Mímọ́ yìí yẹ̀ wò.

Ibi márùn-ún ni Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ńlá tó ń jẹ́ Máíkẹ́lì. Mẹ́ta lára wọn wà nínú ìwé Dáníẹ́lì. Ní Dáníẹ́lì 10:13, 21, a kà nípa bí Máíkẹ́lì ṣe gba áńgẹ́lì kan tí wọ́n rán níṣẹ́ sílẹ̀. Bíbélì pe Máíkẹ́lì yìí ní “ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú pátápátá” àti “ọmọ aládé yín.” Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ ní Dáníẹ́lì 12:1, pé ní àkókò òpin, “Máíkẹ́lì yóò dìde dúró, ọmọ aládé ńlá tí ó dúró nítorí àwọn ọmọ àwọn ènìyàn rẹ.”

A tún mẹ́nu ba Máíkẹ́lì nínú Ìṣípayá 12:7, pé “Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀” ń ja ogun pàtàkì kan tó mú kí wọ́n lé Sátánì Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì burúkú rẹ̀ kúrò ní ọ̀run.

Kíyè si pé ní gbogbo ibi tá a ti mẹ́nu kan Máíkẹ́lì yìí, ó jẹ́ jagunjagun áńgẹ́lì tó ń jà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run, tó sì ń dáàbò bò wọ́n, kódà ó dojú kọ Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá Jèhófà tó lágbára jù lọ.

Ìwé Júúdà ẹsẹ 9 pe Máíkẹ́lì ní “olú-áńgẹ́lì.” Ọ̀rọ̀ ìṣáájú náà, “olú” túmọ̀ sí “olórí,” wọn kò sì lo ọ̀rọ̀ náà, “olú-áńgẹ́lì” fún ẹni méjì rí nínú Bíbélì. Ẹsẹ Bíbélì míì tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa olú áńgẹ́lì ni 1 Tẹsalóníkà 4:16, níbi tí Pọ́ọ̀lù ti sọ̀rọ̀ nípa Jésù tó jíǹde, ó ní: “Olúwa [Jésù] fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú-áńgẹ́lì àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run.” Nítorí náà, Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ni ibí yìí pè ní olú-áńgẹ́lì tàbí olórí áńgẹ́lì.

Lójú gbogbo ohun tá a ti ń sọ bọ̀ yìí, ibo la lè parí èrò wa sí? Òun ni pé, Jésù Kristi ni Máíkẹ́lì olú áńgẹ́lì. Orúkọ méjèèjì, ìyẹn Máíkẹ́lì (tó túmọ̀ sí “Ta Ni Ó Dà Bí Ọlọ́run?”) àti Jésù (tó túmọ̀ sí “Ti Jèhófà Ni Ìgbàlà”), dá lórí ipa tí Jésù ń kó gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú àwọn tó ń ṣalágbàwí ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ìwé Fílípì 2:9 sọ pé: “Ọlọ́run [gbé Jésù tá a ṣe lógo] sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.”

Ó ṣe pàtàkì ká fi sọ́kàn pé kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bí Jésù sáyé ni ìwàláàyè rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Kí Màríà tó bí Jésù, áńgẹ́lì kan wá sọ́dọ̀ Màríà, ó sọ fún un pé yóò lóyún nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ àti pé kí ó pe ọmọ náà ní Jésù. (Lúùkù 1:31) Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìwàláàyè rẹ̀ kí wọ́n tó bí i sáyé.—Jòhánù 3:13; 8:23, 58.

Nítorí náà, Jésù ni Máíkẹ́lì olú áńgẹ́lì ṣáájú kí wọ́n tó bí i sáyé. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bíi Máíkẹ́lì, olórí áńgẹ́lì “fún ògo Ọlọ́run Baba.”—Fílípì 2:11.