Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ Gbogbo Òtítọ́ Nípa Jésù fún Wa?

Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ Gbogbo Òtítọ́ Nípa Jésù fún Wa?

Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ Gbogbo Òtítọ́ Nípa Jésù fún Wa?

Ṣé òótọ́ ni Jésù kú ní Gọ́gọ́tà gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ àbí kò tiẹ̀ kú rárá? Ṣé òótọ́ ni pé Jésù gbé Màríà Magidalénì níyàwó tó sì bí àwọn ọmọ fún un? Àbí aláwo tó ń ṣẹ́ra rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́ tí kò nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo ìgbádùn ayé ni Jésù? Ṣé òótọ́ ni pé Jésù fi ẹ̀kọ́ tó yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn?

IRÚ àwọn èrò bẹ́ẹ̀ gbilẹ̀ gan-an láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Ara ìdí tí èrò yìí sì tún fi yọjú ni pé àwọn fíìmù àti àwọn ìwé tó gbajúmọ̀ ń gbé wọ́n jáde. Yàtọ̀ sí ìtàn àròsọ tó lárinrin, ọ̀pọ̀ ìwé àti àpilẹ̀kọ tún wà tí wọ́n dá lórí àwọn ìwé àpókírífà, ìyẹn àwọn ìwé tí kò ní ìmísí Ọlọ́run tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì àti ìkẹta Sànmánì Kristẹni, wọ́n sọ pé àwọn ìwé yìí ní àwọn òtítọ́ kan nípa Jésù tí kò sí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì. Ṣé òótọ́ ni ohun tí wọ́n sọ yẹn? Ǹjẹ́ ó dá wa lójú pé Bíbélì sọ gbogbo òtítọ́ nípa Jésù fún wa?

Láti lè dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, á dára ká gbé àwọn kókó pàtàkì mẹ́ta kan yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́, ó yẹ ká mọ àwọn nǹkan pàtàkì nípa àwọn ọkùnrin tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere àti ìgbà tí wọ́n kọ wọ́n. Èkejì, ó yẹ ká mọ àwọn tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo ìwé inú Bíbélì jẹ́ ìwé tó ní ìmísí Ọlọ́run àti bó ṣe rí bẹ́ẹ̀. Ìkẹta, ó yẹ ká mọ bí wọ́n ṣe kọ àwọn ìwé àpókírífà àti bí wọ́n ṣe yàtọ̀ sí àwọn ìwé onímìísí. a

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, Àwọn Wo Ló sì Kọ Ọ́?

Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti wí, ọdún kẹjọ lẹ́yìn ikú Kristi ni wọ́n kọ ìwé Ìhìn Rere Mátíù, ìyẹn ní nǹkan bí ọdún 41 Sànmánì Kristẹni. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ló fara mọ pé ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni wọ́n kọ ọ́, àmọ́ ohun tí àwọn èèyàn fẹnu kò sí ni pé gbogbo Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ni wọ́n ti kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, ìyẹn nǹkan bí ọdún márùn-dín-láàádọ́rin [65] lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀.

Àwọn tí wọ́n rí Jésù nígbà tó wà láyé, tí wọ́n mọ ìgbà tó kú àti ìgbà tó jíǹde ṣì wà láyé nígbà yẹn. Wọ́n lè jẹ́rìí sí i pé àwọn ohun tí wọ́n kọ sínú àwọn ìwé Ìhìn Rere jóòótọ́. Wọ́n tún lè tètè túdìí àṣírí irọ́ táwọn èèyàn dà pọ̀ mọ́ òótọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n F. F. Bruce ṣàkíyèsí pé: “Ọ̀kan lára àwọn kókó tó lágbára jù lọ nínú ìwàásù táwọn àpọ́sítélì ṣe ni pé ohun táwọn olùgbọ́ wọn lè mọ̀ ni wọ́n sọ. Wọn kì í kàn sọ fún àwọn èèyàn pé, ‘Àwa ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí’ àmọ́ wọ́n tún máa ń sọ fún wọn pé ‘gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀’ (Ìṣe 2:22).”

Àwọn wo ló kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì? Àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá ti Jésù wà lára wọn. Àwọn wọ̀nyí àtàwọn míì tó kọ Bíbélì irú bíi, Jákọ́bù àti Júúdà wà níbẹ̀ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó sì ṣeé ṣe kí Máàkù pẹ̀lú wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yìí tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Gbogbo àwọ́n tó kọ Bíbélì títí kan Pọ́ọ̀lù ló fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ olùdarí ti ìjọ Kristẹni ìjímìjí, tí gbogbo wọn jẹ́ àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù.—Ìṣe 15:2, 6, 12-14, 22; Gálátíà 2:7-10.

Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa bá iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni tóun ti bẹ̀rẹ̀ nìṣó. (Mátíù 28:19, 20) Kódà, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá fetí sí yín, fetí sí mi pẹ̀lú.” (Lúùkù 10:16) Síwájú sí i, ó ṣèlérí fún wọn pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa fún wọn lágbára tí wọ́n nílò láti fi ṣe iṣẹ́ náà. Nítorí náà, nígbà tí àwọn àpọ́sítélì àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ bá kọ̀wé, ìyẹn àwọn ọkùnrin tí wọ́n fẹ̀rí tó ṣe kedere hàn pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń darí àwọn, àwọn Kristẹni ìjímìjí kì í janpata, wọ́n gbà pé Ọlọ́run fàṣẹ sí irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀.

Àwọn kan lára àwọn tó kọ Bíbélì jẹ́rìí sí i pé ìwé Bíbélì táwọn òǹkọ̀wé bíi tiwọn kọ ní àṣẹ àti ìmísí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pétérù tọ́ka sí àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ, ó sì sọ pé wọ́n wà ní ipò kan náà pẹ̀lú “àwọn Ìwé Mímọ́ yòókù.” (2 Pétérù 3:15, 16) Pọ́ọ̀lù náà gbà pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ wòlíì.—Éfésù 3:5.

Nítorí náà, àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìhìn Rere ṣeé gbára lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́. Wọn kì í ṣe ìtàn àtẹnudẹ́nu àti àlọ́. Àwọn ọkùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mí sí ló fara balẹ̀ kọ ìtàn náà, àwọn ẹlẹ́rìí tí ọ̀ràn ṣojú wọn sì jẹ́rìí sí i.

Àwọn Wo Ló Ṣàkójọ Àwọn Ìwé Onímìísí Náà?

Àwọn òǹṣèwé kan sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì ló ṣàkójọ àwọn ìwé onímìísí Ọlọ́run tí wọ́n di Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kọ ọ́, Olú Ọba Kọnsitatáìnì ló sì fún ṣọ́ọ̀ṣì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ òkodoro òtítọ́ fi hàn pé ọ̀ràn náà kò rí bẹ́ẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, gbọ́ ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Oskar Skarsaune tó jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa Ìtàn Ṣọ́ọ̀ṣì sọ, ó ní: “Kì í ṣe ìgbìmọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kankan tàbí èèyàn kan ṣoṣo ló pinnu àwọn ìwé tó máa wà lára Májẹ̀mú Tuntun àtàwọn tí kò ní sí níbẹ̀, . . . Ìlànà tí wọ́n lò hàn sí gbogbo èèyàn, ó sì bọ́gbọ́n mu. Ìlànà náà ni pé, àwọn ìwé tó wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí àwọn àpọ́sítélì kọ tàbí tí àwọn alájọṣiṣẹ́ wọn kọ ni àwọn èèyàn kà sí èyí tó ṣeé gbára lé. Àwọn ìwé, àwọn lẹ́tà yòókù tàbí àwọn ìwé táwọn èèyàn pè ní ìwé ìhìn rere tí wọ́n kọ lẹ́yìn náà kò sí lára wọn . . . Wọ́n ti ṣe àkójọ yìí parí tipẹ́tipẹ́ kó tó di ìgbà Kọnsitatáìnì àti ìgbà tó gbé agbára lé ṣọ́ọ̀ṣì lọ́wọ́. Àwọn Kristẹni tó kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn ló ṣàkójọ Májẹ̀mú Tuntun kì í ṣe àwọn alágbára inú ṣọ́ọ̀ṣì.”

Ken Berding, tó jẹ́ igbákejì ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ṣàlàyé nípa bí wọ́n ṣe mọ àwọn ìwé onímìísí Ọlọ́run, ó ní: “Kì í ṣe ṣọ́ọ̀ṣì ló ṣàkójọ ìwé tó wà lára àwọn ìwé onímìísí, ohun tó yẹ ká sọ ni pé ṣọ́ọ̀ṣì mọ àwọn ìwé náà sí ìwé táwọn Kristẹni ti fi ìgbà gbogbo gbà pé wọ́n jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi àṣẹ sí.”

Àmọ́, ṣé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ yìí ló dá ṣàkójọ àwọn ìwé onímìísí Ọlọ́run ni? Bíbélì sọ fún wa pé ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an tó sì lágbára ló darí wọn.

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ọ̀kan lára ẹ̀bùn ẹ̀mí tí Ọlọ́run fún ìjọ Kristẹni lọ́nà ìyanu ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà tí wọ́n dá a sílẹ̀ ni “fífi òye mọ àwọn àsọjáde onímìísí.” (1 Kọ́ríńtì 12:4, 10) Nítorí náà, Ọlọ́run fún àwọn kan lára àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ni agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ láti lóye ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn àsọjáde tó ní ìmísí Ọlọ́run àtàwọn tí kò ní. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni lónìí lè nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé pé àwọn Ìwé Mímọ́ tó para pọ̀ di Bíbélì ni a gbà pé ó ní ìmísí Ọlọ́run.

Nígbà náà, ó wá hàn kedere pé ẹ̀mí mímọ́ ló darí wọn ní ìjímìjí láti fìdí àwọn ìwé náà múlẹ̀ pé wọ́n jẹ́ ìwé tó ní ìmísí Ọlọ́run. Láti apá kejì ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́fà [117] lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, ni àwọn kan lára òǹkọ̀wé ayé ti sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìwé inú Bíbélì ṣe jẹ́ ìwé tó ní ìmísí Ọlọ́run. Àmọ́ àwọn òǹkọ̀wé yìí kọ́ ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ìwé náà jẹ́ ìwé tó ní ìmísí Ọlọ́run, ohun tí wọ́n kàn ṣe ni pé wọ́n jẹ́rìí sí ohun tí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ àwọn aṣojú rẹ̀ tí ẹ̀mí rẹ̀ darí.

Àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti ìgbà láéláé tún pèsè ẹ̀rí tó lágbára láti fi ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìwé onímìísí táwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà lónìí. Ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ìwé tí wọ́n dà kọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ló wà, títí kan àwọn kan tó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì àti ìkẹta Sànmánì Kristẹni. Àwọn ìwé yìí ni àwọn èèyàn kà sí ìwé tó láṣẹ ní àwọn ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan tó bẹ̀rẹ̀ Sànmánì Kristẹni, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ṣàdàkọ wọn, tí wọ́n sì pín wọn káàkiri. Àmọ́, ní ti àwọn ìwé àpókírífà, àwọn èèyàn kò kà wọ́n sí rárá.

Àmọ́ ṣá o, ẹ̀rí tó wà nínú àwọn ìwé náà fúnra wọn fi hàn pé wọ́n ní ìmísí Ọlọ́run, ẹ̀rí yẹn ló sì ṣe pàtàkì jù lọ. Àwọn ìwé onímìísí náà bá “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera,” yòókù tó wà nínú Bíbélì mu. (2 Tímótì 1:13) Wọ́n rọ àwọn tó ń kà wọ́n láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n máa jọ́sìn rẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ sìn ín. Wọ́n kìlọ̀ pé ká ṣọ́ra fún ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, bíbá ẹ̀mí èṣù lò àti jíjọ́sìn ìṣẹ̀dá. Àwọn ìtàn inú àwọn ìwé náà péye, wọ́n sì ní àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́ nínú. Wọ́n tún gba àwọn èèyàn níyànjú láti nífẹ̀ẹ́ èèyàn bíi tiwọn. Àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú. Ṣé àwọn ìwé àpókírífà kúnjú ìwọ̀n tó bá dọ̀ràn àwọn ohun tá a ti sọ yìí?

Bí Àwọn Ìwé Àpókírífà Ṣe Yàtọ̀

Àwọn ìwé àpókírífà yàtọ̀ gan-an sí àwọn ìwé tó ní ìmísí Ọlọ́run. Wọ́n kọ àwọn ìwé àpókírífà wọ̀nyí ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́fà [117] lẹ́yìn tí wọ́n ti dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ àwọn ìwé onímìísí Ọlọ́run tán tipẹ́. Ohun tí àwọn ìwé àpókírífà náà sọ nípa Jésù àti ẹ̀sìn Kristẹni kò bá àwọn Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí mu rárá.

Bí àpẹẹrẹ, ìwé àpókírífà ti Ìhìn Rere Tọ́másì sọ pé Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó ṣàjèjì, irú bíi pé òun máa sọ Màríà di ọkùnrin kó lè wọ Ìjọba ọ̀run. Ìwé Ìhìn Rere Àwọn Ọmọdé ti Tọ́másì ṣàpèjúwe Jésù pé ó jẹ́ ọmọ tó ń bínú fùfù tó mọ̀ọ́mọ̀ ṣekú pa ọmọ kan. Ìwé àpókírífà ti Ìṣe Pọ́ọ̀lù àti Ìṣe Pétérù sọ pé kéèyàn ta kété sí ìbálòpọ̀, kódà ó sọ pé àwọn àpọ́sítélì ń sọ fún àwọn obìnrin pé kí wọ́n pínyà pẹ̀lú ọkọ wọn. Ìwé Ìhìn Rere Júdásì sọ pé Jésù ń fi àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ rẹ́rìn-ín pé wọ́n ń gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà tí wọ́n fẹ́ jẹun. Irú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ta ko àwọn ohun tó wà nínú àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí.—Máàkù 14:22; 1 Kọ́ríńtì 7:3-5; Gálátíà 3:28; Hébérù 7:26.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé àpókírífà ló gbé èrò àwọn onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀, àwọn tó gbà gbọ́ pé Jèhófà Ẹlẹ́dàá kì í ṣe Ọlọ́run tó dáa. Wọ́n tún gbà gbọ́ pé àjíǹde kì í ṣe ohun téèyàn máa fojú rí, wọ́n ní ibi ni gbogbo nǹkan téèyàn bá lè fojú rí àti pé Sátánì ni ẹni tó dá ìgbéyàwó àti ọmọ bíbí sílẹ̀.

Àwọn ìwé àpókírífà kan sọ nípa àwọn èèyàn inú Bíbélì àmọ́ ohun tí wọ́n sọ nípa wọn kì í ṣe òótọ́. Ǹjẹ́ ìgbà tí ọ̀tẹ̀ kan wáyé ni wọ́n yọ àwọn ìwé náà kúrò lára àwọn ìwé inú Bíbélì? Ògbógi nínú ìmọ̀ nípa àwọn ìwé àpókírífà, Ọ̀gbẹ́ni M. R. James, sọ pé: “Ó dájú pé kì í ṣe ẹnì kan ló yọ àwọn ìwé náà kúrò lára Májẹ̀mú Tuntun, bí wọ́n ṣe kọ wọ́n ló fi hàn pé wọn kì í ṣe ara àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí.”

Àwọn Tó Kọ Bíbélì Kìlọ̀ Pé Ìpẹ̀yìndà Ń Bọ̀

Àwọn ìwé tó ní ìmísí Ọlọ́run ṣe àwọn ìkìlọ̀ kan nípa ìpẹ̀yìndà tó máa sọ ìjọ Kristẹni dìbàjẹ́. Kódà, ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni ìpẹ̀yìndà náà ti bẹ̀rẹ̀, àmọ́ àwọn àpọ́sítélì ni kò jẹ́ kó tàn kálẹ̀. (Ìṣe 20:30; 2 Tẹsalóníkà 2:3, 6, 7; 1 Tímótì 4:1-3; 2 Pétérù 2:1; 1 Jòhánù 2:18, 19; 4:1-3) Irú àwọn ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn ìwé tó bẹ̀rẹ̀ sí jáde lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì ti kú tán, ìyẹn àwọn ìwé tó lòdì sí ẹ̀kọ́ Jésù.

Lóòótọ́, irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ lè ti pẹ́ gan-an, kí àwọn ọ̀mọ̀wé àtàwọn òpìtàn sì máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀. Àmọ́, rò ó wò ná, ká ní àwọn ọ̀mọ̀wé ṣàkójọ àwọn ayédèrú ìwé tí àwọn èèyàn tẹ̀ jáde lóde òní, bóyá wọ́n ṣà wọ́n láti inú àwọn ìwé àhesọ àtàwọn ìwé ẹgbẹ́ òkùnkùn, tí wọ́n sì wá tọ́jú wọn pa mọ́ sínú yàrá kan. Ṣé bí ọjọ́ àwọn ìwé yẹn bá ṣe pẹ́ tó lè sọ wọ́n di ojúlówó ìwé tó ṣeé gbára lé? Lẹ́yìn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700] ọdún, ṣé irọ́ àti ìsọkúsọ tó wà nínú àwọn ìwé yẹn ti di òótọ́ torí pé ọjọ́ wọn ti pẹ́?

Rárá o! Bákan náà lọ̀rọ̀ rí ní ti àwọn ìwé tó sọ pé Jésù gbé Màríà Magidalénì níyàwó àtàwọn ọ̀rọ̀ tí ò bọ́gbọ́n mu tó wá látinú àwọn ìwé àpókírífà. Kí ló dé tó o fi fọkàn tán irú àwọn ìwé tí kò ṣeé gbára lé bẹ́ẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé àwọn ìwé tó ṣeé gbára lé wà lọ́wọ́? Gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká mọ̀ nípa Ọmọ rẹ̀ ti wà nínú Bíbélì, ìwé tó ṣeé fọkàn tán.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ náà “ìwé onímìísí” ń tọ́ka sí àkójọ àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n ní ẹ̀rí tó dájú pé Ọlọ́run mí sí wọn. Àwọn ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ló wà táwọn èèyàn gbà pé wọ́n jẹ́ ìwé tó ní ìmísí Ọlọ́run tí wọ́n sì para pọ̀ di Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌGBÉSÍ AYÉ JÉSÙ ÌGBÀ TÍ WỌ́N KỌ APÁ TÍ ÌGBÀ TÍ WỌ́N KỌ

WỌ́N FI ÈDÈ GÍRÍÌKÌ ÀWỌN ÌWÉ ÀPÓKÍRÍFÀ

KỌ NÍNÚ BÍBÉLÌ

2 Ṣ.S.K. 33 S.K. 41 98 130 300

[Credit Line]

Kenneth Garrett/National Geographic Image Collection

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣé àwọn iṣẹ́ ìyanu, kódà ó jí òkú dìde, èyí jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé ẹ̀mí Ọlọ́run tì í lẹ́yìn àtàwọn ìwé tó kọ