Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
ÀWỌN nǹkan wo ni ọmọ ìta, tó sì tún jẹ́ amugbó kan ṣe tó fi borí ìwà burúkú tó ti mọ́ ọn lára? Kí ló mú kí ọmọ ẹgbẹ́ akọrin ewèlè kan gé irun rẹ̀ tó gùn, tó sì pa orin tó fẹ́ràn yìí tì? Kí ló mú kí ọkùnrin kan tó kórìíra ìsìn àti àwọn aláṣẹ ìjọba di ẹni tó ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Jẹ́ ká gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.
“Mo jáwọ́ nínú àṣà burúkú tó ti mọ́ mi lára.”—PETER KAUSANGA
ỌJỌ́ ORÍ: 32
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: NÀMÍBÍÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌ ÌTA ÀTI AMUGBÓ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ibùdó Kehemu, ìyẹn ibùdó tó tóbi jù lọ lára ibùdó mẹ́rin tó wà ní ìlú Rundu ni mo gbé dàgbà. Owó táwọn tó ń gbé ibẹ̀ ń rí látara ọkà bàbà, igi àti èédú tí wọ́n ń tà ni wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn.
Ọmọ ọdún méjì ni mí nígbà tí ìyá mi ti kú, torí náà, ìyá mi àgbà ló tọ́ mi dàgbà. Ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ là ń gbé. Mi ò kì í ṣe oníjàgídíjàgan èèyàn, àmọ́ nítorí pé mo fẹ́ ṣe ohun tí àwọn ẹgbẹ́ mi ń ṣe, mo kó sínú ìjàngbọ̀n. Mo wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta nílé ìwé. Èyí tó yọrí sí jíja ìjà ìgboro, bíbúmọ́ni, olè jíjà, ṣíṣe fàyàwọ́ dáyámọ́ǹdì, à ń mutí, a sì ń lo oògùn olóró. Ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n ti mú mi, tí wọ́n sì sọ mí sẹ́wọ̀n nítorí pé mo fọ́lé, tí mo sì lu jìbìtì.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18], mo pa ilé ìwé tì, mo sì fi ìlú ìbílẹ̀ mi àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa sílẹ̀. Mo fẹ́ lọ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun. Àmọ́, mi ò tíì jáwọ́ nínú igbó mímu. Ìgbà míì wà tí mo máa ń rin ọ̀pọ̀ kìlómítà kí n bàa lè lọ ra igbó.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1999, mo rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ń fún àwọn èèyàn tó ń kọjá lójú pópó ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n bá mi sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wọ́n sì buyì fún mi, èyí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ kí n gbà pé mo ti rí ìsìn tòótọ́. Mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì taápọntaápọn, nígbà tó sì yá, mo rí i pé mo ní láti ṣàtúnṣe sí ìgbésí ayé mi tí mo bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run.
Mo mú ọjọ́ kan tí mo máa jáwọ́ nínú mímu sìgá àti igbó, tí màá sì ba gbogbo nǹkan tó ní í ìwé Òwe 24:16 sọ́kàn, ó ní: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.” Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo jáwọ́ nínú àwọn àṣà burúkú tó ti mọ́ mi lára yìí.
ṣe pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí jẹ́. Mo tún sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ mi pé kí wọ́n má ṣe fún mi ní sìgá mọ́ àti pé kí wọ́n má mu sìgá nítòsí mi. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, nǹkan ò lọ bí mo ṣe rò. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo tún pa dà lọ mu sìgá àti igbó. Síbẹ̀, mi ò rẹ̀wẹ̀sì. Mo fi ìlànà tó wà nínúBí mo ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà ni mo ṣe ń fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ìwé Sáàmù 27:10, jẹ́ ọ̀kan lára ẹsẹ Bíbélì tó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó ní: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sí i, ni mò ń rí báwọn ọ̀rọ̀ yẹn ṣe jẹ́ òótọ́. Jèhófà ti jẹ́ ẹni gidi àti Bàbá onífẹ̀ẹ́ sí mi.
Mo tún máa ń lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé. Níbẹ̀, mo rí bí àwọn èèyàn ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ fún ara wọn, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. Mi ò tíì rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àti tàwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí, mo ti ṣàtúnṣe ìmúra mi, ìwà mi àti bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀. Tí mo bá ronú sí àwọn ohun tí mo ti ṣe sẹ́yìn, mo rí i pé ìgbésí ayé mi ti yí pa dà bí kòkòrò mùkúlú kan ṣe ń yíra pa dà di labalábá ẹlẹ́wà. Inú àwọn mọ̀lẹ́bí mi dùn gan-an sí ìyípadà tí mo ṣe yìí, mo sì ti dẹni tí wọ́n fọkàn tán. Mo ti gbéyàwó báyìí, mo sì ń sapá láti máa jẹ́ ọkọ rere sí aya mi àti bàbá onífẹ̀ẹ́ sí àwọn ọmọ mi.
“Mo ti ń fi ìgbésí ayé mi ṣe ohun tó dáa.”—MARCOS PAULO DE SOUSA
ỌJỌ́ ORÍ: 29
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: BRAZIL
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌ ẸGBẸ́ AKỌRIN EWÈLÈ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Jaguariuna, ní São Paulo làwọn ìdílé mi ń gbé. Onísìn Kátólíìkì paraku làwọn òbí mi, nígbà tí mo wà ní kékeré, mo di ọmọ ìdí pẹpẹ. Èyí ló mú kí àwọn ọmọ tá a jọ wà nínú kíláàsì nígbà yẹn máa pè mí ní Fadá. Àmọ́ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo ṣalábàápàdé àwọn akọrin ewèlè. Mo bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ wọn. Mo fi irun orí mi sílẹ̀ kó lè gùn. Nígbà tó sì di ọdún 1996, bàbá mi ra ìlù mi àkọ́kọ́ fún mi.
Ní ọdún 1998, mo di ọmọ ẹgbẹ́ akọrin ewèlè. Orin tó ń fi ìyìn fún Sátánì, tó sì kún fún ọ̀rọ̀ rírùn ni orin yìí. Ìwà ipá ló ń gbé lárugẹ. Orin yìí ṣàkóbá fún ìrònú, ìwà àti ìṣe mi. Mo wá di ẹni tó ń ro ìròkurò ṣáá, tí mo sì ń hùwà ẹhànnà.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ọdún 1999 ni mo kọ́kọ́ pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n béèrè bóyá mo nífẹ̀ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo gbà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i. Àmọ́ ohun tí mo kọ́ látinú Bíbélì yí ojú tí mo fi ń wo ìgbésí ayé pa dà.
“Onírun gígùn,” “olókìkí akọrin ewèlè” tàbí “onílù” làwọn èèyàn mọ̀ mí sí. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé bí mo ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ yìí ti sọ mí di ẹni tó mọ tara rẹ̀ nìkan àti
abánidíje, mi ò sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú òkìkí tí mo ní. Ó wá yé mi pé, ìgbésí ayé àwọn olórin tí mo sọ di òrìṣà kò nítumọ̀ gidi. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé, tí mo bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run, mo ní láti fi orin ewèlè sílẹ̀ àti ìgbésí ayé oníṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà tó ń bá orin náà rìn.Mo fẹ́ràn orin mi àti irun mi tó gùn gan-an. Mò ń ṣe kàyéfì pé bóyá ni mo lè wà láàyè láìsí àwọn nǹkan yìí. Mo tún máa ń bínú sódì, mo sì mọ̀ pé mo ní láti kọ́ bí màá ṣe kápá rẹ̀. Àmọ́, bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà síwájú àti síwájú sí i. Ohun tí mo kọ́ nípa ìfẹ́, sùúrù àti àánú Ọlọ́run mú kí n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Mo bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè yí pa dà, ó sì ti ràn mí lọ́wọ́. Mo ti fojú ara mi rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Hébérù 4:12. Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”
Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo rí i pé wọ́n yàtọ̀. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo máa rí àwọn èèyàn tó fẹ́ràn ara wọn dénú. Àwọn àpéjọ ńlá tí àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń ṣe ni ìfẹ́ yìí ti máa ń hàn jù. Ó jọ mí lójú láti rí bí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ṣe ń fi ìtara ṣiṣẹ́ kí ibi tí àwọn èèyàn fẹ́ lò lè jẹ́ ibi tó tuni lára.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ní báyìí mo ti ń kápá ìbínú mi. Mi ò kì í ṣe ẹni tó mọ tara rẹ̀ nìkan àti onígbèéraga mọ́.
Kí n sòótọ́, ìgbà kan wà tó ń wù mí láti pa dà gbé irú ìgbésí ayé tí mò ń gbé tẹ́lẹ̀, àmọ́ nísinsìnyí, kò wù mí mọ́. Ní báyìí, mo ti ń fi ìgbésí ayé mi ṣe ohun tó dáa. Mo láyọ̀ pé mò ń kọ́ béèyàn ṣe ń fífẹ̀ hàn sí àwọn èèyàn àti béèyàn ṣe ń wá ire wọn.
“Mo ní ayọ̀ torí pé mò ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.”—GEOFFREY NOBLE
ỌJỌ́ ORÍ: 59
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: AMẸ́RÍKÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO KÓRÌÍRA ÌSÌN ÀTI ÀWỌN ALÁṢẸ ÌJỌBA
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Ipswich, ní Massachusetts, tó wà létí òkun ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, àwọn lébìrà máa ń gbé nílùú yìí. Nígbà tí mo dàgbà, mo yàn láti máa gbé ní abúlé Vermont. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ará àríwá Amẹ́ríkà, èmi àti ọ̀rẹ́bìnrin mi ń gbé ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ. A kò ní iná mànàmáná, nítorí náà, ńṣe la máa ń figi dáná kí ilé wa lè móoru, igi la sì tún fi ń se oúnjẹ wa. Ìta ni ilé ìyàgbẹ́ wa wà, a kì í sì í rí omi ẹ̀rọ lò láwọn ọdún kan. A kì í bá àwọn èèyàn ṣe nǹkan pọ̀, ìrísí wa sì fi èyí hàn. Lákòókò kan, mò ń
fi irun orí mi tí mi ò yà fún oṣù mẹ́fà gbáko yangàn.Lákòókò tí mò ń wí yìí, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dá sí ogun tó ń lọ lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè Vietnam. Èyí ṣàkóbá fún ìwà tí mò ń hù sáwọn aláṣẹ. Mo rí àgàbàgebè tó wà nínú ìjọba àti ìsìn. Èrò mi sì ni pé èèyàn ò lè rí ìtọ́sọ́nà tó ṣe tààrà lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ àtàwọn onísìn, torí náà kí kálukú máa dá pinnu ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Nítorí ìdí yìí, mi ò rí ohun tó burú nínú jíjí ohun tí mo bá fẹ́ lò.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Èmi àti ọ̀rẹ́bìnrin mi ti bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì, àmọ́ a ò ka ohun tó wà nínú rẹ̀ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń sapá láti fi oògùn olóró sílẹ̀, síbẹ̀ mo ṣì ń lò ó. Ọ̀rẹ́bìnrin mi fẹ́ ká forúkọ ìgbéyàwó wa sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba, ó sì fẹ́ bímọ. Lákòókò yẹn, obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sí ilé wa, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Kò pẹ́ tí mo fi jáwọ́ nínú àṣà burúkú tó ti mọ́ mi lára, àmọ́ ó ṣòro fún mi gan-an láti yí èrò mi nípa àwọn aláṣẹ pa dà. Gbogbo nǹkan táwọn èèyàn bá sọ ni mo máa ń wádìí rẹ̀ wò fínnífínní. Ìwà tó wù mí ni mò ń hù títí mo fi dàgbà, torí náà, kò rọrùn fún mi láti fi ara mi sábẹ́ ìlànà tí ẹnì kan bá gbé kalẹ̀.
Mo gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, àmọ́ mi ò mọ ohun púpọ̀ nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ànímọ́ Jèhófà Ọlọ́run wá ń ṣe kedere sí mi. Mo rí i pé, kedere ló sọ ohun tó fẹ́ kí n ṣe. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn àṣẹ rẹ̀ tí kò yé èèyàn. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ó ní in lọ́kàn láti sọ ayé yìí di Párádísè. (2 Pétérù 3:13) Àwọn òtítọ́ yìí mú kí n fẹ́ láti yí ìgbésí ayé mi pa dà, kí n bàa lè jọ́sìn rẹ̀.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí ogun jíjà, èyí sì jọ mí lójú gan-an ni. Kò sí ìsìn kankan láyé tí mo mọ̀ tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú Bíbélì bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Mo mọ̀ pé tí mo bá fẹ́ jọ́sìn Jèhófà, mo ní láti tún ìrísí mi ṣe. Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀nà tí àwọn Ẹlẹ́rìí gbà ń wọṣọ kò bá mi lára mu rárá. Ó ṣe tán, èmi tàbí ọ̀rẹ́bìnrin mi kò ní aṣọ àti bàtà gidi tá a lè wọ̀ jáde. Èmi fúnra mi ò sì ní táì! Àmọ́ mo gé irun gígùn tó wà lórí mi, mo sì tún ìrísí mi ṣe. Àní, mo rántí ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ wàásù láti ilé dé ilé. Mo rí ara mi nínú dígí, mo sì rí i pé mo ti yàtọ̀. Mo bi ara mi pé, ‘Kí lo ṣe èyí fún?’ Àmọ́ nígbà tó yá, ìrísí mi tuntun yìí tẹ́ mi lọ́rùn.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Mo gbé ọ̀rẹ́bìnrin mi níyàwó, a sì jọ wà títí dòní. Àwa méjèèjì ti tọ́ àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dàgbà láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì máa jọ́sìn rẹ̀. Mo tún ń gbádùn bí mo ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì kan náà tó ràn mí lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé mi pa dà.
Nígbà kan rí, mi ò kì ń ka èrò àwọn èèyàn sí. Àmọ́ ní báyìí, mo ní ayọ̀ torí pé mò ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àwọn èèyàn sì ń ràn mí lọ́wọ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]
“Mo máa ń rin ọ̀pọ̀ kìlómítà kí n bàa lè lọ ra igbó”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]
“Ohun tí mo kọ́ látinú Bíbélì yí ojú tí mo fi ń wo ìgbésí ayé pa dà”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
“Ọ̀nà tí àwọn Ẹlẹ́rìí gbà ń wọṣọ kò bá mi lára mu rárá”