Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Àwọn àǹfààní àtàwọn ojúṣe wo ló máa ń bá ẹ̀tọ́ àkọ́bí tó jẹ́ ọkùnrin rìn?
▪ Láti ìgbà àwọn baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti máa ń fún àwọn àkọ́bí tó jẹ́ ọkùnrin ni ẹ̀tọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Nígbà tí bàbá bá kú, ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà ló máa tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ olórí ìdílé. Òun lá máa bójú tó ìdílé náà, táá sì jẹ́ aláṣẹ lórí gbogbo ará ilé tó ń gbé ibẹ̀. Ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí ló tún máa ń ṣojú fún ìdílé náà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọkùnrin yòókù náà máa gba ogún, ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí ló máa ń gba ogún tó pọ̀ jù. Tá a bá sì fi ogún tí ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí máa gbà wé tàwọn yòókù, ìlọ́po méjì ni tirẹ̀ jẹ́.
Ní àkókò àwọn baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí lè pàdánù ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí. Bí àpẹẹrẹ, Ísọ̀ ta ogún ìbí rẹ̀ fún àbúrò rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 25:30-34) Jákọ́bù gbé ẹ̀tọ́ Rúbẹ́nì tó jẹ́ àkọ́bí rẹ̀ fún Jósẹ́fù. Rúbẹ́nì pàdánù àǹfààní náà nítorí ìwà pálapàla tó hù. (1 Kíróníkà 5:1) Lábẹ́ Òfin Mósè, ọkùnrin tó bá fẹ́ ju ìyàwó kan lọ kò lè gbé ẹ̀tọ́ ọmọkùnrin àkọ́bí ti ìyàwó kìíní fún ti ìyàwó kejì nítorí pé ó yan ìyàwó kejì láàyò. Ọkùnrin náà kò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ tó jẹ́ ti ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí dù ú.—Diutarónómì 21:15-17.
Kí nìdí tí àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí fi máa ń wọ aṣọ tó ní akóló ìkó-ìwé-mímọ́-sí?
▪ Jésù bá àwọn onísìn tó máa ń ta kò ó wí, ìyẹn àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí, nítorí pé wọ́n mú “àwọn akóló ìkó-ìwé-mímọ́-sí fẹ̀, èyí tí wọ́n ń dè mọ́ ara láti fi ṣe ìṣọ́rí.” (Mátíù 23:2, 5) Àwọn onísìn yẹn máa ń de akóló kékeré tí wọ́n fi awọ ṣe, tó dúdú, tó ní igun mẹ́rin mọ́ iwájú orí wọn. Wọ́n tún máa ń dè é mọ́ apá nítòsí abíyá. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ló máa ń wà nínú akóló náà. Àṣà síso àwọn akóló ìkó-ìwé-mímọ́-sí mọ́ra, wá látinú àṣìlóye táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nípa ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run fún wọn pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ . . . Kí ìwọ sì so wọ́n gẹ́gẹ́ bí àmì mọ́ ọwọ́ rẹ, kí wọ́n sì jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀já ìgbàjú láàárín ojú rẹ.” (Diutarónómì 6:6-8) A kò mọ ìgbà náà gan-an tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ àṣà síso akóló mọ́ra, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀mọ̀wé sọ pé ó bẹ̀rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì tàbí ìkẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Ìdí méjì ni Jésù fi sọ pé àṣà yìí kò dára. Àkọ́kọ́, àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí máa ń mú kí akóló wọn fẹ̀ láti gbayì lójú àwọn èèyàn pé àwọn jẹ́ olùfọkànsìn. Èkejì, àwùjọ àwọn èèyàn méjì yìí ti sọ akóló ìkó-ìwé-mímọ́-sí di oògùn ìṣọ́ra tí yóò máa dáàbò bò wọ́n. Nínú àwọn ìwé tí kì í ṣe Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n fi ń pe àwọn akóló wọ̀nyí, ìyẹn phylakterion, túmọ̀ sí “ilé àwọn ológun,” “odi” tàbí “ohun ààbò.”