A Rán Àwọn Míṣọ́nnárì Jáde Láti Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Kejìdínláàádóje Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
A Rán Àwọn Míṣọ́nnárì Jáde Láti Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
“KÍ ÀWỌN èèyàn tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè bàa lè gbọ́ nípa ìhìn rere, àwọn Kristẹni kan ní láti fínnúfíndọ̀ fi ilé àtàwọn èèyàn wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì lọ wàásù ní orílẹ̀-èdè míì.” Báyìí ni Arákùnrin David Splane tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe kí àwọn èèyàn káàbọ̀ fún àpéjọ tẹ̀mí tó gbádùn mọ́ni náà.
Ní March 13, ọdún 2010, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] èèyàn ló péjọ síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kejìdínláàádóje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àwọn ọ̀rẹ́, ará ilé àtàwọn àlejò láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ló wá síbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.
“Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Kò Gbọ́dọ̀ Dúró Sílé”
Arákùnrin Splane tó jẹ́ alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa jíjíròrò àṣẹ Jésù tó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Ó tọ́ka sí i pé Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn. Òótọ́ ni pé, ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn èèyàn fúnra wọn ni wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù láti Mesopotámíà, Àríwá Áfíríkà àti láti apá ibi tó pọ̀ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù, tí wọ́n sì gbọ́ ìhìn rere. Olùbánisọ̀rọ̀ sọ pé, àmọ́, “àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò gbọ́dọ̀ dúró sílé, kí wọ́n wá máa retí pé kí àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo wá bá àwọn. Wọ́n ní láti wá àwọn èèyàn lọ sí apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8.
Arákùnrin Splane sọ pé: “Jésù kò kàn sọ ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ṣe, ó tún kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa ṣe é. Kò kàn sọ pé kí wọ́n máa gbàdúrà, ó kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà. Kò kàn sọ pé kí wọ́n máa wàásù, ó fi bí wọ́n á ṣe máa wàásù hàn wọ́n. Kò kàn sọ pé kí wọ́n jẹ́ olùkọ́ rere, ó fi àpẹẹrẹ béèyàn ṣe lè kọ́ni lọ́nà tó jáfáfá hàn wọ́n.”
Alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, ó fa ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yọ pé: “Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:20) Arákùnrin Splane fi dá àwùjọ náà lójú pé, Jésù á bójú tó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà nílẹ̀ òkèèrè tá a yàn wọ́n sí láti lọ ṣiṣẹ́.
“Ẹ Lọ Kí Ẹ sì Máa Ṣògo”
Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé, “ẹ lọ kí ẹ sì máa ṣògo.” Ó sọ pé, ọ̀nà méjì ni ṣíṣògo pín sín, ọ̀kan dára àmọ́ ìkejì kò dára. Èyí tí kò dára ni kéèyàn máa wá ògo fún ara rẹ̀. Èyí tó dára ni ìwé 1 Kọ́ríńtì 1:31 ṣàlàyé rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Jèhófà.” Arákùnrin Morris sọ pé: “Téèyàn bá fẹ́ ṣògo nípa ohunkóhun, kó jẹ́ nípa òye àti ìmọ̀ téèyàn ní nípa Jèhófà Ọlọ́run. Kódà, àǹfààní tó tóbi jù lọ tí èmi àti ẹ̀yin ní ni jíjẹ́ tá à ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn orúkọ tó jẹ mọ́ orúkọ mímọ́ náà.”—Jeremáyà 9:24.
Olùbánisọ̀rọ̀ yìí wá sọ ìrírí míṣọ́nnárì kan tó wà lórílẹ̀-èdè Áfíríkà láti jẹ́ ká rí bí sísọ orúkọ Jèhófà fún àwọn èèyàn ti ṣe pàtàkì tó. Míṣọ́nnárì yìí àti ìyàwó rẹ̀ ń rìnrìn àjò láti lọ sọ àsọyé Bíbélì fún àwọn èèyàn. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn sójà tó ń dá ọkọ̀ dúró lójú ọ̀nà, sójà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ dojú ìbọn kọ arákùnrin náà, ó sì ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ta ni ẹ́? Ìyàwó arákùnrin yìí rántí ohun tó kọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, nítorí náà, ó sún mọ́ ọkọ rẹ̀, ó sì sọ́ fún un wúyẹ́wúyẹ́ pé, “Sọ fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́ àti pé àsọyé Bíbélì lo fẹ́ lọ sọ.” Ó ṣe ohun tí ìyàwó rẹ̀ sọ, sójà náà sì yọ̀ǹda wọn láti kọjá. Lọ́jọ̀ kejì, àwọn tọkọtaya yìí gbọ́ ìròyìn lórí rédíò pé, ààrẹ ti sọ fún àwọn sójà pé kí wọ́n wà lójúfò
láti mú àwọn agbanipa tí wọ́n ń pe ara wọn ní míṣọ́nnárì! Wọ́n bọ́ nínú ọ̀pọ̀ ìṣòro nítorí wọ́n sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn dípò kí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ míṣọ́nnárì. Arákùnrin Morris wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Tẹ́ ẹ bá ti dé ibi tá a yàn yín sí, ẹ máa ṣògo. Ẹ máa ṣògo nínú gbogbo ohun tí Jèhófà máa lò yín láti ṣe fún ògo rẹ̀ ayérayé.”“Ṣé Wàá Ṣe Iṣẹ́ Rẹ Yanjú?”
Arákùnrin Geoffrey Jackson, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, tó sì tún jẹ́ míṣọ́nnárì nígbà kan rí ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege lọ́wọ́ láti ronú lórí ìbéèrè tó wà lókè yìí. Ó béèrè pé, “Kí la ní lọ́kàn tá a bá pe ẹnì kan ní míṣọ́nnárì?” Ó ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ náà, “míṣọ́nnárì” wá látinú èdè Látìn tó túmọ̀ sí ẹnì kan tàbí àwùjọ kan tó gba àkànṣe iṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, iṣẹ́ wa ni láti kéde ìhìn rere àti láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó fi iṣẹ́ tó wá ṣe lórí ilẹ̀ ayé sọ́kàn nígbà gbogbo là ń tẹ̀ lé. Jésù sọ fún Pọ́ńtù Pílátù tó jẹ́ Gómìnà Róòmù pé: “Nítorí èyí . . . ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.”—Jòhánù 18:37.
Olùbánisọ̀rọ̀ náà pe àfiyèsí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ìtàn Bíbélì nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Jẹ́ríkò. Ọjọ́ mẹ́fà làwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì fi ń jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, tí wọ́n á gbé ohun ìjà wọ̀, tí wọ́n á sì rìn yí ìlú Jẹ́ríkò ká lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà wọ́n á pa dà sílé. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé, “Lójú èèyàn, iṣẹ́ náà dà bí ohun tí kò bọ́gbọ́n mu.” Ó sọ pé àwọn sójà kan lè ti rò pé, ‘Èèyàn kàn ń fàkókò ṣòfò ni.’ Àmọ́ ní ọjọ́ keje, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ìtọ́ni pé kí wọ́n yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, lẹ́yìn náà, kí wọ́n kígbe ogun lọ́nà tó rinlẹ̀. Kí ló wá yọrí sí? Ògiri ìlú Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ!—Jóṣúà 6:13-15, 20.
Arákùnrin Jackson wá fa ẹ̀kọ́ mẹ́rin yọ látinú ìtàn nípa ìlú Jẹ́ríkò yìí. (1) Ìgbọràn ṣe kókó. A gbọ́dọ̀ máa ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́, ká má ṣe máa ronú pé ọ̀nà tiwa ló dára jù. (2) Ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà ṣe pàtàkì. “Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn ògiri Jẹ́ríkò fi wó lulẹ̀,” kì í ṣe pé wọ́n fi òlùgbóró wó o. (Hébérù 11:30) (3) A gbọ́dọ̀ ní sùúrù. Ìbùkún Jèhófà yóò “dé bá ọ” lákòókò tó yẹ. (Diutarónómì 28:2) (4) Ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Ẹ má ṣe gbàgbé iṣẹ́ tá a fi rán yín. Arákùnrin Jackson parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Tẹ́ ẹ bá fi àwọn kókó yìí sọ́kàn, ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín yanjú fún ìyìn àti ògo Jèhófà.”
Àwọn Kókò Míì Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà
“Nífẹ̀ẹ́ Bíbélì àti Ẹni Tó Ni Ín.” Arákùnrin Maxwell Lloyd tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló sọ̀rọ̀ lórí àkòrí yìí. Ó sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé, “Ẹ rí i pé ẹ̀ ń lo Bíbélì nígbà gbogbo.” Lẹ́yìn náà ló wá gbà wọ́n níyànjú pé, Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní fún Jèhófà Ọlọ́run tutù. Ẹ má ṣe rò pé gbogbo èèyàn ló lóye ohun tí ẹ̀ ń kọ́ wọn. Ẹ kọ́ béèyàn ṣe ń ṣàlàyé òtítọ́ lọ́nà tó rọrùn kí ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ àwọn èèyàn lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe bíi pé ẹ ní ìmọ̀ kan tó ga ju táwọn èèyàn yòókù lọ. Ẹ máa fi àpẹẹrẹ yín kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jẹ́ káwọn tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ rí i pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Bíbélì.
‘Ẹ Ṣàkíyèsí Àwọn Ẹyẹ Ìwò Dáadáa.’ Arákùnrin Michael Burnett, tó jẹ́ olùkọ́ ní kíláàsì náà tó sì jẹ́ míṣọ́nnárì nígbà kan rí, ló sọ̀rọ̀ lórí àkòrí tó wà lókè yìí. Ó sọ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a ó máa ṣàníyàn. Àmọ́, ẹ rántí ìmọ̀ràn Jésù pé: “Ẹ ṣàkíyèsí dáadáa pé àwọn ẹyẹ ìwò kì í fún irúgbìn tàbí kárúgbìn, . . . síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn.” (Lúùkù 12:24) Gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú Òfin ti sọ, aláìmọ́ ni àwọn ẹyẹ ìwò jẹ́, wọn kó sì yẹ fún jíjẹ. Nǹkan ẹlẹ́gbin ni wọ́n jẹ́. (Léfítíkù 11:13, 15) Àmọ́ pẹ̀lú bí àwọn ẹyẹ yìí ṣe jẹ́, Ọlọ́run ń fún wọn ní oúnjẹ. Arákùnrin Burnett wá sọ pé: “Nítorí náà, bí àwọn nǹkan tó ń múni ṣàníyàn bá dé bá yín lọ́jọ́ iwájú, ẹ máa rántí ẹyẹ ìwò. Tí Ọlọ́run bá lè bójú tó ẹyẹ tó jẹ́ aláìmọ́ tó sì tún jẹ́ nǹkan ẹlẹ́gbin, ó dájú pé ó máa bójú tó ẹ̀yin tẹ́ ẹ jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀.”
“Èmi Kò Ṣe Àìtọ́ Kankan Sí Ọ.” Arákùnrin Mark Noumair, tí òun náà jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì mú kí àwọn tó wà níbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà Mátíù 20:13, 14) Kí la lè rí kọ́ nínú àpèjúwe yìí? Ẹ má ṣe fi ara yín wé àwọn ẹlòmíì. Arákùnrin Noumair sọ pé: “Ńṣe ni àfiwé tí kò tọ́ máa jẹ́ kẹ́ ẹ pàdánù ayọ̀ yín. Èyí tó wá burú jù ni pé, ó lè jẹ́ kẹ́ ẹ fi àǹfààní iṣẹ́ ìsìn iyebíye tẹ́ ẹ ní sílẹ̀.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ létí pé, Jésù ló ń darí ìkórè tẹ̀mí ní àkókò tiwa yìí, ó sì lè ṣe ohun tó bá fẹ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Tí Jèhófà àti Jésù bá yàn láti ṣe nǹkan àrà ọ̀tọ̀ kan fún àwọn kan, wọn ò ṣe àìtọ́ kankan sí ẹ. Gbájú mọ́ ohun tó jẹ́ tìrẹ, má sì jẹ́ kí “owó ọ̀yà” àwọn ẹlòmíì gba àfiyèsí rẹ kúrò nínú iṣẹ́ tí Jèhófà fi fún ẹ.
ronú lórí àpèjúwe Jésù nípa àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà. Àwọn òṣìṣẹ́ kan ṣiṣẹ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. Wákàtí kan péré láwọn kan fi ṣiṣẹ́. Síbẹ̀, iye kan náà ni gbogbo wọn gbà! Ni àwọn tó ṣiṣẹ́ láti àárọ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn. Ọ̀gá tó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún àwọn tó ń kùn náà pé: “Èmi kò ṣe àìtọ́ kankan sí ọ. Àdéhùn owó dínárì kan ni ìwọ bá mi ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Gba ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, kí o sì máa lọ.” (Àwọn Ìrírí àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń jáde láti lọ wàásù pẹ̀lú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí wọn tí wọn kò bá ní kíláàsì tàbí iṣẹ́ àṣetiléwá. Arákùnrin Sam Roberson, tó jẹ́ ọ̀kan lára olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mélòó kan nípa àwọn ìrírí tí wọ́n ní. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Alessandra Kirchler, pàdé obìnrin kan tó ń ṣàníyàn nípa sìgá tó ti di bárakú fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. Alessandra pa dà lọ, ó sì mú ìwé ìròyìn Jí! tó ní àpilẹ̀kọ kan tó dá lórí kókó náà dání. Kò sí ẹnì kankan ní ilé, àmọ́ ó fi ìwé náà sílẹ̀. Nígbà tó yá, Alessandra rí obìnrin yìí nílé, obìnrin náà sì gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Obìnrin yìí mọrírì àpilẹ̀kọ náà gan-an, ó sì sọ pé, “Mo máa ń ṣe kàyéfì pé, kí ni Ọlọ́run fẹ́ kọ́ mi pẹ̀lú gbogbo ìṣòro tó ń kó bá mi yìí.” Arábìnrin Alessandra fi hàn án nínú Bíbélì pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ohun burúkú bá wa. (Jákọ́bù 1:13) Ní báyìí, obìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ti ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Arákùnrin Melvin Jones tó jẹ́ ara àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì nígbà kan rí, àwọn bíi, Jon Sommerud, tó ń sìn ní Alibéníà, Mark Anderson, tó ń sìn ní Kẹ́ńyà àti James Hinderer, tó ń sìn ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ló gbà pé kì í ṣe òtítọ́ Bíbélì nìkan ni wọ́n ń kọ́ni nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, àmọ́ wọ́n tún ń kọ́ni béèyàn ṣe lè fi àwọn òtítọ́ náà sílò, láìka irú ẹni tí akẹ́kọ̀ọ́ kan jẹ́ sí tàbí ibi tó ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn.
Lẹ́yìn náà ni ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wá ka lẹ́tà ìmọrírì tó wọni lọ́kàn èyí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kọ. Arákùnrin John Barr, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96] tó dàgbà jù lára àwọn Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá fi àdúrà parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìbùkún Jèhófà lórí iṣẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kejìdínláàádóje ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì.
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 31]
ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ
8 Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá
54 iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́
27 iye àwọn tọkọtaya
35.2 ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn
19.1 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti ṣèrìbọmi
13.8 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún
[Àwòrán ilẹ̀]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
A rán kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí lọ sí orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tó wà nísàlẹ̀ yìí:
IBI TÁ A RÁN ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ LỌ
ALIBÉNÍÀ
ARUBA
BÒLÍFÍÀ
KÀǸBÓDÍÀ
CÔTE D’IVOIRE
DOMINICAN REPUBLIC
ECUADOR
GÁNÀ
GUATEMALA
GUINEA
GUYANA
HONDURAS
INDONESIA
SERBIA
LATVIA
LÀÌBÉRÍÀ
MADAGÁSÍKÀ
MÒǸGÓLÍÀ
NÀMÍBÍÀ
NICARAGUA
PARAGUAY
ROMANIA
RÙWÁŃDÀ
KOSOVO
TAIWAN
(ABẸ́ ÀBÓJÚTÓ Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ WA TÓ WÀ NÍ ỌSIRÉLÍÀ NI WỌ́N WÀ)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára àwọn ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Kíláàsì Kejìdínláàádóje Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
A to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì lọ sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Keller, E.; Ostopowich, I.; Jacobsen, S.; Arias, M.; Dieckmann, Y.; Tanaka, J.; Harada, K.
(2) Camacho, L.; Kirchler, A.; Rodríguez, S.; Ward, B.; Trenalone, K.; Victoria, V.; Oxley, F.; Nguyen, K.
(3) Oxley, O.; De Dios, A.; Lindström, C.; Allen, J.; Meads, T.; Waddington, J.; Victoria, E.
(4) Harada, H.; Lindström, A.; Orsini, E.; Logue, D.; Missud, T.; Bergeron, S.; Camacho, G.; Ward, T.
(5) Kirchler, W.; Nguyen, H.; Kremer, E.; Burgaud, C.; Titmas, N.; De Dios, C.; Rodríguez, A.; Waddington, M.
(6) Dieckmann, J.; Allen, C.; Titmas, R.; Arias, J.; Bergeron, E.; Keller, J.; Ostopowich, F.; Burgaud, F.
(7) Tanaka, K.; Kremer, J.; Jacobsen, R.; Trenalone, J.; Logue, J.; Meads, D.; Missud, D.; Orsini, A.