Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Béèrè Pé Ká Máa Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀?

Ṣé Ọlọ́run Béèrè Pé Ká Máa Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀?

Ṣé Ọlọ́run Béèrè Pé Ká Máa Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀?

Jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ẹni fún àlùfáà tàbí òjíṣẹ́ ìsìn ṣì jẹ́ apá kan lára ààtò àti ìjọsìn ní ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì. Àmọ́, ǹjẹ́ jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ pọn dandan lóde òní tí kálukú ń ṣe ohun tó wù ú?

ORÍṢIRÍṢI èrò làwọn èèyàn ní lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ ìwé ìròyìn National Post ti Kánádà sọ nípa ẹnì kan tó sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro láti sọ ohun tí kò tọ́ téèyàn ṣe fún ẹlòmíì, “àǹfààní wà nínú sísọ ọ́ fún ẹnì kan, á gbàdúrà fún ẹ, á sì sọ ohun tó yẹ kó o ṣe nípa rẹ̀.” Àmọ́, ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn Bless Me, Father, for I Have Sinned sọ nípa ọkùnrin kan tó sọ pé: “Jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń bani lọ́kàn jẹ́ jù lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ó máa ń jẹ́ kéèyàn ṣàníyàn àṣejù.” Kí ni Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn yìí?

Kí Ni Bíbélì Sọ

Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, a rí àwọn ìtọ́ni pàtó nípa ohun tó yẹ kẹ́nì kan ṣe tó bá dẹ́ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹnì kan bá ṣẹ èèyàn tàbí tó bá rú ọ̀kan lára òfin Ọlọ́run, ó ní láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún àlùfáà tó jẹ́ ẹ̀yà Léfì, àlùfáà yìí yóò ṣe ètùtù nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà nípa rírú ẹbọ sí Ọlọ́run fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.—Léfítíkù 5:1-6.

Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí wòlíì Nátánì bá Dáfídì Ọba wí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ni Dáfídì ṣe? Lójú ẹsẹ̀ ló gbà, ó ní: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.” (2 Sámúẹ́lì 12:13) Ó tún gbàdúrà, ó bẹ Ọlọ́run pé kí ó fojú rere hàn sóun. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Dáfídì wá sọ lẹ́yìn náà pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìṣìnà mi ni èmi kò sì bò mọ́lẹ̀. Mo wí pé: ‘Èmi yóò jẹ́wọ́ àwọn ìrélànàkọjá mi fún Jèhófà.’ Ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.”—Sáàmù 32:5; 51:1-4.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run ṣì béèrè pé kí àwọn Kristẹni máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Jákọ́bù ọmọ ìyá Jésù tó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù, rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ máa jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbangba fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ lè gba ìmúláradá.” (Jákọ́bù 5:16) Nígbà náà, irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni àwọn Kristẹni máa jẹ́wọ́ rẹ̀, ta ni wọ́n sì máa jẹ́wọ́ fún?

Irú Ẹ̀ṣẹ̀ Wo Ló Yẹ Kí Èèyàn Jẹ́wọ́ Rẹ̀?

Ojoojúmọ́ ni àwa èèyàn aláìpé máa ń hùwà láìronú tàbí ká ṣi ahọ́n wa lò, tá a sì máa ń ṣẹ àwọn ẹlòmíì. (Róòmù 3:23) Ṣé ó wá pọn dandan pé ká jẹ́wọ́ irú àṣìṣe wọ̀nyí fún ẹnì kan tá a yàn sípò àṣẹ tàbí aṣojú kan?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni kò dára lójú Ọlọ́run, ó máa ń fi àánú hàn sí wa nítorí àìpé tá a jogún. Ìdí nìyẹn tí onísáàmù náà fi sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.” (Sáàmù 130:3, 4) Nítorí náà, kí ló yẹ ká ṣe nígbà tí a bá ṣàṣìṣe tá a sì ṣẹ àwọn ẹlòmíì láìmọ̀ọ́mọ̀? Rántí pé àdúrà àwòfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀bẹ̀ kan nínú tó sọ pé: “Dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa fúnra wa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè.” (Lúùkù 11:4) Ó dájú pé Ọlọ́run á dárí jì wá tá a bá tọrọ ìdáríjì lórúkọ Jésù.—Jòhánù 14:13, 14.

Kíyè sí i pé Jésù fi kún un pé ká tó lè rí ìdáríjì gbà, a ní láti dárí ji àwọn “tí ó jẹ wá ní gbèsè.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ létí pé: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfésù 4:32) Tá a bá dárí àṣìṣe àwọn ẹlòmíì jì wọ́n, ìgbà yẹn la tó lè retí pé kí Ọlọ́run dárí àṣìṣe wa jì wá.

Àmọ́, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńkọ́, irú bí olè jíjà, mímọ̀ọ́mọ̀ parọ́, ìṣekúṣe, ìmutípara àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ? Òfin Ọlọ́run ni ẹnikẹ́ni tó bá ń lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ń rú, ó sì ń dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. Ṣé ó yẹ kẹ́ni náà jẹ́wọ́?

Ta Ló Yẹ Kéèyàn Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Fún?

Ọlọ́run kò fún èèyàn láṣẹ láti dárí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ sí òun, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè dárí irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ jini. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: “Bí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, òun jẹ́ aṣeégbíyèlé àti olódodo tí yóò fi dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, tí yóò sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo.” (1 Jòhánù 1:9) Àmọ́, ta ló yẹ kéèyàn jẹ́wọ́ irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún?

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ló máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, òun ni a gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún. Ohun tí Dáfídì ṣe nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀. Àmọ́, kí ló máa mú kéèyàn rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà? Bíbélì sọ fún wa: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àwọn àsìkò títunilára lè wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 3:19) Yàtọ̀ sí pé kéèyàn gbà pé ìwà tóun hù kò dára, kó sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó tún ní láti fínnú fíndọ̀ jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́ náà. Àmọ́ ṣá o, èyí kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti ṣe. Ṣùgbọ́n ìrànlọ́wọ́ wà.

Rántí ọ̀rọ̀ tí ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà, Jákọ́bù sọ, èyí tá a tọ́ka sí níbẹ̀rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ máa jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbangba fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ lè gba ìmúláradá.” Jákọ́bù fi kún un pé: “Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo, nígbà tí ó bá wà lẹ́nu iṣẹ́, ní ipá púpọ̀.” (Jákọ́bù 5:16) ‘Olódodo’ tí ibí yìí ń sọ lè jẹ́ ọ̀kan lára “àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ,” èyí tí Jákọ́bù mẹ́nu kàn ní ẹsẹ 14. “Àwọn àgbà ọkùnrin” nípa tẹ̀mí tàbí àwọn alàgbà wà nínú ìjọ Kristẹni láti ran àwọn tó ń fẹ́ ìdáríjì Ọlọ́run lọ́wọ́. Irú “àwọn àgbà ọkùnrin” bẹ́ẹ̀ kò lè pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́, nítorí Ọlọ́run kò fún èèyàn láṣẹ láti dárí jì èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. a Àmọ́, wọ́n kúnjú ìwọ̀n nípa tẹ̀mí láti báni wí, kí wọ́n sì mú ẹni tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá bọ̀ sípò, tí wọ́n á ràn án lọ́wọ́ láti rí bí ẹ̀ṣẹ̀ náà ti wúwo tó àti ìdí tó fi yẹ kó ronú pìwà dà.—Gálátíà 6:1.

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kéèyàn Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀?

Bóyá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kékeré, ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà ti ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú èèyàn àti Ọlọ́run jẹ́. Nítorí náà, ìdààmú tàbí àníyàn lè bá ẹni náà. Ẹ̀rí ọkàn tí Ẹlẹ́dàá dá mọ́ wa ló ń ṣiṣẹ́ yẹn. (Róòmù 2:14, 15) Kí ni ẹni náà lè ṣe?

Nígbà tá a tún wo ìwé Jákọ́bù lẹ́ẹ̀kan sí i, a rí ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí tó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn láàárín yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.”—Jákọ́bù 5:14, 15.

Ibí yìí tún jẹ́ ká rí i pé àwọn àgbà ọkùnrin tàbí àwọn alàgbà ní láti bójú tó ohun tí agbo nílò. Báwo? Kì í ṣe kí wọ́n kàn gbọ́ ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan láti “mú aláàárẹ̀ náà lára dá,” nítorí àìsàn nípa tẹ̀mí tó ń ṣe é. Jákọ́bù mẹ́nu kan ohun méjì tí wọ́n lè ṣe.

Ohun àkọ́kọ́ ni fífi ‘òróró pa aláìsàn.’ Èyí ń tọ́ka sí agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní láti woni sàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà,” ìyẹn ni pé ó lágbára láti dénú èrò àti ọkàn ẹni. (Hébérù 4:12) Nípa lílo Bíbélì lọ́nà tó jáfáfá, àwọn àgbà ọkùnrin lè ran ẹni tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí lọ́wọ́ láti rí ohun tó fa ìṣòro náà, kó sì ṣe nǹkan kan láti tún àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe.

Ohun kejì ni “àdúrà ìgbàgbọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdúrà àwọn àgbà ọkùnrin kò ní yí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run pa dà, àmọ́ àdúrà yìí ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run tó ṣe tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini nítorí ẹbọ ìràpadà Kristi. (1 Jòhánù 2:2) Ọlọ́run múra tán láti ṣèrànwọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ èyíkéyìí tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tó sì ṣe “àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.”—Ìṣe 26:20.

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì jù lọ pé kí ẹnì kan jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ sí èèyàn tàbí sí Ọlọ́run ni láti rí ojú rere Ọlọ́run. Jésù Kristi fi hàn pé a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ yanjú ìṣòro èyíkéyìí tó wà láàárín àwa àtàwọn èèyàn, ká sì wá àlàáfíà pẹ̀lú wọn kí a tó lè jọ́sìn Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rere. (Mátíù 5:23, 24) Ìwé Òwe 28:13 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” Tí a bá rẹ ara wa sílẹ̀ lójú Jèhófà Ọlọ́run tá a sì tọrọ ìdáríjì, a óò rí ojú rere rẹ̀, yóò sì gbé wa ga ní àkókò tó yẹ.—1 Pétérù 5:6.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èrò àwọn kan ni pé ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Jòhánù 20:22, 23 ṣètìlẹ́yìn fún èrò náà pé èèyàn lágbára láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ẹni tó ṣẹ Ọlọ́run. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí kókó yìí, ka Ilé-Ìṣọ́nà, April 15, 1996, ojú ìwé 28 sí 29.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]

Ọlọ́run yóò gbójú fo àwọn àṣìṣe wa, yóò sì dárí jì wá, tá a bá tọrọ ìdáríjì lórúkọ Jésù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì jù lọ pé kí ẹnì kan jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni láti rí ojú rere Ọlọ́run