Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Amágẹ́dọ́nì—Kí Ni Àwọn Èèyàn Kan Sọ Pé Ó Jẹ́?

Amágẹ́dọ́nì—Kí Ni Àwọn Èèyàn Kan Sọ Pé Ó Jẹ́?

Amágẹ́dọ́nì—Kí Ni Àwọn Èèyàn Kan Sọ Pé Ó Jẹ́?

“Wọ́n sì kó wọn jọpọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”—ÌṢÍPAYÁ 16:16.

TÓ O bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì,” kí lo máa rò pé ó jẹ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àjálù runlérùnnà kan tó burú jáì ló máa ń wá sí ọkàn rẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan péré ni Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà Amágẹ́dọ́nì, léraléra làwọn oníròyìn àti àwọn aṣáájú ìsìn máa ń lò ó.

Ǹjẹ́ ohun tí àwọn èèyàn máa ń sọ nípa Amágẹ́dọ́nì bá ohun tí Bíbélì kọ́ni mu? Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé tó o bá mọ ohun tí Amágẹ́dọ́nì jẹ́ gan-an, ó lè jẹ́ kó o bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù, kí ọkàn rẹ sì balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, yóò sì jẹ́ kó o ní èrò rere nípa Ọlọ́run.

Ṣàgbéyẹ̀wò ìbéèrè mẹ́ta tó tẹ̀ lé e yìí, kó o sì fi ohun tí àwọn èèyàn máa ń sọ nípa Amágẹ́dọ́nì wé ohun tí Bíbélì kọ́ni gan-an.

1. ṢÉ ÀJÁLÙ KAN TÓ MÁA TỌWỌ́ ÈÈYÀN WÁ NI AMÁGẸ́DỌ́NÌ?

Àwọn akọ̀ròyìn àti àwọn olùṣèwádìí sábà máa ń pe àwọn àjálù tó burú jáì tí àwọn èèyàn fà ní Amágẹ́dọ́nì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n pe Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ìkejì ní Amágẹ́dọ́nì. Lẹ́yìn ogun méjèèjì yẹn, àwọn èèyàn ń bẹ̀rù pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ilẹ̀ Soviet Union lè fi àwọn bọ́ǹbù runlérùnnà bá ara wọn jà. Àwọn oníròyìn pe ogun tí wọ́n rò pé ó lè wáyé yẹn ní Amágẹ́dọ́nì, wọ́n ní bọ́ǹbù runlérùnnà ló máa fà á. Lóde òní, àwọn olùṣèwádìí kan ń ṣàníyàn pé bí àwọn èèyàn ṣe ń ba àyíká jẹ́ máa mú kí ojú ọjọ́ yí pa dà lọ́nà tó burú jáì kárí ayé, wọ́n wá kìlọ̀ pé èyí máa yọrí sí àjálù búburú kan tí wọ́n pè ní Amágẹ́dọ́nì.

Ohun tí ọ̀rọ̀ wọn túmọ̀ sí: Yálà ayé yìí àti àwọn ohun alààyè inú rẹ̀ máa pa run tàbí ó máa dára sí i lọ́jọ́ iwájú, ọwọ́ àwa èèyàn ló wà. A jẹ́ pé tí àwọn ìjọba kò bá ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, ayé yìí lè bà jẹ́ kọjá àtúnṣe.

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí àwọn èèyàn pa ayé run. Bíbélì mú kó dá wa lójú pé Jèhófà * “kò wulẹ̀ dá [ilẹ̀ ayé] lásán.” Àti pé ó ṣẹ̀dá rẹ̀ “kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Dípò tí Ọlọ́run á fi jẹ́ kí àwọn èèyàn ba ilẹ̀ ayé yìí jẹ́ pátápátá, ṣe ni yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.

2. ṢÉ ÀJÁLÙ KAN TÓ LÉ KENKÀ NI AMÁGẸ́DỌ́NÌ?

Nígbà míì, àwọn akọ̀ròyìn máa ń pe àwọn àjálù ńláńlá ní Amágẹ́dọ́nì. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2010, ìròyìn kan gbé e jáde pé “‘Amágẹ́dọ́nì’ wáyé lórílẹ̀-èdè Haiti.” Ìròyìn náà sọ nípa ìyà, àdánù àti ọ̀pọ̀ ẹ̀mí tó ṣòfò nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó bùáyà ba orílẹ̀-èdè yẹn jẹ́. Kì í ṣe àwọn àjálù tó ti ṣẹlẹ̀ nìkan ni àwọn oníròyìn àti àwọn tó ń ṣe fíìmù máa ń pè ní Amágẹ́dọ́nì, wọ́n tún máa ń pe àjálù tí wọ́n bá ń bẹ̀rù pé ó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú ní Amágẹ́dọ́nì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi orúkọ náà Amágẹ́dọ́nì pe àjálù tí wọ́n rò pé ó máa wáyé tí ìràwọ̀ asteroid bá já lu ayé yìí.

Ohun tí ọ̀rọ̀ wọn túmọ̀ sí: Lójú tiwọn, Amágẹ́dọ́nì jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó kàn máa ń pa àwọn ẹni ẹlẹ́ni tó bá ṣe kòńgẹ́ rẹ̀. Kò sì sí ohun tí o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ ewu náà.

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe àjálù tó kàn máa pa gbogbo èèyàn tó bá wà níbikíbi tó bá ti ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn burúkú nìkan ni ogun Amágẹ́dọ́nì yóò pa run. Bíbélì ṣèlérí pé láìpẹ́ “ẹni burúkú kì yóò . . . sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí.”—Sáàmù 37:10.

3. ṢÉ ỌLỌ́RUN MÁA PA AYÉ RUN NÍGBÀ AMÁGẸ́DỌ́NÌ?

Ọ̀pọ̀ àwọn onísìn ló gbà gbọ́ pé ogun àjàkẹ́yìn kan máa wáyé láàárín ibi àti ire, èyí tó máa mú kí ayé yìí pa run. Nígbà tí àjọ kan, ìyẹn Princeton Survey Research Associates, ṣe ìwádìí káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n rí i pé, ìdámẹ́rin nínú mẹ́wàá lára àwọn àgbàlagbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà gbọ́ pé ayé yìí yóò pa run “nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.”

Ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yìí fi hàn pé: Ọlọ́run kò dá èèyàn pé kí wọ́n wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ayé pé kó wà títí lọ gbére. Àti pé bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn èèyàn ni pé tó bá ti tó àkókò kan kí gbogbo wọn kàn ṣàdédé kú.

Ohun tí Bíbélì sọ: Bíbélì sọ ọ́ kedere pé Ọlọ́run “fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn inú ayé pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

Ó ṣe kedere pé, ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ń sọ nípa Amágẹ́dọ́nì. Kí wá ni Amágẹ́dọ́nì jẹ́ gan-an?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Bíbélì sọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.