Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àwọn Obìnrin Tó Jẹ́ Òjíṣẹ́ Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àwọn Obìnrin Tó Jẹ́ Òjíṣẹ́ Ọlọ́run?

Bẹ́ẹ̀ ni. Kárí ayé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn obìnrin tí ó tó mílíọ̀nù mélòó kan tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn obìnrin yìí jẹ́ àwùjọ ńlá tí ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Sáàmù 68:11 sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn òjíṣẹ́ yìí, ó ní: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó sọ àsọjáde náà; àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.”

Àmọ́ ṣá o, iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí àwọn obìnrin ń ṣe láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò dà bí irú èyí tí àwọn obìnrin tó jẹ́ aṣáájú ìsìn ń ṣe nínú àwọn ẹ̀sìn yòókù. Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ wà láàárín wọn. Àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n gbà yàtọ̀ síra?

Àwọn tí obìnrin tó jẹ́ òjíṣẹ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wàásù fún yàtọ̀ sí irú àwọn tí obìnrin tó jẹ́ aṣáájú ìsìn ń wàásù fún. Bí àpẹẹrẹ, àwọn obìnrin tó jẹ́ aṣáájú ìsìn máa ń ṣe olùdarí nínú ìjọ wọn, pàápàá láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, àwọn ọmọ ìjọ wọn ni wọ́n sì sábà máa ń wàásù fún. Ní ti àwọn obìnrin tó jẹ́ òjíṣẹ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í ṣe àwọn ọmọ ìjọ wọn ni wọ́n sábà máa ń wàásù fún, àwọn tí wọ́n máa ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé àti níbòmíì ni.

Ohun mìíràn tí àwọn obìnrin tó jẹ́ òjíṣẹ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi yàtọ̀ sí àwọn obìnrin tó jẹ́ òjíṣẹ́ nínú àwọn ẹ̀sìn yòókù ni ohun tí wọ́n máa ń ṣe nínú ìjọ. Àwọn obìnrin tó jẹ́ aṣáájú ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì tàbí nínú àwọn ẹ̀sìn míì máa ń darí ìsìn, wọ́n sì máa ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn ní ẹ̀kọ́ àti ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn wọn. Àwọn obìnrin tó jẹ́ òjíṣẹ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í kọ́ni láàárín ìjọ nígbà tí àwọn ọkùnrin tó ti ṣe ìrìbọmi bá wà níbẹ̀. Kìkì àwọn ọkùnrin tí wọ́n bá yàn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ló máa ń kọ́ni láàárín ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—1 Tímótì 3:2; Jákọ́bù 3:1.

Bíbélì fi hàn pé àwọn ọkùnrin nìkan ló tọ́ láti yàn kí wọ́n máa bójú tó ìjọ. Wo àpẹẹrẹ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ nígbà tó kọ̀wé sí Títù tó jẹ́ alábòójútó bíi tirẹ̀. Ó ní: “Fún ìdí yìí ni mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí o lè . . . yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá.” Pọ́ọ̀lù fi kún un pé ọkùnrin tí wọ́n bá yàn gbọ́dọ̀ wà “láìní ẹ̀sùn lọ́rùn, ọkọ aya kan.” (Títù 1:5, 6) Pọ́ọ̀lù fún Tímótì ní irú ìtọ́ni yìí nínú ìwé tó kọ sí i nípa ètò inú ìjọ, ó ní: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́. Nítorí náà, alábòójútó ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, . . . ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni.”—1 Tímótì 3:1, 2.

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ọkùnrin nìkan ló ni ojúṣe ṣíṣe àbójútó nínú ìjọ? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èmi kò gba obìnrin láyè láti kọ́ni, tàbí láti lo ọlá àṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe láti wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Nítorí Ádámù ni a kọ́kọ́ ṣẹ̀dá, lẹ́yìn náà Éfà.” (1 Tímótì 2:12, 13) Bó ṣe jẹ́ pé ọkùnrin ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá pàápàá, jẹ́ ká rí ìdí tí Ọlọ́run fi fa iṣẹ́ kíkọ́ni àti ṣíṣe àbójútó lé àwọn ọkùnrin lọ́wọ́.

Àpẹẹrẹ Jésù Kristi Aṣáájú wọn ni àwọn òjíṣẹ́ Jèhófà ń tẹ̀ lé. Lúùkù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó ní: “Ó ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà, Jésù rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jáde láti lọ ṣe irú iṣẹ́ yìí kan náà: “Wọ́n la ìpínlẹ̀ náà já láti abúlé dé abúlé, ní pípolongo ìhìn rere.”—Lúùkù 8:1; 9:2-6.

Nítorí náà, lónìí, gbogbo òjíṣẹ́ Jèhófà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ló ń kó ipa kíkún nínú iṣẹ́ tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.