Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Kejì: Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Mi Nígbà Tí Mo Bá Kú?

Ìbéèrè Kejì: Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Mi Nígbà Tí Mo Bá Kú?

NÍGBÀ tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Roman ṣì wà lọ́mọdé, ọkọ̀ pa ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kan. Ó sọ pé: “Ikú ọ̀rẹ́ mi yìí dùn mí gan-an. Lẹ́yìn ìjàǹbá náà, ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń ronú nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ séèyàn nígbà téèyàn bá kú.”

Kí ló ń jẹ́ káwọn èèyàn béèrè irú ìbéèrè yìí?

Ikú jẹ́ ohun tí kì í bá àwa èèyàn lára mu. Bó ti wù ká dàgbà tó, a kì í sábà fẹ́ kú. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá kú.

Kí ni àwọn kan sọ nípa ìbéèrè yìí?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé tí a bá kú nǹkan kan wà lára wa tí kì í kú. Wọ́n gbà gbọ́ pé táwọn èèyàn rere bá kú wọn yóò lọ sí ọ̀run, àmọ́ àwọn èèyàn burúkú yóò máa joró títí láé nínú ọ̀run àpáàdì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn míì sì gbà pé téèyàn bá ti kú onítọ̀hún kò sí mọ́ nìyẹn, pé aráyé a sì gbàgbé rẹ̀ tó bá yá.

Kí làwọn ìdáhùn yìí ń fi hàn?

Ohun tí ìdáhùn àkọ́kọ́ ń fi hàn ni pé téèyàn bá ṣaláìsí ó kàn papò dà lásán ni. Ìdáhùn kejì sì túmọ̀ sí pé kò sídìí kan gúnmọ́ tí a fi wà láàyè. Àwọn tó máa ń ronú pé kò sídìí kan gúnmọ́ tí a fi wà láàyè máa ń gbà pé kádàrá ni gbogbo nǹkan. Irú wọn ló máa ń dáṣà pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.”—1 Kọ́ríńtì 15:32.

Kí ni Bíbélì fi kọ́ni?

Bíbélì kò sọ pé tí a bá kú nǹkan kan wà lára wa tí kì í kú. Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti kọ̀wé pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Àwọn tí “kò mọ nǹkan kan rárá” kò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká wọn mọ́. Wọn kò lè ṣe ohunkóhun, wọn kò sì mọ nǹkan kan lára mọ́. Torí náà òkú kò lè ran alààyè lọ́wọ́, wọn kò sì lè pa alààyè lára.

Ète Ọlọ́run fún àwa èèyàn yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ, pé Ọlọ́run dá ikú mọ́ wa. Kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run rárá pé kí àwa èèyàn máa kú. Ṣe ni ó dá Ádámù lọ́nà tí á fi lè máa wà láàyè lọ títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ìgbà tí Ọlọ́run ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Ádámù tó bá ṣàìgbọràn nìkan ni Ọlọ́run mẹ́nu kan ikú. Ó sọ pé Ádámù kò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi kan, ó sì wá kìlọ̀ fún un pé tó bá jẹ̀ ẹ́ “dájúdájú . . . yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ká ní Ádámù àti Éfà kò ṣàìgbọràn ni, àwọn àti gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ì bá wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.

Ṣe ni Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ má tẹ̀ lé ìkìlọ̀ Ọlọ́run. Torí náà ẹ̀ṣẹ̀ ló dá nígbà tó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tó fi kú. (Róòmù 6:23) Nígbà tí Ádámù kú, kò sí nǹkan kan lára rẹ̀ tó tún ṣì wà láàyè, tí kò kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí Ádámù ṣe kú, kò sí níbikíbi mọ́. Ohun tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù ni pé: “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Nígbà tó sì jẹ́ pé Ádámù ni baba ńlá gbogbo ìran èèyàn, ọ̀dọ̀ rẹ̀ la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Róòmù 5:12.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn, Ọlọ́run ṣì máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn, ìyẹn láti mú kí àwọn èèyàn pípé tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Aísáyà 55:11) Láìpẹ́ Jèhófà máa jí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ti kú dìde. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà yẹn, ó ní: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.

Ọkùnrin tó ń jẹ́ Roman tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá mọ ohun tó sọ nípa ikú àti irú ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Àwọn ohun tí ó wá mọ̀ yìí ní ipa tó jinlẹ̀ lórí rẹ̀. Ka ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ lójú ìwé 11 nínú ìwé ìròyìn yìí.