ILÉ ÌṢỌ́ December 2012 | Ohun Kan Wà Tó Dára Ju Kérésìmesì lọ

Báwo lo ṣe rò pé ó yẹ kí Kérésìmesì máa rí? Ṣé ohun kan wà tó dára jù ú lọ?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Gbà Pé Ó Ṣe Pàtàkì Nígbà Kérésì?

Ohun pàtàkì ni kéèyàn wáyè láti fara mọ́ ìdílé, ran àwọn aláìní lọ́wọ́ àti kéèyàn rántí Jésù. Àmọ́ kí ló ṣe pàtàkì jù?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Rírántí Jésù Kristi

Ọnà wo ló dáa jù táa lè gbà bọ̀wọ̀ fún Jésù ká sì máa rántí rẹ̀?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Rírí Ayọ̀ Látinú Fífúnni Lẹ́bùn

Ẹ̀bùn táwọn èèyàn máa ń fúnni lásìkò Kérésìmesì sábà máa ń tánni lókun ju kó fúnni láyọ̀ lọ. Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣíṣe Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Aláìní

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká máa ṣoore, ká sì máa fúnni nigbà gbogbo yí ká ọdún. Ìmọ̀ràn pàtó wo ló fún wa?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Wíwá Àyè Láti Fara Mọ́ Ìdílé

Ọ̀pọ̀ ìdílé máa ń fojú sọ́nà fún Kérésìmesì torí wọ́n á lè jọ wà pa pọ̀, wọ́n á sì gbádùn ara wọn. Àmọ́, kí nìdí tí kìí fi rọrùn?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Àlàáfíà Láàárín Àwọn Ẹni Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí

Kí ló lè mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbádùn àlááfíà tó máa tọ́jọ́?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Wọ́n Rí Ohun Tó Dára Jù

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni ni kìí ṣe ọdún Kérésìmesì. Báwo ni ìpinnu yìí ṣe rí lára wọn?

ÀWỌN ÒǸKÀWÉ WA BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tí Àwọn Kan Kì Í Fi í Ṣe Kérésìmesì?

Wo ìdí mẹ́rin tí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jésù kìí fi ṣe Kérésìmesì.

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú “Ìwé Ìrántí” Ọlọ́run?

Kí ni ìwé yìí, báwo sì lorúkọ rẹ ṣe lè wọ ibẹ̀?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ní Gbẹ̀yìn Gbẹ́yín Mo Di Òmìnira!

Kà nípa bí Maria Kilin ṣé fara da ìyà tó jẹ lẹ́wọ̀n ní orílẹ̀-èdè North Korea, àti bí òtítọ́ Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́ láti ní òmìnira tòótọ́.

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Rán Jésù Wá Sí Ayé?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tí Jésù fi wá sí ayé àti bá a ṣe ń jàǹfàní lónìí.

Ǹjẹ́ O Rò Pé Èèyàn Máa Ń Tún Ayé Wá?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbàgbọ́ nínú àtúnwáyé. Àmọ́ ṣé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa iyọ̀ tó wà nínú Òkun Òkú àti bí ẹyọ owó dírákímà ṣe ṣe pàtàkì tó nígbà ayé Jésù.

Ṣé Apá Mi Á Lè Ká Ohun Tí Mo Dáwọ́ Lé Yìí?

Kà nípa bí miṣọ́nnárì kan lórílẹ̀-èdè Benin ṣe kọ́ èdè àwọn adití kó lè ran àwọn adití lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run.

Bí Wọ́n Ṣe Ń Lo Ohun Ìṣaralóge Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Kí làwọn obìnrin máa ń lò láti fi gbé ẹwà wọn yọ ní ayé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

“Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Ti Ṣẹlẹ̀ Àmọ Ẹ Fi Ṣàríkọ́gbọ́n”

Ní April 1, 1951, Ọgọ́ọ̀rọ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n lé kúrò nílùú Estonia lọ sí Siberia. Kí nìdí?

KỌ ỌMỌ RẸ

Jótámù Jẹ́ Olóòótọ́ Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Bàbá Rẹ̀ Kò Sin Jèhófà Mọ́

Báwp lo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run kódà tí àwọn òbí rẹ ò bá ṣe bẹ́ẹ̀?