ILÉ ÌṢỌ́ May 2013 | Ṣé Ìkà Ni Ọlọ́run?
Àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí àti àkọ́sílẹ̀ àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì mú kí ọ̀pọ̀ máa ronú nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Ṣé òótọ́ ni pé ìkà ni Ọlọ́run? Kí ni ẹ̀rí fi hàn?
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Kí Nìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Sọ Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?
Àwọn èèyàn kan rò pé ìkà ni Ọlọ́run tàbí pé ọ̀rọ̀ wa kò ká a lára? Kí ni Bíbélì sọ?
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ṣé Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Fi Hàn Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?
Nígbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run kórìíra ìwà ìkà, kí ló dé tó fi ń jẹ́ kí àwọn àjálù gba ẹ̀mí àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀?
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ṣé Àwọn Ìdájọ́ Ọlọ́run Fi Hàn Pé Ìkà Ni?
Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì nínú àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì. A máa wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún-omi ọjọ́ Nóà àti nígbà ìparun àwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì.
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ṣé Wàá Fọkàn Tán Ọlọ́run?
Wo bí ọ̀kàn rẹ ṣe máa balẹ̀ tó tóo bá mọ Ọlọ́run bí ọ̀rẹ́ tó ṣee fọkàn tán.
BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
“Ó Wù Mí Kí N Di Àlùfáà”
Láti ìgbà tí Roberto Pacheco ti jẹ́ ọ̀dọ́ ló ti ń wù ú pé kó di àlùfáà nínú ìjọ Kátólí ìkì. Wo ohun tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.
OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀
Bí Àárín Àwọn Tó Tún Ìgbéyàwó Ṣe Àti Àwọn Ẹlòmí ì Ṣe Lè Tòrò
Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè mú kí ọkùnrin tàbí obìnrin tó lọ fẹ́ ẹlòmí ì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àti ẹni tí wọ́n ń fẹ́ tẹ́lẹ̀?
SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ Jẹ Jèhófà Lógún Lóòótọ́?
Ǹjẹ́ ó ṣòro fún ẹ láti gbà pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ Ọlọ́run lógún? Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní Jòhánù 6:44 fi ẹ̀rí tó lágbára hàn pé ọ̀rọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ Ọlọ́run lógún.
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì jini? Tí a bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọrun, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
Òtítọ́
Ibo lo ti lè rí i? Báwo ni òtítọ́ ṣe lè ṣe ìwọ àti ìdílé rẹ láǹfààní? A pè ọ́ tayọ̀tayọ̀ kí o wá gbọ́ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí ní àpéjọ ọlọ́jọ́-mẹ́ta wa.
Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì
Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Rò Pé Àwọn Nìkan Ló Máa Rí Ìgbàlà?
Bíbélì ṣàlàyé àwọn tó máa rí ìgbàlà.