Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ẹ̀sìn Kankan Tiẹ̀ Wà Téèyàn Lè Gbára Lé?

Ǹjẹ́ Ẹ̀sìn Kankan Tiẹ̀ Wà Téèyàn Lè Gbára Lé?

Tí ẹ̀sìn kan bá ti já ẹ kulẹ̀ rí, ó lè má rọrùn fún ẹ láti gbára lé ẹ̀sìn kankan. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ẹ̀sìn kan tí o lè gbára lé ṣì wà. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn olóòótọ́ kan jọ, ó sì kọ́ wọn pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ìyẹn àwọn tí wọ́n ń rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé ìlànà Kristẹni ṣì wà. Báwo ni wàá ṣe dá wọn mọ̀?

Estelle tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ kejì, sọ pé: “Ìgbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ ni mo tó bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ nípa Bíbélì. Kò pẹ́ rárá tí mo fi lóye ohun tó wà nínú Jòhánù 8:32, ó ní: ‘Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.’”

Ray, tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mo tó mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro aráyé. Inú mi dùn nígbà tí mo mọ̀ pé ó ní ìdí tí Ọlọ́run ṣì fi fàyè gba ìwà ibi àti pé ó ti ṣèlérí pé òun máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò láìpẹ́.”

Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti máa ṣe ohun tí ó tọ́ láàárín àwọn èèyàn tí ìwà rere ò jámọ́ nǹkan kan lójú wọn. Àmọ́, ó ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ẹni tó máa ran àwọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì lè máa fi í sílò. Ìdí nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ kárí ayé. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an, èyí sì ń mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì ń láyọ̀ nígbèésí ayé wọn. *

Bi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà léèrè ìdí tí wọ́n fi gbára lé ẹ̀sìn wọn

Nígbà míì tó o bá tún rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bi wọ́n léèrè ìdí tí wọ́n fi gbára lé ẹ̀sìn wọn. Wádìí nípa wọn, kí o sì ṣàyẹ̀wò ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Kó o wá pinnu fúnra rẹ bóyá ẹ̀sìn tó o lè gbára lé ṣì wà.

^ ìpínrọ̀ 5 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, ka ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.