Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fẹ́ Kí Àwọn Ẹ̀sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Máa Jọ́sìn Pa Pọ̀?
Nínú ìwé ìròyìn The Sydney Morning Herald wọ́n béèrè pé: “Ṣé ìsìn máa ń jẹ́ ká wà ní ìṣọ̀kan ni àbí ó máa ń fa ìyapa?” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó èèyàn mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá tó sọ pé ìsìn máa ń fa ìyapa.
ÀMỌ́, èrò àwọn alámùúlùmálà ìgbàgbọ́, ìyẹn àwọn tó gbà pé kí àwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa jọ́sìn pọ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn sọ lókè yìí. Eboo Patel tó dá ẹgbẹ́ Interfaith Youth Core sílẹ̀ sọ pé: “Kò sí ẹ̀sìn tí kì í fẹ́ ṣàánú . . . , tí kì í fẹ́ kí àwọn èèyàn máa tún àyíká ṣe . . . , tí kì í sì í fẹ́ kí àwọn ọmọ ìjọ máa kó èèyàn mọ́ra.”
Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù, àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí àti àwọn ẹlẹ́sìn lónírúurú ti pawọ́ pọ̀ láti gbógun ti ipò òṣì, láti jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti láti fòfin de ríri bọ́ǹbù mọ́lẹ̀. Kódà, wọ́n tún gbìyànjú láti wá ojútùú sí bí àwọn kan ṣe ń ba àyíká jẹ́. Onírúurú àpérò ni àwọn ẹlẹ́sìn wọ̀nyí ti ṣe láti wá ọ̀nà bí àwọn èèyàn á ṣe máa gbé ní ìṣọ̀kan, tí wọ́n á sì máa ran ara wọn lọ́wọ́. Láìka ẹ̀yà àti ìran ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ti wá sí, onírúurú nǹkan ni wọ́n máa ń ṣe nígbà ayẹyẹ ìpàdé wọn. Lára rẹ̀ ni pé, wọ́n á tan àbẹ́là, wọ́n á ṣe àríyá, wọ́n á kọrin, wọ́n á sì gbàdúrà.
Ṣé bí àwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe ń jọ́sìn pa pọ̀ ló máa yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wọn? Ṣé àmúlùmálà ìgbàgbọ́ ni Ọlọ́run máa fi tún ayé yìí ṣe?
KÍ NI WỌ́N ṢE LÁTI LÈ WÀ NÍ ÌṢỌ̀KAN?
Ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ alámùúlùmálà ìgbàgbọ́ tó gbòòrò gan-an tiẹ̀ fọ́nnu pé òun ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó wá láti onírúurú ẹ̀sìn tó ju igba [200] lọ àti pé láti orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá. Wọ́n ní, àwọn dá ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ kí “àwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè wà ní ìṣọ̀kan, kí wọ́n sì lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nígbà gbogbo.” Lóòótọ́, ẹnu wọ́n dùn, àmọ́ kò jọ pé ohun tí wọ́n sọ yẹn ṣeé ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ńṣe ni wọ́n fara balẹ̀ ṣe àkọsílẹ̀ ìwé òfin tí wọ́n fi dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀, tìṣọ́ratìṣọ́ra ni wọ́n sì fi kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kí wọ́n má bàa ṣẹ onírúurú ẹgbẹ́ àti àwọn ẹ̀sìn tó buwọ́ lu ìwé òfin náà. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ohun tó fà á ni pé, ẹnu wọn ò kò lórí bóyá kí wọ́n fi orúkọ Ọlọ́run sí i tàbí kí wọ́n má fi sí i. Ni wọ́n bá kúkú yọ ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run kúrò nínú ìwé òfin yìí pátápátá.
Tí kò bá sí ibì kankan nínú ìwé òfin wọn tó tọ́ka sí Ọlọ́run, kí wá ni àwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ń jọ́sìn pa pọ̀ ńṣe? Àti pé, ṣé irú àmúlùmálà ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn ẹgbẹ́ aláàánú tó kàn ń fowó ṣàánú? Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbà pé àwọn kì í ṣe àwùjọ ẹ̀sìn ní pàtó, ṣùgbọ́n “ẹgbẹ́ tó ń ṣagbátẹrù ìfọwọ́sowọ́pọ̀” ni àwọn jẹ́.
ṢÉ ÌWÀ RERE NÌKAN NI WỌ́N FI Ń MỌ Ẹ̀SÌN?
Dalai Lama tó jẹ́ abẹnugan nínú àwọn tó sọ pé ó yẹ kí àwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa jọ́sìn pa pọ̀, sọ pé: “Gbogbo ẹ̀sìn ló ń kọni pé kéèyàn ní ìfẹ́, àánú, àti ìdáríjì. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, kí á máa fi àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ṣe ìwà hù lójoojúmọ́.”
Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, àwọn ìwà ọmọlúwàbí bí ìfẹ́, àánú àti ìdáríjì kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Ohun tí Jésù náà sọ nìyẹn, ó ní: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Ṣùgbọ́n, ṣé kéèyàn ṣáà ti máa gbé ìwà rere lárugẹ nìkan ti tó láti ní ojúlówó ìgbàgbọ́?
Nígbà tí Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó pera wọn ní olùjọsìn Ọlọ́run nígbà yẹn, ó ní: “Mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” Kí ló fà á? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nítorí, fún ìdí náà pé wọn kò mọ òdodo Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé tiwọn kalẹ̀.” (Róòmù 10:2, 3) Nítorí tí wọn kò ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe, asán ni gbogbo ìtara àti ìgbàgbọ́ wọ́n já sí.— Mátíù 7:21-23.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÀMÚLÙMÚLÀ ÌGBÀGBỌ́
Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” (Mátíù 5:9) Ohun tí Jésù ń wàásù rẹ̀ fún àwọn èèyàn kò yàtọ̀ sí àwọn ohun tó hù níwà. Nítorí ó kórìíra ìwà ipá, ọ̀rọ̀ àlàáfíà ló máa ń sọ fún gbogbo èèyàn láìka onírúurú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí. (Mátíù 26:52) Àwọn tó kọbi ara sí ẹ̀kọ́ Jésù ti fi ìfẹ́ sọ ara wọn di ọ̀kan. (Kólósè 3:14) Àmọ́, ṣé Jésù kàn ń ṣagbátẹrù ìfọwọ́sowọ́pọ̀ torí kí àlàáfíà lè wà láàárín àwọn èèyàn tí wọ́n wá láti inú onírúurú ẹ̀sìn tó yàtọ̀ síra nìkan ni? Ṣé ó bá àwọn èèyàn lọ́wọ́ sí ìjọsìn míì tí wọ́n ń ṣe?
Àwọn Farisí àtàwọn Sadusí tí wọ́n jẹ́ àwọn aṣáájú ìsìn ta ko Jésù lọ́nà rírorò, kódà, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù. Àmọ́, kí ni Jésù ṣe? Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́ wọn. Afọ́jú afinimọ̀nà ni wọ́n.” (Mátíù 15:14) Jésù kò fara mọ́ irú àmúlùmálà ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, kò sì fẹ́ bá wọn da nǹkan kan pọ̀.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà náà tí ìjọ Kristẹni fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrú ní ìlú Kọ́ríńtì àti ní ilẹ̀ Gíríìsì láyé ìgbà yẹn. Àárín àwọn èèyàn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra ni àwọn Kristẹni wọ̀nyí sì ń gbé. Kí ni àwọn Kristẹni yẹn máa ṣe ní irú àgbègbè yìí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe, ó ní: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” Kí ló fà á tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ṣàlàyé síwájú sí i, ó ní: ‘Ìbáramu wo ni ó wà láàárín Kristi àti Bélíálì [Sátánì]? Tàbí ìpín wo ni olùṣòtítọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?’ Ó wá gbà wọ́n ní ìmọ̀ràn pé: “Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀.’—2 Kọ́ríńtì 6:14, 15, 17.
Ó ṣe kedere pé, Bíbélì kò fara mọ́ kí àwọn ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa jọ́sìn pa pọ̀. O wá lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ni yóò mú ká wà ní ìṣọ̀kan?’
BÍ A ṢE LÈ WÀ NÍ ÌṢỌ̀KAN
Àgbàyanu ẹ̀rọ kan wà tó máa ń yí òbìrí ayé po tí wọ́n ń pè ní International Space Station. Ó kéré tán, orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ló fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣe ẹ̀rọ yìí. Ǹjẹ́ o rò pé àkànṣe iṣẹ́ yìí á ṣeé ṣe, ká ní àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí kò fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kí wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan lórí bí ẹ̀rọ yìí ṣe gbọ́dọ̀ rí?
Bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń ṣe agbátẹrù àmúlùmálà ìgbàgbọ́ lónìí náà rí nìyẹn, àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọ́n sọ pé àwọn bọ̀wọ̀ fún ara àwọn, àwọn sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, síbẹ̀, èrò wọn ò ṣọ̀kan nípa àwọn ìlànà tó dá lórí bí èèyàn ṣe lè ní ìgbàgbọ́. Abájọ tí ọ̀ràn ẹ̀sìn àti ìwà rere fi di ọ̀ràn èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́.
Àwọn ìlànà Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì, wọ́n sì jẹ́ ìtọ́ni fún wa. Ńṣe ló yẹ ká máa lo ìgbésí ayé wa lọ́nà tí Bíbélì là sílẹ̀. Àwọn tó ń fi àwọn ìlànà inú rẹ̀ sílò ti borí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ẹ̀tanú ìsìn, wọ́n sì ti kọ́ bí èèyàn ṣe lè máa ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti àlàáfíà. Ọlọ́run ti sọ èyí tẹ́lẹ̀, nígbà tó sọ pé: “Èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” Tí àwọn èèyàn bá ń sọ “èdè mímọ́ gaara,” ìyẹn ni pé, tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn ìjọsìn nìkan ló lè mú kí aráyé wà ní ìṣọ̀kan.—Sefanáyà 3:9; Aísáyà 2:2-4.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ pè ẹ́ wá sí ilé ìjọsìn wa tó wà ní àdúgbò rẹ, a fẹ́ kí ìwọ náà gbádùn irú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tí kò lẹ́gbẹ́ tó wà láàárín wa.—Sáàmù 133:1.