Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo La Ṣe Lè Rí Ọlọ́run?

Báwo La Ṣe Lè Rí Ọlọ́run?

“ỌLỌ́RUN jẹ́ Ẹ̀mí,” torí náà, a kò lè fojú rí i. (Jòhánù 4:24) Síbẹ̀, Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn tó ti rí Ọlọ́run lọ́nà kan. (Hébérù 11:27) Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà rí i? Báwo làwa náà ṣe lè rí ‘Ọlọ́run tí kò ṣeé fojú rí’?—Kólósè 1:15.

Ọ̀rọ̀ náà dà bí ti ẹni tí kò ríran látìgbà tí wọ́n ti bí i. Torí pé ẹni kan ò ríran kò tún mọ̀ sí pé kò lè mọ ohun tó ń lọ láyìíká rẹ̀. Onírúurú ọ̀nà ni àwọn afọ́jú gbà ń rí ìsọfúnni tó ń jẹ́ kí wọ́n lè mọ àwọn èèyàn tàbí nǹkan tó wà nítòsí wọn tàbí ohun táwọn èèyàn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn ń ṣe. Ọkùnrin afọ́jú kan sọ pé: “Ojú nìkan kọ́ lèèyàn fi ń ríran, èèyàn tún lè fọkàn yàwòrán ohun tó ń lọ láyìíká.”

Lọ́nà kan náà, bí a ò tiẹ̀ lè fi ojú wa rí Ọlọ́run, a ṣì lè rí i tá a bá lo “ojú ọkàn-àyà” wa. (Éfésù 1:18) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

“A RÍ NÍ KEDERE LÁTI ÌGBÀ ÌṢẸ̀DÁ AYÉ”

Àwọn tó fọ́jú sábà máa ń tètè mọ̀ tí ẹnì kan bá fọwọ́ kàn wọ́n, etí wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ gan-an. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n fi ń mọ ohun tó ń lọ láyìíká wọn. Bákàn náà, àwa náà lè fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan mèremère tó wà láyìíká wa, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ fòye mọ Ọlọ́run tó ṣẹ̀dá wọn. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá.”—Róòmù 1:20.

Bí àpẹẹrẹ, ọ̀nà àrà tí Ọlọ́run gbà dá ilẹ̀ ayé wa fi hàn pé kò kàn fẹ́ ká wà láàyè lásán, àmọ́ ó tún fẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń gbádùn afẹ́fẹ́ tó tutù minimini, oòrùn tó rora mú fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, èso tó dùn mọ̀ràn-ìn-mọran-in tàbí orin atunilára táwọn ẹyẹ ń kọ. Ká sòótọ́, àwọn nǹkan wọ̀nyí fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wá jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti ọ̀làwọ́, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

Kí la lè rí kọ́ nípa Ọlọ́run tá a bá kíyè sí àwọn ohun tó dá? Ohun kan ni pé ìsálú ọ̀run ń fi agbára ńlá Ọlọ́run hàn. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tiẹ̀ sọ pé ńṣe ni àgbáálá ayé wa ń fẹ̀ sí i lọ́nà tó túbọ̀ ń yára kánkán! Tá a bá gbójú sókè wo ọ̀run tó lọ salalu lọ́wọ́ alẹ́, ó máa ń ṣe wá ní kàyéfì pé: ‘Ta lẹni tó ń mú kí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀?’ Bíbélì ṣàlàyé pé Ẹlẹ́dàá wa ní ‘ọ̀pọ̀ yanturu okun alágbára gíga.’ (Aísáyà 40:26) Àwọn ohun tí Ọlọ́run dá fi hàn pé òun ni “Olódùmarè,” àti pé “Ó ga ní agbára.”—Jóòbù 37:23.

“ẸNI TÍ Ó TI ṢÀLÀYÉ RẸ̀”

Obìnrin kan tí àwọn ọmọ rẹ̀ méjì jẹ́ afọ́jú sọ pé: “Tó o bá fẹ́ kí wọ́n tètè kẹ́kọ̀ọ́, ohun pàtàkì tí o máa ṣe ni pé kí o máa bá wọn sọ̀rọ̀ dáádáá. O gbọ́dọ̀ ṣe tán láti máa sọ gbogbo nǹkan tó o bá rí tàbí tó o gbọ́ nígbà tí ẹ bá jọ jáde, fún wọn torí pé ìwọ ni ojú fún wọn.” Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn ti wa rí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí,” Jésù Ọmọ rẹ̀, “tí ó wà ní ipò oókan àyà lọ́dọ̀ Baba ni ẹni tí ó ti ṣàlàyé rẹ̀.” (Jòhánù 1:18) Jésù ló dàbí “ojú” tí àwa náà lè fi rí Ọlọ́run, torí pé òun ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run àti ẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá. Abájọ tó fi jẹ́ pé òun nìkan ló lè fun wa ní kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni nípa Ọlọ́run tí a kò lè rí.

Jésù tó ti lo ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún pẹ̀lú Baba rẹ̀ sọ díẹ̀ fún wa nípa Ọlọ́run, lára ohun tó sọ ní pé:

  • Ọlọ́run jẹ́ òṣìṣẹ́ kára. “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí.”—Jòhánù 5:17.

  • Ọlọ́run mọ ohun tí a nílò. “Baba yín mọ àwọn  ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.”—Mátíù 6:8.

  • Ọlọ́run ń fìfẹ́ pèsè ohun tí a nílò. “Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run . . . ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.”—Mátíù 5:45.

  • Ọlọ́run mọyì wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”—Matthew 10:29-31.

ẸNI TÓ JẸ́ KÁ MỌ ỌLỌ́RUN

Bí àwọn afọ́jú ṣe máa ń mọ ohun tó wà láyìíká wọn yàtọ̀ sí tàwọn tó ń ríran. Lọ́dọ̀ àwọn afọ́jú, òjìji kì í ṣe ibi tó kàn ṣókùnkùn, ó wulẹ̀ jẹ́ ibi kan tó tutù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tí oòrùn kò sì dé. Bó ṣe jẹ́ pé ẹni tó fọ́jú kò dá ìmọ́lẹ̀ mọ̀ yàtọ̀ sí òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ náà ni a kò lè fi òye wa mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ká bàa lè mọ irú ẹni tó jẹ́, Jèhófà rán ẹnì kan wá sáyé tó gbé ìwà rẹ̀ yọ dáádáá.

Jésù ni ẹni tí Jèhófà rán wá. (Fílípì 2:7) Kì í ṣe pé Jésù kàn sọ̀rọ̀ nípa Baba rẹ̀ nìkan, àmọ́ ó tún fi irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ hàn wá. Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí i pé: “Olúwa, fi Baba hàn wá.” Jésù sọ fún un pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:8, 9) Ẹ jẹ́ ká wo irú ẹni tí Jésù jẹ́, ká lè mọ irú ẹni tí Ọlọ́run náà jẹ́.

Jésù jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ tó ṣeé sún mọ́, kì í ṣe agbéraga. (Mátíù 11:28-30) Nítorí àwọn ìwà dáadáa tó ní yìí, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Jésù máa ń bá àwọn èèyàn kẹ́dùn nígbà ìṣòro, ó sì máa ń bá wọn yọ̀ lọ́jọ́ ayọ̀ wọn. (Lúùkù 10:17, 21; Jòhánù 11:32-35) Tí o bá ń ka Bíbélì tàbí tó ń gbọ́ ìtàn Jésù, ṣe bíi pé ó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kó o sì fọkàn yàwòrán bí ìtàn náà ṣe ń lọ. Tí o bá ń ronú jinlẹ̀ lórí bí Jésù ṣe hùwà sáwọn èèyàn, á jẹ́ kó o mọ àwọn ìwà àtàtà tí Baba rẹ̀ ní, ó sì dájú pé á wù ẹ́ kó o sún mọ́ Ọlọ́run.

ÀWỌN OHUN TÓ LÈ JẸ́ KÁ RÍ ỌLỌ́RUN

Òǹkọ̀wé kan sọ nípa bí àwọn afọ́jú ṣe máa ń lóye ohun tó wà láyìíká wọn, ó ní: “Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n máa ń gbà rí ìsọfúnni, bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń gbóòórùn, wọ́n sì máa ń kíyè sí ohun tí wọ́n ń gbọ́ tàbí fọwọ́ kàn. Lẹ́yìn náà ni wọ́n á kó gbogbo ìsọfúnni yẹn jọ kí wọ́n lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wọn.” Lọ́nà kan náà, tó o bá kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, tó o ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù sọ nípa Baba rẹ̀, tó o sì tún fọkàn yàwòrán bí Jésù ṣe gbé ìwà Ọlọ́run yọ, ó dájú pé wàá rí Ọlọ́run, wàá sì mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Èyí á mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

Ohun tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jóòbù ṣe láyé àtijọ́ nìyẹn. Nígbà tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, òun fúnra rẹ̀ jẹ́wọ́ pé: “Èmi kò lóye.” (Jóòbù 42:3) Àmọ́, lẹ́yìn tó kíyè sí àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ọlọ́run dá, Jóòbù sọ pé: “Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ, Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ojú mi ti rí ọ.”—Jóòbù 42:5.

‘Bí ìwọ bá wá Jèhófà, yóò jẹ́ kí o rí òun’

Ìwọ náà lè fi ìdánilójú sọ irú ọ̀rọ̀ yìí. Bíbélì sọ pé: “Bí ìwọ bá wá [Jèhófà], yóò jẹ́ kí o rí òun.” (1 Kíróníkà 28:9) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti wá Ọlọ́run, kí ìwọ náà sì rí i.