Ohun Siseyebiye Ti Won Ri Ninu Pantiri
KÍ LÓ máa wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà pàǹtírí? Ó ṣeé ṣe kó o máa ronú nípa òórùn burúkú àti ìdọ̀tí tí wọ́n tò jọ pelemọ. Bóyá ni wà á rí nǹkan tó wúlò níbẹ̀, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ nǹkan tó níye lórí.
Ṣùgbọ́n, ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, wọ́n rí ìṣura kan tó ṣeyebíye nínú pàǹtírí. Ohun tí wọ́n rí kì í ṣe ohun ọ̀ṣọ́ olówó gọbọi, àmọ́ ó jẹ́ ìṣura tó níye lórí gan-an. Irú ìṣura wo ni wọ́n rí? Báwo ló sì ṣe wúlò fún wa lónìí?
ÌṢURA TÍ WỌ́N ṢÈÈṢÌ RÍ
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ogún, àwọn ọ̀mọ̀wé méjì láti Yunifásítì Oxford ìyẹn Bernard P. Grenfell àti Arthur S. Hunt, lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì. Wọ́n sì ṣàwárí àwọn àjákù òrépèté nínú pàǹtírí tó wà létí Àfonífojì Náílì. Lọ́dún 1920, nígbà táwọn méjèèjì ń ṣe àkójọ àwọn òrépèté yìí, Grenfell rí àwọn àjákù òrépèté míì nílẹ̀ Íjíbítì. Ibi Ìkówèésí John Rylands nílùú Manchester, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fẹ́ kó àkójọ àwọn òrépèté náà lọ. Àmọ́, àwọn méjèèjì kú kí wọ́n tó parí àkójọ náà.
Ọ̀mọ̀wé míì láti Yunifásítì Oxford tó ń jẹ́ Colin H. Roberts ló parí àkójọ yìí. Nígbà tó ń to àwọn àjákù òrépèté náà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ó rí àjákù òrépèté kékeré kan tí kò ju sẹ̀ǹtímítà mẹ́sàn-án níbùú àti sẹ̀ǹtímítà mẹ́fà [9 x 6 cm] lóròó. Nígbà tó wò ó dáadáa, ó yà á lẹ́nu láti rí i pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀ tí wọ́n kọ ní ọ̀nà ìkọ̀wé àwọn ará Gíríìkì kò ṣàjèjì sí òun rárá. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fàyọ látinú ìwé Jòhánù 18:31-33 ló wà ní ojú òrépèté náà. Apá kan lára ẹsẹ 37 àti 38 ló sì wà ní ẹ̀yìn rẹ̀. Roberts wá rí i pé ìṣura tí kò ṣe é fowó rà lòun mú lọ́wọ́.
ÌGBÀ TÍ WỌ́N KỌ Ọ́
Roberts kíyè sí i pé àjákù òrépèté náà ti gbó gan-an. Ṣùgbọ́n, ìgbà wo ni wọ́n kọ ọ́? Roberts lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ paleography kó lè mọ ìgbà tí wọ́n kọ ọ́. * Ó fi ọ̀nà ìkọ̀wé inú òrépèté náà wé ti àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tí ọjọ́ wọn ti pẹ́. Lọ́nà yìí, ó fojú bu ìgbà tí wọ́n kọ ọ́. Àmọ́, kó lè dá a lójú, ó ya fọ́tò àwọn àjákù òrépèté náà, ó sì fi ránṣẹ́ sáwọn mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa òrépèté, ó ní kí wọ́n wádìí ìgbà tí wọ́n kọ ọ́. Ibo làwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yìí parí èrò sí?
Nígbà tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n mẹ́ta yìí ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ìwé náà, gbogbo wọn fohùn ṣọ̀kan pé nǹkan bí ọdún 125 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ ọ́, ìyẹn nǹkan bí ẹ̀wádún díẹ̀ lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù kú! Àmọ́ ṣá o, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Paleography kì í ṣe ọ̀nà tó péye jù lọ láti mọ bí ìwé àfọwọ́kọ kan ṣe pẹ́ tó. Ọ̀mọ̀wé kan tiẹ̀ sọ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n kọ ìwé náà ní àkókò èyíkéyìí láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kejì. Síbẹ̀, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àjákù òrépèté kékeré yìí ṣì ni ìwé àfọwọ́kọ tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ tí wọ́n tíì rí lára Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.
OHUN TÍ ÀJÁKÙ ÒRÉPÈTÉ RYLANDS JẸ́ KÁ MỌ̀
Kí nìdí tí àjákù ìwé Ìhìn Rere Jòhánù yìí fi ṣe pàtàkì sí àwọn tó fẹ́ràn Bíbélì lóde òní? Ó kéré tán fún ìdí méjì yìí. Àkọ́kọ́, ìwé tí wọ́n lò jẹ́ ká mọ ọwọ́ tí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi mú Ìwé Mímọ́.
Kí nìdí tí àjákù ìwé Ìhìn Rere Jòhánù yìí fi ṣe pàtàkì sí àwọn tó fẹ́ràn Bíbélì lóde òní?
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni, oríṣi ìwé méjì ni wọ́n máa ń kọ̀wé sí, ìyẹn àkájọ ìwé àti ìwé alábala. Òrépèté tàbí awọ ni wọ́n fi ń ṣe àkájọ ìwé, wọ́n á lẹ̀ ẹ́ pọ̀ tàbí kí wọ́n rán an pọ̀ di ìwé gígùn kan. Wọ́n lè ká a jọ tàbí kí wọ́n tú u nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ojú kan ni wọ́n máa ń kọ̀wé sí nínú àkájọ ìwé.
Àmọ́ tojú-tẹ̀yìn ni wọ́n kọ̀wé sí lára àjákù òrépèté tí Roberts rí. Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ara ìwé alábala ni àjákù yẹn ti já kì í ṣe inú àkájọ ìwé. Òrépèté tàbí awọ tí wọ́n rán pọ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan ló máa ń di ìwé alábala.
Kí ló mú kí ìwé alábala dáa ju àkájọ ìwé? Ohun kan ni pé ajíhìnrere làwọn Kristẹni ìjímìjí. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Wọ́n sì máa ń sọ Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì fún àwọn èèyàn níbikíbi tí wọ́n bá ti rí wọn, ì báà jẹ́ ní ilé, ọjà tàbí lójú pópó. (Ìṣe 5:42; 17:17; 20:20) Torí náà, iṣẹ́ yìí á rọ̀ wọ́n lọ́rùn tí wọ́n bá ní Ìwé Mímọ́ tó rọrùn láti gbé kiri.
Ìwé alábala tún mú kó rọrùn fún àwọn ìjọ àti ẹnì kọ̀ọ̀kan láti ṣe àdàkọ ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ tiwọn. Fún ìdí yìí, léraléra ni wọ́n máa ń ṣe àdàkọ àwọn ìwé Ìhìn Rere, èyí sì wà lára ohun tó mú kí ẹ̀sìn Kristẹni túbọ̀ gbilẹ̀ sí i.
Ìkejì, àjákù òrépèté Rylands yìí ṣe pàtàkì sí wa lóde òní torí pé ó jẹ́ ká rí i pé gẹ́lẹ́ bí Bíbélì ṣe wà nígbà tí wọ́n kọ ọ́ náà ló ṣì ṣe wà lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ mélòó kan nínú ìwé Ìhìn Rere Jòhánù ló wà nínú àjákù yẹn, ohun tó wà nínú rẹ̀ àti ohun tó wà nínú Bíbélì tó wà báyìí fẹ́rẹ̀ẹ́ bára dọ́gba tán. Torí náà, àjákù òrépèté Rylands yìí fi hàn pé wọn ò yí ohun tó wà nínú Bíbélì pa dà láìka bí wọ́n ṣe ṣàdàkọ rẹ̀ léraléra.
Ká sòótọ́, ńṣe ni àjákù òrépèté Rylands tí wọ́n kọ Ìhìn Rere Jòhánù sí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àjákù àti ìwé àfọwọ́kọ tó jẹ́rìí sí i pé bí Bíbélì ṣe wà nígbà tí wọ́n kọ ọ́ náà ló ṣe wà títí dòní. Nínú ìwé tí Werner KellerIn ṣe, ìyẹn The Bible as History, ó sọ pé: “Àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣe é já ní koro pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì tá à ń lò lóde òní jẹ́ òótọ́, ó sì ṣe é gbara lé.”
Lóòótọ́, àwa Kristẹni kò gbé ìgbàgbọ́ wa lórí ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí. Ohun tá a gbà gbọ́ ni pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Síbẹ̀, àwọn ìṣura yìí máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i torí pé ńṣe ni wọ́n ń kín ọ̀rọ̀ Bíbélì lẹ́yìn, èyí tó sọ pé: “Àsọjáde Jèhófà wà títí láé”!—1 Pétérù 1:25.
^ ìpínrọ̀ 8 Ìwé náà Manuscripts of the Greek Bible, sọ pé, Palaeography “jẹ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa àwọn ìwé ayé àtijọ́.” Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ni ọ̀nà ìkọ̀wé máa ń yí pa dà. Àwọn àyípadà yìí máa ń jẹ́ kí wọ́n lè fojú bu ìgbà tí wọ́n kọ ìwé kan tí wọ́n bá fi wé àwọn ìwé míì tí wọ́n kọ láàárín àkókò kan náà.