Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ TI RỌ́PÒ BÍBÉLÌ?

Àǹfààní Tí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ń Ṣe fún Wa

Àǹfààní Tí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ń Ṣe fún Wa

Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó wà lórí ilẹ̀ ayé bí ewéko, ẹranko àtàwọn nǹkan míì. Wọ́n tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó wà lójú sánmà bí oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń ṣe ìwádìí taápọntaápọn nípa kíkíyèsí bí àwọn nǹkan yìí ṣe ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni iṣẹ́ yìí. Wọ́n lè wà nídìí iṣẹ́ kan fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí ọ̀pọ̀ oṣù, kódà wọ́n lè lo ọ̀pọ̀ ọdún nídìí rẹ̀ pàápàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà míì wà tí ìsapá wọn máa ń já sí pàbó, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ìsapá wọn máa ń ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní. Wo àwọn àpẹẹrẹ kan.

Ilé iṣẹ́ kan ní ilẹ̀ Yúróòpù fi ike tó nípọn àti àwọn asẹ́ ìgbàlódé ṣe ẹ̀rọ kan. Ẹ̀rọ yìí máa ń sẹ́ omi ìdọ̀tí, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti mu omi náà láìkó àrùn. Wọ́n máa ń lo ẹ̀rọ yìí ní àwọn àgbègbè tí ìjábá bá ti ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lò ó nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé lórílẹ̀-èdè Haiti lọ́dún 2010.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tún gbé àwọn ẹ̀rọ sátẹ́láìtì tó so kọ́ra sí ojú sánmà. Àwọn ẹ̀rọ yìí máa ń jẹ́ kí èèyàn mọ ọ̀nà ibi tó ń lọ. Wọ́n ń pe ẹ̀rọ̀ náà ní Global Positioning System (GPS). Àwọn ológun ni wọ́n dìídì ṣe ẹ̀rọ yìí fún, àmọ́ ní báyìí, àwọn onímọ́tò, àwọn awakọ̀ òfúrufú, àwọn atukọ̀ òkun àti àwọn ọlọ́dẹ ti ń lo ẹ̀rọ yìí. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ṣe ẹ̀rọ yìí, ó ti jẹ́ kó rọrùn láti lọ sí ibikíbi láìbẹ̀rù pé èèyàn máa sọnù.

Ṣé o máa ń lo fóònù, kọ̀ǹpútà tàbí íńtánẹ́ẹ̀tì? Ṣé o ti lo àwọn oògùn ìgbàlódé tó mú kí ara rẹ túbọ̀ jí pépé? Ṣé o ti wọ ọkọ̀ òfúrufú rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ìwọ náà ń jèrè nínú àwọn ọ̀nà tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbà ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti gbà ṣe ẹ́ láǹfààní.

IBI TÍ ÒYE ÀWỌN ONÍMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ DÉ

Kí òye àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè pọ̀ sí i, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń walẹ̀ jìn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bí àwọn onímọ̀ nípa átọ́ọ̀mù ṣe ń tú tìfun-tẹ̀dọ̀ àwọn átọ́ọ̀mù tín-tìn-tín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn onímọ̀ nípa ojú sánmà ń ṣe ìwádìí nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún sẹ́yìn kí wọ́n lè mọ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run. Bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe túbọ̀ ń walẹ̀ jìn débí tí ojú ẹ̀dá èèyàn kò lè tó, àwọn kan nínú wọn ronú pé tí Ọlọ́run tí Bíbélì pè ní Ẹlẹ́dàá bá wà, ó yẹ kí àwọn lè rí i.

Àwọn kan tó jẹ́ abẹnugan nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tún gbé ọwọ́ tó le jùyẹn lọ. Wọ́n ṣagbátẹrù ohun tí òǹṣèwé onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó ń jẹ Amir D. Aczel sọ pé, “ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fi hàn dájú pé kò sí Ọlọ́run.” Bí àpẹẹrẹ, onímọ̀ físíìsì kan tó gbajúmọ̀ kárí ayé sọ pé kò sí ẹ̀rí kankan tó ṣe gúnmọ́ tá a fi lè sọ pé Ọlọ́run wà. Fún ìdí yìí, ó hàn gbangba pé kò sí Ọlọ́run rárá. Àwọn míì sọ pé pidánpidán kan lásán ni Ọlọ́run tí Bíbélì pè ní Ẹlẹ́dàá. *

Àmọ́, ìbéèrè kan ni pé: Ṣé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ gbogbo nǹkan tán nípa ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run, débi tí wọ́n fi ń fọwọ́ sọ̀yà pé kò sí Ọlọ́run? Rárá o. Ká sòótọ́, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti tẹ̀síwájú gan-an, àmọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ò tíì mọ̀, àwọn nǹkan míì sì wà tí àwọn ò lè mọ̀ láéláé. Ọ̀gbẹ́ni Steven Weinberg, tó jẹ́ onímọ̀ físíìsì, tó sì tún gba àmì ẹ̀yẹ Nobel sọ nípa ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run pé: “A ò lè rídìí gbogbo nǹkan láé.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Martin Rees tó jẹ́ ọ̀gá àwọn onímọ̀ nípa ojú sánmà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àìmọye nǹkan ló wà tí àwa èèyàn kò lè lóye láé.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì wà tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò tíì mọ̀ rárá, látorí sẹ́ẹ̀lì bíńtín dé orí àwọn nǹkan àgbàyanu tó wà lójú sánmà. Díẹ̀ lára wọn rèé:

  • Nǹkan díẹ̀ ni àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè ṣì mọ̀ nípa bí àwọn sẹ́ẹ̀lì tín-tìn-tín inú ara ṣe ń ṣiṣẹ́. Wọn ò tíì lóye bí àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ṣe ń gba agbára, bí wọ́n ṣe ń pèsè èròjà aṣaralóore tí ara nílò àti bí wọ́n ṣe ń pín ara wọn.

  • Agbára òòfà ló máa ń jẹ́ kí ohun tá a sọ sókè pa dà wá sílẹ̀. Síbẹ̀ ó ṣì ń ṣe àwọn onímọ̀ físíìsì ní kàyéfì. Títí di báyìí, wọn ò tíì lóye bí agbára yìí ṣe ń mú kí èèyàn wálẹ̀ nígbà tó bá fò sókè àti bó ṣe ń mú kí òṣùpá máa yí ayé po.

  • Àwọn onímọ̀ nípa ohun tó wà lójú ọ̀run fojú bù ú pé ohun tó ju ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn nǹkan tó wà ní ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run ni kò ṣe é rí. Kò tiẹ̀ sí ẹ̀rọ kankan tí wọ́n lè fi ṣe ìwádìí nípa wọn. Ohun tí àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ kò tíì yé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.

Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan míì ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tíì mọ̀ tó sì máa ń ṣe wọ́n ní kàyéfì. Kí nìdí táwọn nǹkan yìí fi ṣe pàtàkì? Òǹkọ̀wé onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó gbajúmọ̀ sọ pé: “Ohun tá a mọ̀ kò tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tá ò tíì mọ̀. Ní tèmi o, ńṣe lohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rí yẹ kó wúni lórí, kó sì mú kéèyàn fẹ́ mọ ohun púpọ̀ sí i, dípò tí èèyàn á fi máa ṣe lámèyítọ́.”

Tó bá ń ṣe ẹ́ bí i pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì máa tó rọ́pò Bíbélì, tí kò sì ní jẹ́ káwọn èèyàn gba Ọlọ́run gbọ́ mọ́, á dáa kó o ronú nípa kókó yìí: Ìmọ̀ díẹ̀ ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣì ní nípa ayé àti ìsálú ọ̀run láìka àwọn ẹ̀rọ ńláńlá tí wọ́n fi ń ṣe ìwádìí sí. Tó fi hàn pé àwọn nǹkan kan ṣì wà tí wọn ò tíì mọ̀, ṣe a wá lè sọ pé àwọn nǹkan tí wọn ò mọ̀ yẹn kò ṣe pàtàkì ni? Kókó yìí ni ìwé Encyclopedia Britannica fi parí àpilẹ̀kọ kan tó dá lórí ìtàn àti ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ àwọn onímọ̀ nípa sánmà, ó ní: “Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún táwọn èèyàn ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa sánmà, wọ́n ò tíì lè ṣàlàyé gbogbo ohun tó wà ní ìsálú ọ̀run bí àwọn ará Bábílónì ìgbàanì kò ṣe lè ṣàlàyé rẹ̀.”

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé kálukú ló ní ẹ̀tọ́ láti yan ohun tó máa gbà gbọ́ lórí kókó yìí. A máa ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣàyẹ̀wò bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe bá Bíbélì mu.

^ ìpínrọ̀ 9 Àwọn kan ò gba Bíbélì gbọ́ torí pé wọn kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi kọ́ni láyé àtijọ́ àti èyí tí wọ́n fi ń kọ́ni lóde òní. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ni pé ńṣe ni oòrùn, òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ń yí ayé po. Wọn ò tún fara mọ́ ẹ̀kọ́ náà pé ọjọ́ mẹ́fà tó jẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélógún péré ni Ọlọ́run fi dá ayé.—Wo àpótí náà “ Bí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ṣe Bá Bíbélì Mu.”