Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Bedell—Bíbélì Tó Mú Káwọn Èèyàn Túbọ̀ Lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Bíbélì Bedell—Bíbélì Tó Mú Káwọn Èèyàn Túbọ̀ Lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

NÍGBÀ tí àlùfáà ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ William Bedell lọ sí orílẹ̀-èdè Ireland lọ́dún 1627, ohun tó rí níbẹ̀ jọ ọ́ lọ́jú. Àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ló pọ̀ jù ní ilẹ̀ Ireland, síbẹ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ló ń ṣàkóso wọn. Àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ayé ọjọ́un ti sapá gan-an láti túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè ìbílẹ̀ tó wà ní Yúróòpù. Àmọ́ kò sẹ́ni tó yà sí títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Irish.

Bedell gbà pé ‘ó yẹ kí àwọn tó ń sọ èdè Irish ní Bíbélì lédè tiwọn.’ Torí náà, ó pinnu láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Irish. Ṣùgbọ́n, ńṣe ni àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ta ko ohun tó fẹ́ ṣe. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀?

WỌ́N TA KO LÍLO ÈDÈ IRISH

Bedell pinnu láti kọ́ èdè Irish. Kódà, nígbà tó di ọ̀gá iléèwé gíga Trinity College nílùú Dublin, ńṣe ló máa ń rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti máa lo èdè Irish. Ohun kan náà ló ṣe nígbà tó di bíṣọ́ọ̀bù agbègbè Kilmore. Ohun tó gbàfiyèsí ni pé Ọbabìnrin Elizabeth kìíní ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni olùdásílẹ̀ iléèwé gíga Trinity College, ìdí tó sì fi dá a sílẹ̀ ni pé kó lè dá àwọn pásítọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni èdè ìbílẹ̀ wọn. Ohun tí Bedell ṣe gan-an nìyẹn.

Èdè Irish ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wà lágbègbè Kilmore ń sọ. Torí náà, àwọn pásítọ̀ tó gbọ́ èdè Irish dáadáa ni Bedell gbà sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ohun tí Bedell fẹ́ ṣe bá ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ mu nínú 1 Kọ́ríńtì 14:19, tó ní: “Nínú ìjọ, èmi yóò kúkú fi èrò inú mi sọ̀rọ̀ márùn-ún, kí n lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu fún àwọn ẹlòmíràn ní ìtọ́ni, ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì,” ìyẹn èdè tí kò yé ọ̀pọ̀ èèyàn.

Àmọ́, àwọn èèyàn ńláńlá àtàwọn tó lẹ́nu nílùú ta ko ohun tí Bedell fẹ́ ṣe. Àwọn òpìtàn sọ pé, ńṣe láwọn wọ̀nyí gbà pé táwọn èèyàn bá ń sọ èdè Irish dáadáa, ìyẹn máa “ṣàkóbá fún Ìjọba” àti pé kò ní jẹ́ kí “Ìjọba lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.” Wọ́n ní tí àwọn tó ń sọ èdè Irish bá kàwé, kò ní jẹ́ kí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lè máa darí wọn mọ́. Kódà wọ́n ṣe òfin kan tó kàn án nípá fún àwọn tó ń sọ èdè Irish láti pa èdè àti àṣà wọn tì, kí wọ́n sì kọ́ èdè àti àṣà Gẹ̀ẹ́sì.

IṢẸ́ ÌTÚMỌ̀ BÍBÉLÌ TÍ BEDELL ṢE

Bedell kò jẹ́ kí gbogbo ìyẹn dí òun lọ́wọ́. Láàárín ọdún 1630 sí 1633, ó bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n tẹ̀ jáde nígbà yẹn (ìyẹn Bíbélì King James Version ti ọdún 1611) sí èdè Irish. Ìdí ni pé ó fẹ́ túmọ̀ Bíbélì tó máa rọrùn fún àwọn tó ń sọ èdè Irish láti lóye. Torí pé àwọn tálákà kò ní lè ka Ìwé Mímọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì débi tí wọ́n á fi lè mọ ohun tí wọ́n máa ṣe láti wà láàyè títí láé.Jòhánù 17:3.

Kì í ṣe Bedell ló kọ́kọ́ ní irú èrò yìí. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún ṣáájú àkókò yìí, bíṣọ́ọ̀bù kan tó ń jẹ́ William Daniel, rí i pé ó máa ṣòro fún àwọn èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, torí pé “èdè tí wọn kò gbọ́ ni wọ́n fi kọ ọ́.” Daniel ti kọ́kọ́ túmọ̀ ìwé Mátíù títí dé ìwé Ìṣípayá [Ìfihàn] ní èdè Irish. Bedell wá bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì sí ìwé Málákì. Bíbélì tá a wá mọ̀ sí Bíbélì Bedell jẹ́ àpapọ̀ ìtumọ̀ tí William Daniel kọ́kọ́ ṣe àti èyí tí Bedell fúnra rẹ̀ ṣe. Ó wá di pé Bíbélì Bedell ni odindi Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ ní èdè Irish. Òun sì ni ìtumọ̀ Bíbélì kan ṣoṣo tó wà ní èdè Irish fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún.

Bedell fúnra rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú èdè Hébérù. Ó wá gba àwọn ọkùnrin méjì tó gbọ́ èdè Irish dáadáa kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́ láti túmọ̀ Bíbélì lédè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Irish. Bí wọ́n ṣe ń bá iṣẹ́ ìtumọ̀ náà lọ, Bedell àti àwọn méjì míì tó fọkàn tán máa ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lè rí i pé kò sí àṣìṣe kankan nínú rẹ̀. Kí iṣẹ́ náà lè jẹ́ ojúlówó, wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì, bíi Bíbélì èdè Italian tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tó ń jẹ́ Giovanni Diodati túmọ̀ àti Greek Septuagint, àti Bíbélì èdè Hébérù àtijọ́.

Àpẹẹrẹ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì King James Version ni Bedell àtàwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ tẹ̀ lé. (Ó ṣeé ṣe kí Bedell mọ ọ̀pọ̀ lára wọn) Torí náà, wọ́n fi orúkọ Ọlọ́run sí àwọn ibi mélòó kan nínú ìtumọ̀ Bíbélì Bedell. Bí àpẹẹrẹ, ní Ẹ́kísódù 6:3, wọ́n túmọ̀ orúkọ Ọlọ́run sí “Iehovah.” Ibi ìkówèésí tí wọ́n ń pè ní Marsh’s Library, ní ìlú Dublin, lórílẹ̀-èdè Ireland ni wọ́n tọ́jú Bíbélì tí Bedell fọwọ́ kọ náà sí.—Wo àpótí náà “Ní Ìrántí Bedell.”

WỌ́N TẸ̀ Ẹ́ JÁDE NÍGBẸ̀YÌN-GBẸ́YÍN

Ọdún 1640 ni Bedell parí iṣẹ́ ìtumọ̀ náà. Àmọ́ kò lè tẹ̀ ẹ́ jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ṣì ń dojú kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtakò. Àwọn alátakò yìí sapá kí wọ́n lè ba òléwájú lára àwọn tó bá Bedell ṣiṣẹ́ lórúkọ jẹ́, kí àwọn èèyàn le gbà pé Bíbélì náà kò wúlò. Níbi tó le dé, wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. Kò tán síbẹ̀ o, lọ́dún 1641, àwọn jàǹdùkú tó ń bá àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jà bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà láti mú Bedell. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ireland fi Bedell pa mọ́, torí wọ́n mọ̀ pé tiwọn náà ló ń ṣe. Ṣùgbọ́n, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ọwọ́ àwọn jàǹdùkú náà tẹ Bedell, wọ́n fi sí àtìmọ́lé níbi tí nǹkan ò ti rọgbọ. Ipò tó wà yìí ló jẹ́ kó tètè kú lọ́dún 1642. Èyí ni kó jẹ́ kí wọ́n tẹ Bíbélì náà jáde lójú rẹ̀.

Ojú ìwé tí wọ́n kọ àkọlé sí nínú àfọwọ́kọ tí Bedell ṣe, ṣáájú ọdún 1640, àti Bíbélì tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1685

Díẹ̀ ló kù kí gbogbo làálàá Bedell já sí asán nígbà tí wọ́n wá tú ilé rẹ̀ ká, tí wọ́n sì da gbogbo ẹrù rẹ̀ nù. Ọpẹ́lọpẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó kó àwọn ìwé tí wọ́n fi túmọ̀ pa mọ́. Nígbà tó yá, àwọn ìwé náà dé ọwọ́ Narcissus Marsh, tó wá di bíṣọ́ọ̀bù àgbà ní Armagh, tó sì tún di bíṣọ́ọ̀bù àgbà fún Ṣọ́ọ̀ṣì Ireland. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó ń jẹ́ Robert Boyle, ló fún Narcissus Marsh lówó tí wọ́n fi tẹ Bíbélì Bedell jáde lọ́dún 1685. Marsh ní láti lo ìgboyà kó tó lè ṣe iṣẹ́ yìí.

ÌGBÉSẸ̀ PÀTÀKÌ KAN TÓ MÚ KÁWỌN ÈÈYÀN LÓYE BÍBÉLÌ

Kì í ṣe ibi gbogbo ni wọ́n ti mọyì Bíbélì Bedell yìí. Síbẹ̀ ìgbésẹ̀ pàtàkì yìí mú káwọn èèyàn túbọ̀ lóye Bíbélì, pàápàá àwọn tó ń sọ èdè Irish ní orílẹ̀-èdè Ireland àti Scotland àti láwọn ibòmíì. Ó mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti sún mọ́ Ọlọ́run torí pé wọ́n rí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà ní èdè wọn.Mátíù 5:3, 6.

“Bí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń ka Bíbélì Bedell ti mú kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run, kódà títí di báyìí. Ọ̀kan lára àwọn tó ń sọ èdè Irish tó kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì kọ́ni lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé: “Ńṣe ni Bíbélì Bedell máa ń mú ká gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè tó yé wa. Èyí ni ohun pàtàkì tó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún èmi àti ìdílé mi láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́.”

Bí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń ka Bíbélì Bedell ti mú kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run, kódà títí di báyìí. Ọ̀kan lára àwọn tó ń sọ èdè Irish tó kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì kọ́ni lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé: “Ńṣe ni Bíbélì Bedell máa ń mú ká gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè tó yé wa. Èyí ni ohun pàtàkì tó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún èmi àti ìdílé mi láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́.”