Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ìwà Àgàbàgebè Lè Dópin?

Ṣé Ìwà Àgàbàgebè Lè Dópin?

ERÉKÙṢÙ kan ní Mẹditaréníà ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Panayiota dàgbà sí. Àtìgbà tó ti wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ òṣèlú. Nígbà tó yá, ó ṣiṣẹ́ akọ̀wé fún ẹgbẹ́ òṣèlú kan ní abúlé tó ń gbé. Ó tiẹ̀ tún máa ń lọ láti ilé kan sí òmíràn kó lè kówó jọ fún ẹgbẹ́ náà. Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ òṣèlú yọ lẹ́mìí rẹ̀ pátápátá. Ìdí ni pé láìka bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣe ń pe ara wọn ní ọmọ ìyá, oríṣiríṣi ìwà àbòsí ló kún ọwọ́ wọn bíi kí wọ́n máa jowú ara wọn, kí wọ́n máa jin ara wọn lẹ́sẹ̀, kí kálukú sì máa wá àǹfààní tara ẹ̀.

Ilé tí wọ́n ti fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn ni wọ́n ti tọ́ Daniel dàgbà lórílẹ̀-èdè Ireland. Àmọ́, ó ṣì máa ń rántí ìwà àgàbàgebè àwọn àlùfáà ìjọ wọn. Ńṣe ni wọ́n máa ń mutí yó kẹ́ri, wọ́n máa ń ta tẹ́tẹ́, wọ́n sì máa ń jí owó ìjọ kó. Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n á máa wàásù fún un pé tó bá dẹ́ṣẹ̀, ó máa lọ jóná nínú ọ̀run àpáàdì.

Àwọn oníṣòwò ńlá kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà àti ní United Kingdom ni Jeffery ń bá ṣiṣẹ́. Ó sọ onírúurú ìwà màdàrú tàwọn agbaṣẹ́ṣe máa ń hù tí wọ́n bá ń dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Ẹ̀tàn kún ẹnu wọn, kò sì sí ohun tí wọn ò lè fi dánnu kí wọ́n ṣáà lè ríṣẹ́ gbà lọ́wọ́ ìjọba.

Ká sòótọ́, ìwà àgàbàgebè kún inú ayé. Kò síbi tá a yíjú sí tí a ò ní rí ìwà yìí, ì báà jẹ́ inú ìṣèlú, ẹ̀sìn tàbí lẹ́nu iṣẹ́ ajé. Ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tá a túmọ̀ sí àgàbàgebè wá láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó dúró fún àwọn eléré orí ìtàgé tó máa ń lo ìbòjú. Alágàbàgebè lẹni tó ń díbọ́n kó lè tan àwọn míì jẹ tàbí tó kàn ń ṣojú ayé lásán kó lè rí àǹfààní jẹ lára àwọn míì.

Inú máa ń bí wa tá a bá rí àwọn tó ń hùwà àgàbàgebè. Nígbà míì tára bá kan wá, a lè sọ pé, “Ṣé ìwà àgàbàgebè lè dópin?” A dúpẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé ó máa dópin.

OJÚ TÍ ỌLỌ́RUN ÀTI JÉSÙ FI Ń WO ÌWÀ ÀGÀBÀGEBÈ

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé áńgẹ́lì kan ló kọ́kọ́ hùwà àgàbàgebè, kì í ṣe àwa èèyàn. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá àwa èèyàn, Sátánì Èṣù gọ sẹ́yìn ejò kan láti tan Éfà jẹ. Ńṣe ló díbọ́n bíi pé afẹ́nifẹ́re ni, ṣùgbọ́n bó ṣe máa ṣi Éfà lọ́nà ló ń wá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Látìgbà yẹn wá ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń fara wé Sátánì ní ti pé, wọ́n máa ń díbọ́n kí wọ́n lè tan àwọn míì jẹ nítorí èrè àbòsí.

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn àfaraṣe-máfọkànsẹ, Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn pé ọ̀rọ̀ náà máa lẹ́yìn. Jèhófà Ọlọ́run wá gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ pé: “Àwọn ènìyàn yìí ti fi ẹnu wọn sún mọ́ mi, tí wọ́n sì ti fi kìkì ètè wọn yìn mí lógo, tí wọ́n sì ti mú ọkàn-àyà wọn pàápàá lọ jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ mi.” (Aísáyà 29:13) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ láti yí pa dà, Ọlọ́run gba àwọn orílẹ̀-èdè míì láyè láti pa ìlú wọn run. Àwọn ará Bábílónì ló kọ́kọ́ run Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tó di ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù wá pa á run pátápátá. Èyí fi hàn pé Ọlọ́run kì í fàyè gba ìwà àgàbàgebè lọ títí.

Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run àti Jésù Ọmọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ àti aláìlábòsí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nàtáníẹ́lì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gbàrà tí Jésù rí i, ó sọ pé: “Wò ó, ọmọ Ísírẹ́lì kan dájúdájú, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kankan kò sí.” (Jòhánù 1:47) Nàtáníẹ́lì tá a tún mọ̀ sí Batólómíù di ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá tí Jésù ní.Lúùkù 6:13-16.

Jésù lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sì kọ́ wọn ní èrò Ọlọ́run nípa ọ̀pọ̀ nǹkan. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ máa hùwà àgàbàgebè. Jésù wá bẹnu àtẹ́ lu àwọn ìwà àgàbàgebè táwọn aṣáájú ìsìn ń hù láti fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ìwà àwọn aṣáájú ìsìn yìí.

“Òdodo” ṣekárími ni wọ́n máa ń ṣe. Jésù sọ fún àwọn tó ń kọ́ pé: “Ẹ ṣọ́ra gidigidi láti má ṣe fi òdodo yín ṣe ìwà hù níwájú àwọn ènìyàn kí wọ́n bàa lè ṣàkíyèsí rẹ̀ . . . gẹ́gẹ́ bí àwọn alágàbàgebè ti ń ṣe.” Ó tún sọ fún wọn pé tí wọ́n bá fẹ́ fúnni ní ẹ̀bùn àánú, kí wọ́n ṣe é “ní ìkọ̀kọ̀.” Bí wọ́n bá sì fẹ́ gbàdúrà, kí wọ́n gbà á níkọ̀kọ̀ kì í ṣe káwọn míì lè rí wọn. Ìgbà yẹn gan-an ló jẹ́ pé wọ́n fòótọ́ ọkàn sin Ọlọ́run, irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọ́run máa ń tẹ́wọ́ gbà.Mátíù 6:1-6.

Wọ́n tètè máa ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn míì. Jésù sọ pé: “Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì ríran kedere ní ti bí o ṣe lè yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.” (Mátíù 7:5) Arítẹnimọ̀ọ́wí tó ń fi àpáàdì jànràn bo tiẹ̀ mọ́lẹ̀ ni àwọn aṣáájú ìsìn náà. Wọ́n á máa ṣe bí ẹni tí kò lábùkù. Àmọ́ Bíbélì sọ pé, “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.”Róòmù 3:23.

Ètekéte kún ọwọ́ wọn. Nígbà kan, àwọn ọmọlẹ́yìn àwọn Farisí àtàwọn ọmọlẹ́yìn àjọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù wá bi Jésù nípa owó orí. Wọ́n kọ́kọ́ pọ́n Jésù, wọ́n ní: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ jẹ́ olùsọ òtítọ́, o sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́.” Wọ́n wá dán an wò nípa bíbéèrè pé: “Ó ha bófin mu láti san owó orí fún Késárì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Jésù dáhùn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń dán mi wò, ẹ̀yin alágàbàgebè?” Alágàbàgebè tí Jésù pè wọ́n gẹ́lẹ́ ni wọ́n jẹ́ torí pé kì í ṣe ìdáhùn sí ìbéèrè náà ni wọ́n ń wá, àmọ́ ńṣe ni wọ́n fẹ́ “dẹ pańpẹ́ mú un nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.”Mátíù 22:15-22.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ní “ìfẹ́ láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ àti láti inú ẹ̀rí-ọkàn rere àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.”1 TÍMÓTÌ 1:5

Nígbà tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ ní ọdún Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni, òtítọ́ àti òdodo gbilẹ̀ láàárín wọn. Àwọn Kristẹni tòótọ́ yìí sapá gan-an kí wọ́n lè yẹra fún ìwà àgàbàgebè. Bí àpẹẹrẹ, Pétérù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa ṣègbọràn “sí òtítọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè.” (1 Pétérù 1:22) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gba àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n ní “ìfẹ́ láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ àti láti inú ẹ̀rí-ọkàn rere àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.”1 Tímótì 1:5.

AGBÁRA TÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN NÍ

Bí àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti tàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe lágbára láyé ìgbà yẹn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe lágbára lóde òní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá sọ lórí kókó yìí pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì ń pa ohun tó wà nínú rẹ̀ mọ́. Ẹ̀kọ́ yìí ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìwà àgàbàgebè, kí wọ́n sì máa sọ òtítọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn mẹ́ta tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.

“Mo rí i bí àwọn èèyàn ṣe nífẹ̀ẹ́ tòótọ́ sí ara wọn.”—PANAYIOTA

Nǹkan yí pa dà fún Panayiota nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ilé ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò rí i kí ẹnikẹ́ni máa ṣe òdodo ṣekárími torí àtigbayì lójú àwọn míì. Ó ní: “Mo rí i bí àwọn èèyàn ṣe nífẹ̀ẹ́ tòótọ́ sí ara wọn, ohun kan tí mi ò rí ní gbogbo ọdún tí mo fi ṣòṣèlú.”

Panayiota bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì títí tó fi ṣèrìbọmi. Ọ̀rọ̀ náà ti lé lọ́gbọ̀n ọdún báyìí. Ó wá sọ pé: “Ìgbésí ayé mi kò lójú nígbà tí mò ń káàkiri ojúlé sí ojúlé láti gbé ẹgbẹ́ òṣèlú lárugẹ. Àmọ́ ní báyìí, ìgbésí ayé mi nítumọ̀ bí mo ṣe ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba kan tí kò ní sí ìwà àgàbàgebè nínú rẹ̀.”

“Ọkàn mi ò gbà á láti máa ṣojú ayé nínú ìjọ.”—DANIEL

Daniel tẹ̀síwájú nínú ìjọ Kristẹni débi tó fi láǹfààní láti máa bójú tó àwọn iṣẹ́ kan nínú ìjọ. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ó ṣàṣìṣe, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sí bẹ̀rẹ̀ sí í dà á láàmù. Ó sọ pé: “Mo rántí bí ìwà àgàbàgebè ṣe kún inú ṣọ́ọ̀ṣì tí mò ń lọ tẹ́lẹ̀, fún ìdí yìí mo gbé àwọn iṣẹ́ tí mò ń bójú tó náà sílẹ̀. Ọkàn mi ò gbà á láti máa ṣojú ayé nínú ìjọ.”

Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ tí Daniel ti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ, ó rí i pé òun lè wá máa ṣe àwọn iṣẹ́ inú ìjọ láìjẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn ń da òun láàmù, ó sì gba àwọn iṣẹ́ náà pa dà tayọ̀tayọ̀. Irú òótọ́ inú báyìí la máa ń rí lára àwọn tó bá ń sin Ọlọ́run láìsí àgàbàgebè. Wọ́n kọ́kọ́ “yọ igi ìrólé” tó wà lójú tiwọn kí wọ́n tó gbìyànjú láti “yọ èérún pòròpórò” tó wà lójú arákùnrin wọn.

‘Ọkàn mi ò gbé e mọ́ láti jẹ́ agbaṣẹ́ṣe ẹnúdùnjuyọ̀. Bíbélì ti gún mi ní kẹ́ṣẹ́ ọkàn.’—JEFFERY

Jeffery tó fi ọ̀pọ̀ ọdún bá àwọn oníṣòwò ńlá ṣiṣẹ́ sọ pé: “Bí mo ṣe túbọ̀ ń lóye Bíbélì sí i, ọkàn mi ò gbé e mọ́ láti jẹ́ agbaṣẹ́ṣe ẹnúdùnjuyọ̀ tó lè dánnu láti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ìjọba. Àwọn ẹsẹ Bíbélì irú bí Òwe 11:1 ti gún mi ní kẹ́ṣẹ́ ọkàn, èyí tó sọ pé ‘òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì tí a fi ń rẹ́ni jẹ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.’ ” Jeffery ti rí i pé kò yẹ kí òun dà bí àwọn elétekéte tó ju ìbéèrè nípa owó orí sí Jésù, àmọ́ kí òun máa bá àwọn ará ìjọ àtàwọn tí kì í ṣe ará ìjọ lò láìní ète míì lọ́kàn.

Gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé là ń sapá láti fi àwọn ohun tá a ti kọ́ nínú Bíbélì sílò. À ń sapá gan-an láti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:24) A rọ̀ ẹ́ pé kó o wádìí nípa irú ẹni táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́, ohun tá a gbà gbọ́ àti bá a ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ̀ nípa ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Nínú ayé tuntun náà, ìwà àgàbàgebè máa pòórá, òdodo sì máa gbilẹ̀ níbẹ̀.2 Pétérù 3:13.