JỌ́JÍÀ
Mo Bẹ Jèhófà Pé Kó Tọ́ Mi Sọ́nà
Tamazi Biblaia
-
WỌ́N BÍ I NÍ 1954
-
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1982
-
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó ṣèrànwọ́ nígbà tí wọ́n ń tẹ ìwé wa jáde lábẹ́lẹ̀, ó sì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà, tòun ti ọmọ mẹ́rin.
ṢE NI ìyá mi gbaná jẹ nígbà tí èmi àti Tsitso ìyàwó mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́jọ́ kan, wọ́n pe gbogbo mọ̀lẹ́bí wa jọ, lérò pé tí gbogbo wọn bá bá mi sọ̀rọ̀, mi ò ní ṣe Ẹlẹ́rìí mọ́. Wọ́n ní kí n mú ọ̀kan, nínú kí n jáwọ́ nínú Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí mò ń ṣe, àbí kí n máa ṣe é lọ kí gbogbo ẹbí sì kọ̀ mí lọ́mọ.
Mo bá pinnu pé màá kúrò nílùú. Torí pé oníṣẹ́ irin ni mí, mo wò ó pé kí n kó lọ sílùú Kutaisi, tó jẹ́ ìlú kejì tó tóbi jù ní Jọ́jíà, torí ó máa rọrùn fún mi láti ríṣẹ́ níbẹ̀. Mo tún wò ó pé àwọn akéde tó wà nílùú yẹn ò pọ̀ rárá, mo wá bẹ Jèhófà pé kó tọ́ mi sọ́nà.
Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo pàdé ọ̀kan lára àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó ń gbé nílùú kékeré kan tó ń jẹ́ Jvari. Nígbà tó gbọ́ pé mò ń ronú láti kó lọ sí Kutaisi, ó bẹ̀ mí pé ìlú òun ni kí n kó wá. Ó sọ fún mi pé, “A ní ilé tá à ń gbé. Èmi, ìyàwó mi àtàwọn ọmọ mi á bọ́ sí yàrá kan, ìwọ àti ìyàwó ẹ á sì kó sí yàrá kejì.”
Torí pé Jèhófà ni mo fẹ́ kó tọ́ mi sọ́nà, mo sọ fún un pé tí mo bá tètè ríṣẹ́ nílùú Jvari, tí mo sì rílé tá a lè yá gbé níbẹ̀, màá gbà láti kó wá fúngbà díẹ̀. Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn ló pa dà wá bá mi, tó ń sọ oríṣiríṣi iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ fún mi. Ó yà mí lẹ́nu gan-an!
Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn ni èmi àti ìyàwó mi dèrò ìlú Jvari. Ọjọ́ àkọ́kọ́ tá a débẹ̀ ni mo ti ríṣẹ́ tí wọ́n á ti máa sanwó gidi fún mi, mi ò mọ̀ pé mo lè rírú iṣẹ́ yẹn. Ọ̀ga mi tuntun ní kí n máa kó bọ̀ nínú ilé ńlá kan tó jẹ́ ti iléeṣẹ́ náà. Nígbà tó yá, àwọn ará ní kí n ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwé tí wọ́n ń tẹ̀ jáde lábẹ́lẹ̀. Àyè kúkú pọ̀ nínú ilé wa tuntun, lèmi àti ìyàwó mi bá gbà láti máa lò ó fún iṣẹ́ yìí.
Ilé wa ńlá yìí ríṣẹ́ ṣe gan-an fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ibẹ̀ la ti ń sẹ Ìrántí Ikú Kristi àtàwọn àpéjọ pàtàkì míì. Àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ló ṣèrìbọmi nínú ilé wa! Inú mi dùn gan-an pé mo rí ọwọ́ Jèhófà tó ń tọ́ mi sọ́nà, mo sì tẹ̀ lé e!