Orukọ Ọlọrun ati “Majẹmu Titun” Naa
Orukọ Ọlọrun ati “Majẹmu Titun” Naa
IPO-ÀYÈ orukọ Ọlọrun ninu Iwe-mimọ Hebrew, “Majẹmu Laelae” jẹ alaileṣeemì. Bi o tilẹ jẹ pe ní asẹhinwa-asẹhinbọ awọn Jew dá pípè é duro, awọn igbagbọ isin wọn kò gbà wọn láyè lati yọ orukọ naa kuro nigba tí wọn nṣe awọn ẹ̀da awọn iwe-alafọwọkọ ti Bibeli ọlọjọ-gbọọrọ. Fun idi eyi, Iwe-mimọ Hebrew ní orukọ Ọlọrun ninu ju orukọ eyikeyi miiran lọ.
Pẹlu Iwe-mimọ Greek ti Kristian, “Majẹmu Titun,” ipo-ọran naa yatọ. Awọn iwe-alafọwọkọ ti iwe Iṣipaya (iwe tí ó gbẹhin ninu Bibeli) ní orukọ Ọlọrun ní ọna ikekuru rẹ̀, “Jah,” (ninu ọrọ naa “Hallelujah”). Ṣugbọn yatọ si eyiini, kò si iwe-alafọwọkọ Greek atijọ tí ó wà lọwọ wa lonii lara awọn iwe naa lati Matthew titi dé Iṣipaya tí ó ní orukọ Ọlọrun ní àkọkún. Eyiini ha tumọsi pe orukọ naa kò nilati si nibẹ ni bi? Eyiini yoo jẹ ohun iyalẹnu loju otitọ-iṣẹlẹ naa pe awọn ọmọlẹhin Jesu mọ ijẹpataki orukọ Ọlọrun ní àmọ̀dunjú, Jesu si kọ́ wa lati gbadura fun sisọ orukọ Ọlọrun di mímọ́. Nitori naa kinni ohun tí ó ṣẹlẹ?
Lati loye eyi, ranti pe awọn iwe-alafọwọkọ ti Iwe-mimọ Greek ti Kristian tí wọn wà lọwọ wa lonii kii ṣe ti ipilẹṣẹ. Awọn iwe tí Matthew, Luke ati awọn akọwe Bibeli miiran kọ funraawọn ni a ti lò ní àlògbó tí wọn si ti tete fàya. Fun idi yii, awọn ẹ̀dà ni a ṣe, ati pe nigba tí awọn wọnni bá gbó, awọn ẹ̀dà miiran ni a o ṣe lati inu awọn tí wọn ti gbó tán yẹn. Eyi ni ohun tí awa nilati fojusọna fun, niwọn bi ó ti jẹ pe awọn ẹ̀dà naa ni a ṣe bii ti atẹhinwa fun lílò, kii ṣe fun fifi pamọ.
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ẹ̀dà Iwe-mimọ Greek ti Kristian ni wọn wà lonii, ṣugbọn pupọ ninu wọn ni a ṣe laarin tabi lẹhin ọgọrun ọdun kẹrin Sanmanni tiwa yii. Eyi dabaa ohun kan tí ó le ṣeeṣe: Njẹ ohun kan ha ṣẹlẹ si Iwe-mimọ Greek ti Kristian ṣaaju ọgọrun ọdun kẹrin tí ó yọrisi fífo orukọ Ọlọrun dá bi? Awọn otitọ-iṣẹlẹ fihan pe ohun kan ṣẹlẹ.
Orukọ Naa Wà Nibẹ
Awa lè ní idaniloju pe apostle Matthew fi orukọ Ọlọrun sinu Gospel (itan igbesi-aye ati iṣẹ-ojiṣẹ Jesu) rẹ̀. Eeṣe? Nitori pe ede Hebrew ni oun fi kọ ọ́ ní ipilẹṣẹ. Ní ọgọrun ọdun kẹrin, Jerome, ẹni tí ó tumọ Latin Vulgate, rohin pe: “Matthew, ẹni tiiṣe ọmọ Levi pẹlu, ati pe ẹni tí ó kuro ní agbowo-ode tí ó si di apostle kan, ṣaaju ohunkohun ṣe akojọ Gospel Kristi ní Judea lede Hebrew . . . Ẹni tí ó tumọ rẹ̀ lẹhin naa si ede Greek ni a kò rí isọfunni tí ó tó nipa rẹ̀ lati mọ̀ daju. Jù bẹẹ lọ, eyi tí a kọ lede Hebrew ni a tọju titi di oni yii ní ile-ikowepamọ tí ó wà ní Caesarea.”
Niwọn bi Matthew ti kọwe lede Hebrew, ó jẹ alaile ṣee ronuwoye pe oun kò lo orukọ Ọlọrun, ní pataki nigba tí oun nṣàyọlò lati inu awọn apakan “Majẹmu Laelae” tí ó ní orukọ naa ninu. Bi o tiwu ki o ri, awọn akọwe apá keji Bibeli yoku kọwe fun awujọ-eniyan kari ayé kan lede tí gbogbo ayé akoko yẹn nsọ, Greek. Fun idi eyi, wọn kò ṣàyọlò lati inu awọn iwe Hebrew ti ipilẹṣẹ ṣugbọn lati inu ẹ̀dà Greek ti Septuagint. Ani Gospel Matthew ni a tumọ si ede Greek lẹhin-ọ-rẹhin paapaa. Njẹ orukọ Ọlọrun ha nilati farahan ninu awọn iwe Greek wọnyi bi?
Ó dara, diẹ ninu awọn ogbologbo àfọ́kù Septuagint Version tí wọn wà lọjọ Jesu ni a ti pamọ titi di ọjọ tiwa, eyi si yẹ fun gbigba afiyesi nitori pe orukọ Ọlọrun farahan ninu wọn. The New International Dictionary of New Testament Theology (Idipọ Keji, oju-ewe 512) sọ pe: “Awọn iwe tí a ṣẹṣẹ ṣawari laipẹ yii da iyemeji bo èrò naa pe awọn tí wọn ṣe akojọpọ LXX [Septuagint] fi kyrios tumọ Tetragrammaton naa YHWH. Awọn LXX MSS (àfọ́kù) ọlọjọ-lori julọ tí wọn wà larọwọto wa nisinsinyi ní Tetragrammaton tí a kọ ní awọn lẹta Heb[rew] ninu awọn ọrọ-aarin-iwe ede G[ree]k. Aṣa yii ni awọn ara Jew tí wọn tumọ Majẹmu Laelae dìmú titi ní ọgọrun ọdun kìn-ín-ní A.D.” Nitori naa, yala Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin kà Iwe-mimọ lede Hebrew tabi Greek, wọn yoo bá orukọ atọrunwa naa pade.
Ní bayii, Professor George Howard, ti University of Georgia, U.S.A., ṣe alaye yii: “Nigba tí Septuagint tí ṣọoṣi lò tí wọn si ṣàyọlò Majẹmu Titun rẹ̀ ní orukọ atọrunwa naa lede Hebrew ninu, kò si iyemeji nipa rẹ̀ pe awọn akọwe Majẹmu Titun fi Tetragrammaton naa sinu awọn àyọlò wọn.” (Biblical Archaeology Review, March 1978, oju-ewe 14) Aṣẹ wo ni wọn ní lati ṣe odikeji rẹ̀?
Orukọ Ọlọrun wà ninu awọn itumọ “Majẹmu Titun” ti ede Greek fun igba diẹ. Ní ibẹrẹ ọgọrun ọdun keji, alawọṣe Jew naa Aquila ṣe itumọ titun ti Iwe-mimọ Hebrew si ede Greek, ninu eyi oun si kọ orukọ Ọlọrun bii Tetragrammaton ní awọn lẹta Hebrew ti atijọ. Ní ọgọrun ọdun kẹta, Origen kọwe pe: “Ati pe ninu awọn iwe-alafọwọkọ pípé-pérépéré ORUKỌ NAA ni a kọ ní awọn lẹta Hebrew, sibẹ kii ṣe ní [awọn lẹta] Hebrew ti ode-oni, ṣugbọn ninu awọn ti ayé atijọ.”
Ani ní ọgọrun ọdun kẹrin paapaa, Jerome ṣe akọsilẹ kan ninu inasẹ-ọrọ ewì rẹ̀ nipa awọn iwe Samuel ati Awọn Ọba pe: “A si rí orukọ Ọlọrun, Tetragrammaton [יהוה], ninu awọn idipọ ede Greek kan bayii ani titi di oni yii tí a kọ wọn ní awọn lẹta atijọ.”
Yiyọ Orukọ naa Kuro
Ní akoko yii, bi o tiwu ki o ri, ipẹhinda tí Jesu sọtẹlẹ ti bẹrẹ iṣẹ ní pẹrẹu, orukọ naa, bi o tilẹ jẹ pe ó farahan ninu awọn iwe-alafọwọkọ, ni a ndín lílò rẹ̀ kù. (Matthew 13:24-30; Iṣe 20:29, 30) Lẹhin-ọ-rẹhin, ọpọ awọn onkawe kò tilẹ mọ ohun tí eyi jẹ ati pe Jerome rohin pe ní akoko tirẹ̀ “awọn eniyan alaimọkan kan bayii, nitori ijọra awọn lẹta naa, nigba tí wọn bá rí [Tetragrammaton] ninu awọn iwe lede Greek, ó ti mọ́ wọn lara lati maa ka ΠΙΠΙ.”
Ninu awọn ẹ̀dà Septuagint tí a kọ lẹhin naa, orukọ Ọlọrun ni a yọ kuro tí a si fi awọn ọrọ bii “Ọlọrun” (The·osʹ) ati “Oluwa” (Kyʹri·os) dipo rẹ̀. Awa mọ̀ pe eyi ṣẹlẹ nitori pe awọn àfọ́kù Septuagint ti igba laelae nibi tí a kọ orukọ Ọlọrun si ati awọn ẹ̀dà awọn apá kan naa wọnyẹn ti Septuagint tí a kọ lẹhin naa nibi tí a ti yọ orukọ Ọlọrun kuro wà larọwọto wa.
Ohun kan naa ṣẹlẹ ninu “Majẹmu Titun,” tabi Iwe-mimọ Greek ti Kristian. Professor George Howard nbá ọrọ rẹ̀ lọ ní sisọ pe: “Nigba tí a yọ orukọ atọrunwa naa lede Hebrew kuro nititori awọn àfidípò ede Greek ninu Septuagint, bakan naa pẹlu ni a yọ ọ́ kuro ninu awọn àyọlò Majẹmu Titun ti Septuagint. . . . Kò pẹ́ kò jinna orukọ atọrunwa naa di ohun tí ó sọnu lọdọ awọn ṣọọṣi awọn Keferi ayafi titi dé iwọn tí ó ti farahan ninu awọn àfidípò alakekuru tabi eyi tí awọn ọmọwe bá ranti rẹ̀.”
Fun idi yii, niwọn bi awọn Jew ti kọ̀ lati pe orukọ Ọlọrun, ṣọọṣi Kristian apẹhinda gbiyanju lati yọ ọ́ kuro patapata lati inu awọn iwe-alafọwọkọ ti apá mejeeji Bibeli lede Greek, ati lati inu awọn ẹ̀dà ti ede miiran pẹlu.
Aini fun Orukọ Naa
Lẹhin-ọ-rẹhin, bi a ti rí i ṣaaju, orukọ naa ni a mú padabọsipo sinu ọpọ awọn itumọ Iwe-mimọ Hebrew. Ṣugbọn Iwe-mimọ Greek nkọ́? Họọwu, awọn atumọ Bibeli ati awọn akẹkọọ wá loye pe laisi orukọ Ọlọrun, awọn apá kan ninu Iwe-mimọ Greek ti Kristian yoo ṣoro lati loye lọna yiyẹ. Mímú orukọ naa padabọsipo jẹ iranwọ nla kan ní mímú ibisi bá iṣekedere ati imoye apá yii ninu Bibeli onimisi naa.
Fun apẹẹrẹ, ronu nipa awọn ọrọ Paul si awọn ara Rome, bi wọn ti ṣe farahan ninu Authorized Version: “Nitori pe ẹnikẹni yowu tí yoo bá kepe orukọ Oluwa ni a o gbala.” (Rome 10:13) Orukọ tani a nilati pè ki a tó lè rí igbala? Niwọn bi a ti saba maa nsọrọ Jesu gẹgẹ bi “Oluwa,” ati pe ẹsẹ iwe-mimọ kan tilẹ sọ paapaa pe: “Gba Jesu Kristi Oluwa gbọ́, a o si gbà ọ là,” awa ha nilati pari ero naa si pe Paul nsọrọ nipa Jesu nibi yii ni bi?—Iṣe 16:31, Authorized Version.
Rara o, a kò nilati ṣe bẹẹ. Alaye eti-iwe si Rome 10:13 ninu Authorized Version tọkasi Joel 2:32 ninu Iwe-mimọ Hebrew. Bi iwọ bá ṣakiyesi alaye eti-iwe yẹn, iwọ yoo rí i wipe Paul niti gasikia nṣàyọlò awọn ọrọ Joel ninu lẹta rẹ̀ si awọn ara Rome; ohun tí Joel si sọ ninu Hebrew ti ipilẹṣẹ ni pe: “Olukuluku ẹni tí ó bá kepe orukọ Jehofah ni a o gbala.” (New World Translation) Bẹẹ ni, ohun tí Paul ní lọkan nihin ni pe a nilati kepe orukọ Jehofah. Fun idi yii, niwọn bi a ti nilati gbagbọ ninu Jesu, igbala sopọ pẹkipẹki mọ́ fifi imọriri yíyẹ hàn fun orukọ Ọlọrun.
Apẹẹrẹ yii ṣaṣefihan bi yíyọ orukọ Ọlọrun kuro ninu Iwe-mimọ Greek ṣe pakún idarudapọ àìdákanmọ̀ laarin Jesu ati Jehofah ninu ọkàn awọn ọpọlọpọ eniyan. Laisi tabi ṣugbọn, eyi ti pakún idagbasoke ẹkọ-igbagbọ Mẹtalọkan lọna tí ó gadabu!
A Ha Nilati Dá Orukọ naa Pada Bi?
Atumọ kan yoo ha lẹtọ eyikeyi lati dá orukọ naa pada, loju otitọ-iṣẹlẹ naa pe awọn iwe-alafọwọkọ tí wọn wà larọwọto nisinsinyi kò ní orukọ naa ninu? Bẹẹ ni, oun yoo ní ẹtọ yẹn. Ọpọ julọ ninu awọn iwe-akojọ-ọrọ fun itumọ lede Greek gba ẹri naa jẹ́ si otitọ pe lọpọ igba ni ọrọ naa “Oluwa” ninu Bibeli maa ntọkasi Jehofah. Fun apẹẹrẹ, ní apá tirẹ̀ labẹ ọrọ Greek naa Kyʹri·os (“Oluwa”), iwe Robinson naa tí orukọ rẹ̀ njẹ A Greek and English Lexicon of the New Testament (tí a tẹjade ní 1859) sọ pe ó tumọsi “Ọlọrun gẹgẹ bi Oluwa Giga Julọ ati ọba-alaṣẹ agbaye, bii ti atẹhinwa ninu Sept[uagint] fun Heb[rew] יְהוָֹה Jehovah.” Fun idi yii, ní awọn ibi tí awọn akọwe Iwe-mimọ Greek ti Kristian ti ṣàyọlò ninu Iwe-mimọ Hebrew ti iṣaaju, atumọ naa lẹtọ lati kọ ọrọ naa Kyʹri·os gẹgẹ bi “Jehofah” nibikibi tí orukọ atọrunwa naa ti farahan ninu Hebrwe ti ipilẹṣẹ.
Ọpọ awọn atumọ ti ṣe eyi. Ó keretan bẹrẹ lati ọgọrun ọdun kẹrinla, ọpọlọpọ awọn itumọ lede Hebrew ni a ṣe ninu Iwe-mimọ Greek ti Kristian. Kinni awọn atumọ ṣe nigba tí wọn dórí awọn àyọlò lati inu “Majẹmu Laelae” nibi tí orukọ Ọlọrun ti farahan? Lọpọ igba, wọn ní imọlara pe a fi ipá mú wọn lati dá orukọ Ọlọrun pada. Ọpọ itumọ apakan tabi odi-ndi Iwe-mimọ Greek ti Kristian lede Hebrew ní orukọ Ọlọrun ninu.
Awọn itumọ si awọn ede ode-oni, ní pataki awọn wọnni tí awọn ojiṣẹ Ọlọrun ní ilẹ ajeji lò, ti tẹle apẹẹrẹ yii. Ní bayii ọpọ ẹ̀dà Iwe-mimọ Greek tí Kristian ní awọn ede Africa, Asia, America, ati Pacific-island ni wọn lo orukọ naa Jehofah fàlàlà, nitori ki awọn onkawe bá le rí iyatọ kedere laarin Ọlọrun tootọ ati awọn wọnni tí wọn jẹ eke. Orukọ naa ti farahan, pẹlu, ninu awọn ẹ̀dà ní awọn ede Europe.
Itumọ kan tí ó fi tigboya-tigboya dá orukọ Ọlọrun pada pẹlu ọla-aṣẹ didara ni New World Translation of the Christian Greek Scriptures. Itumọ yii, tí ó wà larọwọto ní awọn ede ode-oni mọkanla, ti dá orukọ Ọlọrun pada ní gbogbo igba tí a ṣàyọlò apakan Iwe-mimọ Hebrew nibi tí ó ti farahan ninu Iwe-mimọ Greek. Lapapọ, orukọ naa farahan pẹlu ipilẹ tí ó yekooro ní 237 igba ninu itumọ Iwe-mimọ Greek yẹn.
Atako si Orukọ Naa
Laika isapa ọpọ awọn atumọ lati dá orukọ Ọlọrun pada ninu Bibeli si, nigba gbogbo ni ikimọlẹ maa nwá lati ọ̀dọ̀ awọn onisin lati mú un kuro. Awọn Jew, bi wọn tilẹ fi i silẹ ninu Bibeli wọn, ti kọ̀ lati pè é. Awọn Kristian apẹhinda ti ọgọrun ọdun ekeji ati ẹkẹta ti fà á yọ kuro nigba tí wọn ṣe awọn ẹ̀dà Bibeli alafọwọkọ Greek tí wọn si gbagbe rẹ̀ nigba tí wọn ṣe awọn itumọ Bibeli. Awọn atumọ lode-oni ti fà á yọ kuro, ani nigba tí wọn bá gbé itumọ wọn ka ori Hebrew ti ipilẹṣẹ paapaa, nibi tí ó ti farahan ní eyi tí ó fẹrẹẹ tó 7,000 igba. (Ó farahan ní 6,973 igba ninu awọn ọrọ-aarin-iwe Hebrew ti New World Translation of the Holy Scriptures, itẹjade ti 1984.)
Oju wo ni Jehofah fi nwo awọn wọnni tí wọn fa orukọ rẹ̀ yọ kuro ninu Bibeli? Bi iwọ bá jẹ onṣewe kan, kinni yoo jẹ imọlara rẹ si ẹnikan tí ó gun igi rekọja ewé lati fa orukọ rẹ yọ kuro ninu iwe tí iwọ ṣe? Awọn atumọ tí wọn ṣodisi orukọ naa, tí wọn nṣe bẹẹ nitori awọn ọran-iṣoro ti pípè tabi nitori aṣa-atọwọdọwọ Jew, ni a le tọkasi gẹgẹ bi awọn tí wọn farajọ awọn wọnni tí Jesu sọ pe wọn “nsẹ́ kò-tó-nkan kuro ṣugbọn tí wọn ngbé ìbakasíẹ mì!” (Matthew 23:24, NW) Awọn ọran-iṣoro keekeeke wọnyi ngbé wọn ṣubu ṣugbọn wọn pari rẹ̀ si dídá ọran-iṣoro nla silẹ—nipa fifa orukọ ẹni tí ó tobi julọ ní agbaye yọ kuro ninu iwe tí oun misi.
Onipsalm naa kọwe pe: “Yoo ti pẹ́ tó, Óò Ọlọrun, tí elénìní yoo fi maa bá kikẹgan niṣo? Ọ̀tá yoo ha maa bá a lọ ní bíbá orukọ rẹ lò pẹlu àìlọ́wọ̀ titilae ni bi?”—Psalm 74:10, NW.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
“OLUWA”—Ohun-ibaṣedeedee fun “Jehofah” Ha Ni Bi?
Lati fa orukọ afiyatọ-hàn ara-ẹni ti Ọlọrun yọ kuro ninu Bibeli ki a si fi akọle bii “Oluwa” tabi “Ọlọrun” ṣàfidípò rẹ̀ nsọ ọrọ-aarin-iwe naa di ahẹrẹpẹ ati alaiyẹ lọpọlọpọ awọn ọna. Fun apẹẹrẹ, ó le ṣamọna si akojọ alainitumọ nipa awọn ọrọ. Ninu ọrọ-iṣaaju rẹ̀, The Jerusalem Bible sọ pe: “Lati sọ pe, ‘Oluwa ni Ọlọrun jẹ ìfọ̀rọ̀ṣòfò [awitunwi asan, alainidii, tabi alainitumọ], ní sisọ pe ‘Yahweh ni Ọlọrun’ kii ṣe bẹẹ.”
Irufẹẹ awọn àfidípò bẹẹ le yọrisi awọn awẹ́-gbolohun tí kò lójútùú. Nipa bẹẹ ninu Authorized Version, Psalm 8:9 kà pe: “Óò OLUWA Oluwa wa, orukọ rẹ ti ní iyì tó ní gbogbo ayé!” Wo bi eyi tí jẹ imusunwọn tó nigba tí a bá dá orukọ Jehofah pada sinu iru ọrọ-aarin-iwe bẹẹ! Nipa bẹẹ, Young’s Literal Translation of the Holy Bible kà nibi yii pe: “Jehofah, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ní ọlá tó ní gbogbo ayé!”
Fifa orukọ naa yọ kuro tún ṣamọna si àìdákanmọ̀ pẹlu. Psalm 110:1 sọ pe: “OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ jokoo ní ọwọ́ ọ̀tún mi, titi emi yoo fi sọ awọn ọta rẹ di apoti itisẹ rẹ.” (Authorized Version) Tani ẹni tí nsọrọ, tani a sọ ọ si? Ẹ wo bi itumọ rẹ̀ ti sunwọn si i tó pe: “Asọjade-ọrọ Jehofah si Oluwa mi ni pe: ‘Jokoo ní ọwọ́ ọ̀tún mi titi emi yoo fi gbé awọn ọta rẹ kalẹ gẹgẹ bi apoti-itisẹ fun ẹsẹ̀-ìtẹlẹ̀ rẹ.’”—New World Translation.
Pẹlupẹlu, fifi “Oluwa” ṣàfidípò “Jehofah” nfa ohun kan tí awọn ohun miiran sinmi lé ori ijẹpataki rẹ̀ yọ kuro ninu Bibeli: Orukọ ara-ẹni ti Ọlọrun. The Illustrated Bible Dictionary (Idipọ Kìn-ín-ní oju-ewe 572) sọ pe: “Ní sisọrọ sibi tí ọrọ wà, Yahweh nikan ni ‘orukọ’ kanṣoṣo ti Ọlọrun.”
The Imperial Bible-Dictionary (Idipọ Kìn-ín-ní, oju-ewe 856) ṣapejuwe iyatọ laarin “Ọlọrun” (Elohim) ati “Jehofah,” ní sisọ pe: “[Jehofah] ni orukọ naa gan-an nibi gbogbo tí ó duro fun Ọlọrun bii ti adanida ẹda-eniyan ani oun nikanṣoṣo; nigba tí Elohim jẹ ọrọ-orukọ tí ó wọpọ, tí ó saba maa nduro fun bii ti atẹhinwa, niti tootọ, ṣugbọn tí kò fi dandan tabi lọna àjùmọ̀gbà jẹ ti Ẹni Giga Julọ naa.”
J. A. Motyer, ọga ile-ẹkọ Trinity College, England, ṣafikun pe: “Ọpọ nkan ni a le padanu ninu kika Bibeli bi a bá gbagbe lati wò rekọja ọrọ àfidípò naa [Oluwa tabi Ọlọrun] si orukọ ti ara-ẹni, orukọ timọtimọ ti Ọlọrun tikalaraarẹ̀. Nipa sisọ orukọ rẹ̀ fun awọn eniyan rẹ̀, Ọlọrun ní in lọkan lati ṣí iwa-ẹda rẹ̀ tí ó farapamọ julọ payá fun wọn.”—Eerdmans’ Handbook to the Bible, oju-ewe 157.
Rara o, ẹnikan kò le fi orukọ-òye lasan tumọ orukọ afìyàtọ̀-hàn. Orukọ-òye kan kò le funni ní ẹkunrẹrẹ ati itumọ tí ó niyelori laelae nipa orukọ naa gan-an tí Ọlọrun njẹ́.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èkúfọ́ Septuagint yii (ti apá ọ̀tún) tí a kọ ní ọgọrun ọdun kìn-ín-ní, tí ó ní Zechariah 8:19-21 ati Zec 8:23-9:4 ninu wà ní Ile Awọn Ohun Iṣẹmbaye ti Israel ní Jerusalem. Ó ní orukọ Ọlọrun ninu ní igba mẹrin, mẹta lara eyi tí a tọkafihan nihin yii. Ninu Iwe-alafọwọkọ ti Alexandrine (ti apá òsì), ẹ̀dà Septuagint kan tí a kọ ní 400 ọdun lẹhin naa, a ti fi KY ati KC, ikekuru ọrọ Greek naa Kyʹri·os (“Oluwa”) dipo orukọ Ọlọrun ninu awọn ẹsẹ kan naa wọnyẹn
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
John W. Davis, ojiṣẹ Ọlọrun ní ilẹ ajeji kan, tí ó wà ní China ní ọgọrun ọdun kọkandinlogun, ṣalaye idi tí oun fi gbagbọ pe orukọ Ọlọrun nilati wà ninu Bibeli: “Bi Ẹmi Mimọ bá sọ Jehofah nibikibi ninu Hebrew, eeṣe tí atumọ naa kò sọ pe Jehofah lede Gẹẹsi tabi Chinese? Ẹtọ wo ló ní lati sọ pe, Emi yoo lo Jehofah nibi yii, tí emi yoo si ṣàfidípò rẹ̀ nibomiran? . . . Bi ẹnikan bá nilati sọ pe awọn ọran kan wà nibi tí lilo Jehofah yoo ti lodi, ẹ jẹ ki ó fi idi rẹ̀ hàn wa; onus probandi [ẹru-inira ami-ẹri] já lé e lori. Oun yoo rí i pe ẹru-iṣẹ naa jẹ eyi tí ó nira, nitori pe ó gbọdọ dahun ibeere rirọrun yii,—bi ó bá jẹ pe ninu ọran eyikeyi kò tọna lati lo Jehofah ninu itumọ nigba naa eeṣe tí onkọwe onimisi naa fi lò ó ninu ti ipilẹṣẹ?”—The Chinese Recorder and Missionary Journal, Idipọ Keje, Shanghai, 1876.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
New World Translation of the Christian Greek Scriptures lo orukọ Ọlọrun ní 237 igba lọna yiyẹ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Orukọ Ọlọrun lara ile ṣọọṣi kan ní Minorca, Spain;
lara ère kan nitosi Paris, France;
ati lara Chiesa di San Lorenzo, Parma, Italy