Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

Kí ni lájorí ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ nínú Bíbélì?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Mọ Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì?

Bíbélì ni ìwé táwọn èèyàn mọ̀ jù láyé. Wo àwọn ìsọfúnni díẹ̀ nípa ẹ̀ tó lè ṣe ẹ́ láǹfààní.

APÁ 1

Ẹlẹ́dàá Dá Èèyàn Sínú Párádísè

Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe dá èèyàn? Àṣẹ wo ni Ọlọ́run pa fún tọkọtaya tó kọ́kọ́ dá?

APÁ 2

A Sọ Párádísè Nù

Nígbà tí Ọlọ́run ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti Éfà jẹ wọ́n, ìrètí wo ni Ọlọ́run jẹ́ ká ní?

APÁ 3

Aráyé La Ìkún Omi Já

Báwo ni ìwà búburú ṣe tàn kálẹ̀ láyé? Kí ni Nóà ṣe láti fi hàn pé olódodo ni òun?

APÁ 4

Ọlọ́run Bá Ábúráhámù Dá Májẹ̀mú

Kí ló dé tí Ábúráhámù fi kó lọ sí Kénáánì? Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Ábúráhámù dá?

APÁ 5

Ọlọ́run Bù Kún Ábúráhámù àti Ìdílé Rẹ̀

Kí ni Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ nígbà tó sọ pé kí Ábúráhámù fi Ísákì rúbọ? Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jékọ́bù sọ kó tó kú?

APÁ 6

Jóòbù Pa Ìwà Títọ́ Rẹ̀ Mọ́

Báwo ni ìwé Jóòbù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá tó ní làákàyè ló lè ṣe ohun tó máa dá ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre?

APÁ 7

Ọlọ́run Dá Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Nídè

Báwo ni Ọlọ́run ṣe lo Mósè láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní oko ẹrú Íjíbítì? Kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá?

APÁ 8

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Wọ Ilẹ̀ Kénáánì

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì, kí ló dé tí Jèhófà fi dá ẹ̀mí Ráhábù àti ti ìdílé rẹ̀ sí ní Jẹ́ríkò?

APÁ 9

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Sọ Pé Àwọn Fẹ́ Ọba

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kí Ọlọ́run fún àwọn ní ọba, Jèhófà yan Sọ́ọ̀lù. Àmọ́ kí ló dé tí Jèhófà tún wá fi Dáfídì rọ́pò Ọba Sọ́ọ̀lù?

APÁ 10

Sólómọ́nì Fọgbọ́n Ṣàkóso

Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Sólómọ́nì fọgbọ́n ṣe? Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó fi ọ̀nà Jèhófà sílẹ̀?

APÁ 11

Àwọn Orin Onímìísí, Tó Ń Tuni Nínú, Tó sì Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Èwo nínú àwọn sáàmù ló sọ bí Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, tó sì ń tù wọ́n nínú? Kí ni Ọba Sólómọ́ni sọ fún wa nínú Orin Sólómọ́nì?

APÁ 12

Ọgbọ́n Ọlọ́run Tó Ń Mú Ká Wà Láàyè

Wo bí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú ìwé Òwe àti ìwé Oníwàásù ṣe lè tọ́ ẹ sọ́nà, kó o sì lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.

APÁ 13

Àwọn Ọba Rere Àtàwọn Ọba Búburú

Báwo ló ṣe di pé ìjọba Ísírẹ́lì pín sí méjì?

APÁ 14

Ọlọ́run Gbẹnu Àwọn Wòlíì Rẹ̀ Sọ̀rọ̀

Iṣẹ́ wo ni àwọn wòlíì Ọlọ́run jẹ́? Wo mẹ́rin lára àwọn kókó pàtàkì tí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì Ọlọ́run dá lé.

APÁ 15

Wòlíì Kan Tó Wà Nígbèkùn Rí Ohun Tó Ń Bọ̀ Wá Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú Nínú Ìran

Kí ni Dáníẹ́lì kọ́ nípa Mèsáyà àti Ìjọba Ọlọ́run?

APÁ 16

Mèsáyà Dé

Báwo ni Jèhófà ṣe lo àwọn áńgẹ́lì àti Jòhánù Oníbatisí láti tọ́ka sí Jésù pé òun ni Mèsáyà? Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kó ṣe kedere Ọmọ òun ni Mèsáyà?

APÁ 17

Jésù Kọ́ni Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Kí ni kókó pàtàkì tí Jésù ń wàásù nípa rẹ̀? Báwo ló ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé kò ní sí ìrẹ́jẹ tó bá ń ṣàkóso, àti pé ìfẹ́ máa jọba?

APÁ 18

Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu

Kí ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ nípa bó ṣe lágbára tó àti bí ayé ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í jọba?

APÁ 19

Jésù Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìmúṣẹ Rẹ̀ Rìn Jìnnà

Kí ni ìtumọ̀ àwọn àmì tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?

APÁ 20

Wọ́n Pa Jésù Kristi

Kí wọ́n tó da Jésù, tí wọ́n sì kàn án mọ́gi, ohun tuntun wo ló dá sílẹ̀, pé ká máa rántí?

APÁ 21

Jésù Jíǹde!

Báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ti jí i dìde?WEB:OnSiteAdTitleJésù Jíǹde!

APÁ 22

Àwọn Àpọ́sítélì Wàásù Láìbẹ̀rù

Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà Àjọyọ̀ Pẹ́ntíkọ́sì? Báwo ló ṣe rí lára àwọn ọ̀tá nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń wàásù?

APÁ 23

Ìhìn Rere Tàn Kálẹ̀

Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù wo ọkùnrin kan sàn ní Lísírà? Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe di èrò ìlú Róòmù?

APÁ 24

Pọ́ọ̀lù Kọ Lẹ́tà Sáwọn Ìjọ

Àwọn ìtọ́ni wo ní Pọ́ọ̀lù pèsè nípa ìṣètò ìjọ? Kí ló sọ nípa irú ọmọ tá a ṣèlérí?

APÁ 25

Ìmọ̀ràn Lórí Ìgbàgbọ́, Ìwà àti Ìfẹ́

Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́? Báwo ni èèyàn ṣe lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run dénú?

APÁ 26

A Jèrè Párádísè Pa Dà!

Báwo ni ìwé Ìṣípayà ṣe parí ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì?

Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì

Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ̀ ní ṣísẹ̀-ń-tẹ̀lé pé Jésù ló máa di Mèsáyà, ẹni tó máa mú kí ayé pa dà di párádísè?

Àtẹ Àwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Inú Bíbélì

Wo àtẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, bẹ̀rẹ̀ láti 4026 Ṣ.S.K títí di nǹkan bíi 100 S.K