Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Apá 26

A Jèrè Párádísè Pa Dà!

A Jèrè Párádísè Pa Dà!

Nípasẹ̀ Ìjọba tí Kristi máa jẹ́ alákòóso rẹ̀, Jèhófà máa ya orúkọ ara Rẹ̀ sí mímọ́, ó máa dá ipò ọba aláṣẹ Rẹ̀ láre, ó sì máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò

ÌWÉ tó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì, tó ń jẹ́ Ìṣípayá tàbí Àpókálíìsì mú kí gbogbo aráyé nírètí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa. Àwọn ìran tó sọ nípa ìmúṣẹ ète Jèhófà ló wà nínú ẹ̀, àpọ́sítélì Jòhánù ló sì kọ ọ́.

Nínú ìran àkọ́kọ́, Jésù tí Ọlọ́run jí dìde gbóríyìn fáwọn ìjọ mélòó kan, ó sì tọ́ wọn sọ́nà. Ìran tó kàn fi ìtẹ́ Ọlọ́run lókè ọ̀run hàn wá, níbi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ti ń fi ìyìn fún Ọlọ́run.

Bí ète Ọlọ́run ṣe ń ní ìmúṣẹ síwájú àti síwájú sí i, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi, gba àkájọ ìwé kan tó ní àwọn èdìdì méje. Nígbà tó ṣí èdìdì mẹ́rin àkọ́kọ́, àwọn agẹṣin ìṣàpẹẹrẹ fara hàn. Èyí àkọ́kọ́ ni Jésù, ó wà lórí ẹṣin funfun, adé Ọba sì wà lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà ló kan àwọn agẹṣin táwọn ẹṣin wọ́n ní onírúurú àwọ̀, lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ẹṣin náà ṣàpẹẹrẹ ogun, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn, gbogbo èyí tó ń wáyé láàárín àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí. Ṣíṣí èdìdì keje ló yọrí sí fífọn àwọn kàkàkí ìṣàpẹẹrẹ méje, tí wọ́n dúró fún àwọn ìpolongo ìdájọ́ Ọlọ́run. Lẹ́yìn èyí ló wá kan àwọn àjàkálẹ̀ àrùn ìṣàpẹẹrẹ méje, tàbí ìtújáde ìbínú Ọlọ́run.

A fìdí Ìjọba Ọlọ́run, tá a fi wé bíbí ọmọ tuntun kan tó jẹ́ akọ, múlẹ̀ lókè ọ̀run. Ogun ṣẹlẹ̀ lọ́run, a sì fi Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì búburú rẹ̀ sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé. Ohùn rara kan kígbe pé, “ègbé ni fún ilẹ̀ ayé.” Èṣù ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé àkókò kúkúrú ni òun ní.—Ìṣípayá 12:12.

Jòhánù rí ọ̀dọ́ àgùntàn, tó ṣàpẹẹrẹ Jésù, lókè ọ̀run, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], tá a yàn láti àárín aráyé, sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí “yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú” Jésù. Nípa báyìí, ìwé Ìṣípayá jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ni iye àwọn tó jẹ́ apá kejì lára irú-ọmọ náà.—Ìṣípayá 14:1; 20:6.

Àwọn olùṣàkóso ayé kóra jọ sí Amágẹ́dọ́nì, “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” Wọ́n bá ẹni tó jókòó sórí ẹṣin funfun náà jagun, ìyẹn Jésù, tó jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ ogun ọ̀run. Ó pa gbogbo àwọn olùṣàkóso ayé yìí run. Jésù de Sátánì, òun àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] sì jọba lé ayé lórí fún “ẹgbẹ̀rún ọdún.” Lópin ẹgbẹ̀rún ọdún náà, ó pa Sátánì run.—Ìṣípayá 16:14; 20:4.

Kí ni Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi àti tàwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ máa túmọ̀ sí fún aráyé onígbọràn? Jòhánù kọ̀wé pé: “[Jèhófà] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Ayé á wá di Párádísè!

Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé Ìṣípayá ló mú àwọn ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì wá sí ìparí. Ìjọba Mèsáyà máa ya orúkọ Jèhófà sí mímọ́, ó sì máa dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run láre títí láé fáàbàdà!

A gbé e ka ìwé Ìṣípayá.